Mal 1:6-9
Mal 1:6-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọmọ a ma bọla fun baba, ati ọmọ-ọdọ fun oluwa rẹ̀: njẹ bi emi ba ṣe baba, ọla mi ha da? bi emi ba si ṣe oluwa, ẹ̀ru mi ha da? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi fun nyin: Ẹnyin alufa, ti ngàn orukọ mi. Ẹnyin si wipe, Ninu kini awa fi kẹ́gàn orukọ rẹ? Ẹnyin fi akarà aimọ́ rubọ lori pẹpẹ mi; ẹnyin si wipe, Ninu kini awa ti sọ ọ di aimọ́? Ninu eyi ti ẹnyin wipe, Tabili Oluwa di ohun ẹgàn. Bi ẹnyin ba si fi eyi ti oju rẹ̀ fọ́ rubọ, ibi kọ́ eyini? bi ẹnyin ba si fi amúkun ati olokunrùn rubọ, ibi kọ́ eyini? mu u tọ bãlẹ rẹ lọ nisisiyi; inu rẹ̀ yio ha dùn si ọ, tabi yio ha kà ọ si? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Njẹ nisisiyi, mo bẹ̀ nyin, ẹ bẹ̀ Ọlọrun ki o ba le ṣe ojurere si wa: lati ọwọ nyin li eyi ti wá: on o ha kà nyin si? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Mal 1:6-9 Yoruba Bible (YCE)
“Ọmọ a máa bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, iranṣẹ a sì máa bẹ̀rù oluwa rẹ̀. Bí mo bá jẹ́ baba yín, ṣé ẹ̀ ń bọ̀wọ̀ fún mi? Bí mo bá sì jẹ́ oluwa yín, ṣé ẹ bẹ̀rù mi ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ń bi ẹ̀yin alufaa tí ẹ̀ ń tàbùkù orúkọ mi? Sibẹsibẹ ẹ̀ ń bèèrè pé, ‘Ọ̀nà wo ni a fi ń tàbùkù orúkọ rẹ?’ Ìdí rẹ̀ tí mo fi ní ẹ̀ ń tàbùkù orúkọ mi ni pé, ẹ̀ ń fi oúnjẹ àìmọ́ rúbọ lórí pẹpẹ mi. Ẹ tún bèèrè pé, ‘Ọ̀nà wo ni a fi sọ pẹpẹ rẹ di àìmọ́?’ Ẹ ti tàbùkù pẹpẹ mi, nípa rírò pé ẹ lè tàbùkù rẹ̀. Nígbà tí ẹ bá mú ẹran tí ó fọ́jú, tabi ẹran tí ó múkùn-ún, tabi ẹran tí ń ṣàìsàn wá rúbọ sí mi, ǹjẹ́ kò burú? Ṣé ẹ lè fún gomina ní irú rẹ̀ kí inú rẹ̀ dùn si yín, tabi kí ẹ rí ojurere rẹ̀?” Nisinsinyii, ẹ̀yin alufaa, ẹ mú irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́, ẹ̀ ń gbadura sí Ọlọrun, pé kí ó lè fi ojurere wò yín; Ṣé ẹ rò pé OLUWA yóo fi ojurere wo ẹnikẹ́ni ninu yín?
Mal 1:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ọmọ a máa bu ọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, ọmọ ọ̀dọ̀ a sì máa bu ọlá fún olúwa rẹ̀. Ǹjẹ́ bí èmí bá jẹ́ baba, ọlá tí ó tọ́ sí mi ha dà? Bí èmi bá sì jẹ́ olúwa, ẹ̀rù tí ó tọ́ sí mi dà?” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Ẹ̀yin ni, ẹ̀yin àlùfáà, ni ẹ ń gan orúkọ mi. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe gan orúkọ rẹ?’ “Ẹ̀yin gbé oúnjẹ àìmọ́ sí orí pẹpẹ mi. “Ẹ̀yin sì tún béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe ṣe àìmọ́ sí ọ?’ “Nípa sísọ pé tábìlì OLúWA di ẹ̀gàn. Nígbà tí ẹ̀yin mú afọ́jú ẹran wá fún ìrúbọ, ṣé èyí kò ha burú bí? Nígbà tí ẹ̀yin fi amúnkùn ún àti aláìsàn ẹran rú ẹbọ, ṣé èyí kò ha burú gidigidi bí? Ẹ dán an wò, ẹ fi wọ́n rú ẹbọ sí àwọn baálẹ̀ yín! Ṣé inú rẹ̀ yóò dùn sí yín? Ṣé yóò gbà yín?” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Ní ìsinsin yìí, ẹ bẹ Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú irú àwọn ẹbọ wọ̀nyí láti ọwọ́ yín wá, ṣé yóò gbà yín?” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí.