Luk 7:1-35
Luk 7:1-35 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI o si pari gbogbo ọ̀rọ rẹ̀ li eti awọn enia, o wọ̀ Kapernaumu lọ. Ọmọ-ọdọ balogun ọrún kan, ti o ṣọwọn fun u, o ṣaisàn, o nkú lọ. Nigbati o si gburó Jesu, o rán awọn agbagba Ju si i, o mbẹ̀ ẹ pe, ki o máṣai wá mu ọmọ-ọdọ on larada. Nigbati nwọn si de ọdọ Jesu, nwọn fi itara bẹ̀ ẹ, wipe, O yẹ li ẹniti on iba ṣe eyi fun: Nitoriti o fẹran orilẹ-ede wa, o si ti kọ́ sinagogu kan fun wa. Jesu si mba wọn lọ. Nigbati kò si jìn si eti ile mọ́, balogun ọrún na rán awọn ọrẹ́ si i, wipe, Oluwa, má yọ ara rẹ lẹnu: nitoriti emi kò to ti iwọ iba fi wọ̀ abẹ orule mi: Nitorina emi kò si rò pe emi na yẹ lati tọ̀ ọ wá: ṣugbọn sọ ni gbolohùn kan, a o si mu ọmọ-ọdọ mi larada. Nitori emi na pẹlu jẹ ẹniti a fi si abẹ aṣẹ, ti o li ọmọ-ogun li ẹhin mi, mo wi fun ọkan pe, Lọ, a si lọ; ati fun omiran pe, Wá, a si wá; ati fun ọmọ-ọdọ mi pe, Ṣe eyi, a si ṣe e. Nigbati Jesu gbọ́ nkan wọnni, ẹnu yà a si i, o si yipada si ijọ enia ti ntọ̀ ọ lẹhin, o wipe, Mo wi fun nyin, emi kò ri irú igbagbọ́ nla bi eyi ninu awọn enia Israeli. Nigbati awọn onṣẹ si pada rè ile, nwọn ba ọmọ-ọdọ na ti nṣaisàn, ara rẹ̀ ti da. O si ṣe ni ijọ keji, o lọ sí ilu kan ti a npè ni Naini; awọn pipọ ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si mba a lọ ati ọ̀pọ ijọ enia. Bi o si ti sunmọ ẹnu bode ilu na, si kiyesi i, nwọn ngbé okú kan jade, ọmọ kanṣoṣo na ti iya rẹ̀, o si jẹ opó: ọ̀pọ ijọ enia ilu na si wà pẹlu rẹ̀. Nigbati Oluwa si ri i, ãnu rẹ̀ ṣe e, o si wi fun u pe, Má sọkun mọ́. O si wá, o si fi ọwọ́ tọ́ aga posi na: awọn ti si nrù u duro jẹ. O si wipe, Ọdọmọkunrin, mo wi fun ọ, Dide. Ẹniti o kú na si dide joko, o bẹ̀rẹ si ohùn ifọ̀. O si fà a le iya rẹ̀ lọwọ. Ẹ̀rù si ba gbogbo wọn: nwọn si nyìn Ọlọrun logo, wipe, Woli nla dide ninu wa; ati pe, Ọlọrun si wa ibẹ̀ awọn enia rẹ̀ wò. Okikí rẹ̀ si kàn ni gbogbo Judea, ati gbogbo àgbegbe ti o yiká. Awọn ọmọ-ẹhin Johanu si fi ninu gbogbo nkan wọnyi hàn fun u. Nigbati Johanu si pè awọn meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o rán wọn sọdọ Jesu, wipe, Iwọ li ẹniti mbọ̀, tabi ki a ma reti ẹlomiran? Nigbati awọn ọkunrin na si de ọdọ rẹ̀, nwọn ni, Johanu Baptisti rán wa sọdọ rẹ, wipe, Iwọ li ẹniti mbọ̀, tabi ki a ma reti ẹlomiran? Ni wakati na, o si ṣe dida ara ọpọlọpọ enia ninu aisan, ati arun, ati ẹmi buburu; o si fi iriran fun ọpọlọpọ awọn afọju. Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ, ẹ ròhin nkan ti ẹnyin ri, ti ẹnyin si gbọ́ fun Johanu: awọn afọju nriran, awọn amukun nrìn ṣaṣa, a sọ awọn adẹtẹ̀ di mimọ́, awọn aditi ngbọran, a njí awọn okú dide, ati fun awọn òtoṣi li a nwasu ihinrere. Alabukun-fun si li ẹnikẹni ti ki yio kọsẹ̀ lara mi. Nigbati awọn onṣẹ Johanu pada lọ, o bẹ̀rẹ si isọ fun ijọ enia niti Johanu pe, Kili ẹnyin jade rè ijù lọ iwò? ifefe ti afẹfẹ nmì? Ṣugbọn kili