Luk 8:40-45
Luk 8:40-45 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, nigbati Jesu pada lọ, awọn enia tẹwọgbà a: nitoriti gbogbo nwọn ti nreti rẹ̀. Si kiyesi i, ọkunrin kan ti a npè ni Jairu, ọkan ninu awọn olori sinagogu, o wá: o si wolẹ lẹba ẹsẹ Jesu, o bẹ̀ ẹ pe, ki o máṣai wá si ile on: Nitori o ni ọmọbinrin kanṣoṣo, ọmọ ìwọn ọdún mejila, o nkú lọ. Bi o si ti nlọ awọn enia nhá a li àye. Obinrin kan ti o si ni isun ẹ̀jẹ lati igba ọdún mejila, ti o ná ohun gbogbo ti o ni fun awọn oniṣegun, bẹ̃ni a ko le mu u larada lati ọwọ́ ẹnikan wá, O wá lẹhin rẹ̀, o fi ọwọ́ tọ́ iṣẹti aṣọ rẹ̀: lọgan ni isun ẹ̀jẹ rẹ̀ si ti gbẹ. Jesu si wipe, Tali o fi ọwọ́ tọ́ mi? Nigbati gbogbo wọn sẹ́, Peteru ati awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ wipe, Olukọni, awọn enia nhá ọ li àye, nwọn si mbilù ọ, iwọ si wipe, Tali o fi ọwọ́ kàn mi?
Luk 8:40-45 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jesu pada dé, àwọn eniyan fi tayọ̀tayọ̀ gbà á, nítorí gbogbo wọn ti ń retí rẹ̀. Ọkunrin kan tí ó ń jẹ́ Jairu, tí ó jẹ́ alákòóso ilé ìpàdé, wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó wólẹ̀ níwájú Jesu, ó bẹ̀ ẹ́ pé kí ó bá òun kálọ sí ilé, nítorí ọmọdebinrin rẹ̀ kan ṣoṣo tí ó ní ń kú lọ. Ọmọ yìí tó ọmọ ọdún mejila. Bí Jesu ti ń lọ àwọn eniyan ń bì lù ú níhìn-ín lọ́hùn-ún. Obinrin kan wà tí nǹkan oṣù rẹ̀ kọ̀, tí kò dá fún ọdún mejila. Ó ti ná gbogbo ohun tí ó ní fún àwọn oníṣègùn ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò lè wò ó sàn. Ó bá gba ẹ̀yìn wá, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí ẹ̀wù Jesu, lẹsẹkẹsẹ ìsun ẹ̀jẹ̀ náà bá dá lára rẹ̀. Jesu ní, “Ta ni fọwọ́ kàn mí?” Nígbà tí gbogbo wọn sẹ́, Peteru ní, “Ọ̀gá, mélòó-mélòó ni àwọn eniyan tí wọn ń fún ọ, tí wọn ń tì ọ́?”
Luk 8:40-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì ṣe, nígbà tí Jesu padà lọ, àwọn ènìyàn tẹ́wọ́gbà á; nítorí tí gbogbo wọn ti ń retí rẹ̀. Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jairu, ọ̀kan nínú àwọn olórí Sinagọgu wá; ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó wá sí ilé òun: Nítorí ó ní ọmọbìnrin kan ṣoṣo, ọmọ ìwọ̀n ọdún méjìlá, ti ó ń kú lọ. Bí ó sì ti ń lọ àwọn ènìyàn ko fun ni ààyè. Obìnrin kan tí ó sì ní ìsun ẹ̀jẹ̀ láti ìgbà ọdún méjìlá, tí ó ná ohun gbogbo tí ó ní fún àwọn oníṣègùn, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó lè mú un láradá, Ó wá sí ẹ̀yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ tọ́ ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀; lọ́gán ni ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ti gbẹ. Jesu sì wí pé, “Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mí?” Nígbà tí gbogbo wọn sẹ́ Peteru àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sọ pé, “Olùkọ́, àwọn ènìyàn ko ní ààyè, wọ́n sì ń kọlù ọ́, ìwọ sì wí pé, Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mi?”