Mal 2:1-9

Mal 2:1-9 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA ní, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin alufaa, ẹ̀yin ni àṣẹ yìí wà fún. Bí ẹ kò bá ní gbọ́ràn, tí ẹ kò sì ní fi sọ́kàn láti fi ògo fún orúkọ mi, n óo mú ègún wá sórí yín, ati sórí àwọn ohun ìní yín. Mo tilẹ̀ ti mú ègún wá sórí àwọn ohun ìní yín, nítorí pé ẹ kò fi ọ̀rọ̀ mi sọ́kàn. Ẹ wò ó! N óo jẹ àwọn ọmọ yín níyà, n óo fi ìgbẹ́ ẹran tí ẹ fi ń rúbọ kùn yín lójú, n óo sì le yín kúrò níwájú mi. Nígbà náà ni ẹ óo mọ̀ pé èmi ni mo pàṣẹ yìí fun yín, kí majẹmu mi pẹlu Lefi má baà yẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun wí! “Majẹmu ìyè ati alaafia ni majẹmu mi pẹlu Lefi. Mo bá a dá majẹmu yìí kí ó baà lè bẹ̀rù mi; ó sì bẹ̀rù mi, ó bọ̀wọ̀ fún orúkọ mi. Ó fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ kọ́ni, kìí sọ̀rọ̀ àìtọ́. Ó bá mi rìn ní alaafia ati ìdúróṣinṣin, ó sì yí ọkàn ọpọlọpọ eniyan pada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀. Láti ẹnu alufaa ni ó ti yẹ kí ìmọ̀ ti máa jáde, kí àwọn eniyan sì máa gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí pé, iranṣẹ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni. “Ṣugbọn ẹ̀yin alufaa ti yapa kúrò ní ọ̀nà òtítọ́, ẹ ti mú ọ̀pọ̀ eniyan kọsẹ̀ nípa ẹ̀kọ́ yín, ẹ sì ti da majẹmu tí mo bá Lefi dá. Nítorí náà, n óo pa yín dà sí àìdára, ẹ óo sì di yẹpẹrẹ lójú àwọn eniyan; nítorí pé ẹ kò tẹ̀lé ìlànà mi, ẹ̀ ń fi ojuṣaaju bá àwọn eniyan lò nígbà tí ẹ bá ń kọ́ wọn. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!”

Mal 2:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ̀yin àlùfáà, òfin yìí ní fún yín. Bí ẹ̀yin kò bá ni gbọ́, bí ẹ̀yin kò bá ní fi í sí àyà láti fi ọ̀wọ̀ fún orúkọ mi,” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí; èmi yóò sì ran ègún sí orí yín, èmi yóò sì fi ìbùkún yín ré. Nítòótọ́ mó ti fi ré ná, nítorí pé, ẹ̀yin kò fi sí ọkàn yín láti bu ọlá fún mi. “Nítorí tiyín èmí yóò ba àwọn ọmọ yín wí, èmi ó sì fi ìgbẹ́ rẹ́ yín lójú, àní àwọn ìgbẹ́ ọrẹ ọwọ́ yín wọ̀nyí, a ó sì kó yín lọ pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ̀yin ó sì mọ̀ pé, èmi ni ó ti rán òfin yìí sí yín, kí májẹ̀mú mi pẹ̀lú Lefi lè tẹ̀síwájú” ní OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Májẹ̀mú mi wà pẹ̀lú rẹ̀, májẹ̀mú ti ìyè àti àlàáfíà wà pẹ̀lú rẹ̀; mo sì fi wọn fún un, nítorí bíbẹ̀rù tí ó bẹ̀rù mi, tí ẹ̀rù orúkọ mi sì bà á. Òfin òtítọ́ wà ni ẹnu rẹ̀, a kò sì rí irọ́ ni ètè rẹ̀: ó ba mi rìn ní àlàáfíà àti ni ìdúró ṣinṣin, ó sì yí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. “Nítorí ètè àlùfáà ní òye láti máa pa ìmọ̀ mọ́, kí àwọn ènìyàn lè máa wá ìtọ́ni ni ẹnu rẹ̀: nítorí òun ni ìránṣẹ́ OLúWA àwọn ọmọ-ogun. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yapa kúrò ní ọ̀nà náà; ẹ̀yin sì ti fi ìkọ́ni yín mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọsẹ̀; ẹ̀yin ti ba májẹ̀mú tí mo da pẹ̀lú Lefi jẹ́,” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Nítorí náà ni èmi pẹ̀lú ṣe sọ yín di ẹ̀gàn, àti ẹni àìkàsí níwájú gbogbo ènìyàn, nítorí ẹ̀yin kò tẹ̀lé ọ̀nà mi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń ṣe ojúsàájú nínú òfin.”