Luk 8:43-46
Luk 8:43-46 Bibeli Mimọ (YBCV)
Obinrin kan ti o si ni isun ẹ̀jẹ lati igba ọdún mejila, ti o ná ohun gbogbo ti o ni fun awọn oniṣegun, bẹ̃ni a ko le mu u larada lati ọwọ́ ẹnikan wá, O wá lẹhin rẹ̀, o fi ọwọ́ tọ́ iṣẹti aṣọ rẹ̀: lọgan ni isun ẹ̀jẹ rẹ̀ si ti gbẹ. Jesu si wipe, Tali o fi ọwọ́ tọ́ mi? Nigbati gbogbo wọn sẹ́, Peteru ati awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ wipe, Olukọni, awọn enia nhá ọ li àye, nwọn si mbilù ọ, iwọ si wipe, Tali o fi ọwọ́ kàn mi? Jesu si wipe, Ẹnikan fi ọwọ́ kàn mi: nitoriti emi mọ̀ pe aṣẹ jade lara mi.
Luk 8:43-46 Yoruba Bible (YCE)
Obinrin kan wà tí nǹkan oṣù rẹ̀ kọ̀, tí kò dá fún ọdún mejila. Ó ti ná gbogbo ohun tí ó ní fún àwọn oníṣègùn ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò lè wò ó sàn. Ó bá gba ẹ̀yìn wá, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí ẹ̀wù Jesu, lẹsẹkẹsẹ ìsun ẹ̀jẹ̀ náà bá dá lára rẹ̀. Jesu ní, “Ta ni fọwọ́ kàn mí?” Nígbà tí gbogbo wọn sẹ́, Peteru ní, “Ọ̀gá, mélòó-mélòó ni àwọn eniyan tí wọn ń fún ọ, tí wọn ń tì ọ́?” Ṣugbọn Jesu tún tẹnu mọ́ ọn pé, “Ẹnìkan fọwọ́ kàn mí sẹ́ẹ̀, nítorí mo mọ̀ pé agbára ti ara mi jáde.”
Luk 8:43-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Obìnrin kan tí ó sì ní ìsun ẹ̀jẹ̀ láti ìgbà ọdún méjìlá, tí ó ná ohun gbogbo tí ó ní fún àwọn oníṣègùn, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó lè mú un láradá, Ó wá sí ẹ̀yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ tọ́ ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀; lọ́gán ni ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ti gbẹ. Jesu sì wí pé, “Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mí?” Nígbà tí gbogbo wọn sẹ́ Peteru àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sọ pé, “Olùkọ́, àwọn ènìyàn ko ní ààyè, wọ́n sì ń kọlù ọ́, ìwọ sì wí pé, Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mi?” Jesu sì wí pé, “Ẹnìkan fi ọwọ́ kàn mí: nítorí tí èmí mọ̀ pé, àṣẹ jáde lára mi.”