ẹnyin jade lọ iwò? ọkunrin ti a wọ̀ li aṣọ fẹlẹfẹlẹ? wò o, awọn ti a wọ̀ li aṣọ ogo, ti nwọn si njaiye, mbẹ li afin ọba. Ṣugbọn kili ẹnyin jade lọ iwò? woli? lõtọ ni mo wi fun nyin, o si jù woli lọ. Eyiyi li ẹniti a ti kọwe nitori rẹ̀ pe, Wò o, mo rán onṣẹ mi siwaju rẹ, ẹniti yio tún ọ̀na rẹ ṣe niwaju rẹ. Mo wi fun nyin, ninu awọn ti a bí ninu obinrin, kò si woli ti o pọ̀ju Johanu Baptisti lọ: ṣugbọn ẹniti o kerejulọ ni ijọba Ọlọrun, o pọ̀ju u lọ. Gbogbo awọn enia ti o gbọ́ ati awọn agbowode, nwọn da Ọlọrun lare, nitori a ti fi baptismu Johanu baptisi wọn. Ṣugbọn awọn Farisi ati awọn amofin kọ ìmọ Ọlọrun fun ara wọn, a kò baptisi wọn lọdọ rẹ̀. Oluwa si wipe, Kili emi iba fi awọn enia iran yi wé? kini nwọn si jọ? Nwọn dabi awọn ọmọ kekere ti o joko ni ibi ọjà, ti nwọn si nkọ si ara wọn, ti nwọn si nwipe, Awa fùn fère fun nyin, ẹnyin kò jó; awa si ṣọ̀fọ fun nyin, ẹnyin kò sọkun. Nitori Johanu Baptisti wá, kò jẹ akara, bẹ̃ni kò si mu ọti-waini; ẹnyin si wipe, O li ẹmi èṣu. Ọmọ-enia de, o njẹ, o si nmu; ẹnyin si wipe, Wò o, ọjẹun, ati ọmuti, ọrẹ́ awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ! Ṣugbọn a da ọgbọ́n lare lati ọdọ awọn ọmọ rẹ̀ gbogbo wá.
Luk 7:1-35 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jesu parí ọ̀rọ̀ tí ó ń bá àwọn eniyan sọ, ó wọ inú ìlú Kapanaumu lọ. Ọ̀gágun kan ní ẹrú kan tí ó ṣàìsàn, ó fẹ́rẹ̀ kú. Ẹrú náà ṣe ọ̀wọ́n fún un. Nígbà tí ó gbọ́ nípa Jesu, ó rán àwọn àgbààgbà Juu kan sí i pé kí wọn bá òun bẹ̀ ẹ́ kí ó wá wo ẹrú òun sàn. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó tètè. Wọ́n ní, “Ọ̀gágun náà yẹ ní ẹni tí o lè ṣe èyí fún, nítorí ó fẹ́ràn orílẹ̀-èdè wa, òun fúnrarẹ̀ ni ó kọ́ ilé ìpàdé fún wa.” Jesu bá ń bá wọn lọ. Ṣugbọn nígbà tí ó ṣì wà ní ọ̀nà jíjìn sí ilé ọ̀gágun náà, ọ̀gágun náà rán àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sí Jesu kí wọ́n sọ pé, “Alàgbà, má ṣe ìyọnu. Èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ìbá wọ ilé rẹ̀. Òun ni kò jẹ́ kí èmi fúnra mi wá sọ́dọ̀ rẹ. Ṣugbọn sọ gbolohun kan, ara ọmọ-ọ̀dọ̀ mi yóo sì dá. Nítorí èmi náà jẹ́ ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ. Mo ní àwọn ọmọ-ogun lábẹ́ mi. Bí mo bá sọ fún ọ̀kan pé, ‘Lọ!’ Yóo lọ ni. Bí mo bá sì sọ fún òmíràn pé, ‘Wá!’ Yóo wá ni. Bí mo bá sọ fún ẹrú mi pé, ‘Ṣe èyí!’ Yóo ṣe é ni.” Nígbà tí Jesu gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹnu yà á. Ó bá yipada sí àwọn eniyan tí ó ń tẹ̀lé e, ó ní, “Mò ń sọ fun yín, n kò rí irú igbagbọ báyìí ní Israẹli pàápàá!” Nígbà tí àwọn tí ọ̀gágun rán pada dé ilé, wọ́n rí ẹrú náà tí ara rẹ̀ ti dá. Láìpẹ́ lẹ́yìn èyí, Jesu lọ sí ìlú kan tí ń jẹ́ Naini. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati ọ̀pọ̀ eniyan ń bá a lọ. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ ẹnu odi ìlú náà, wọ́n rí òkú ọmọ kan tí wọn ń gbé jáde. Ọmọ yìí nìkan náà ni ìyá rẹ̀ bí. Opó sì ni ìyá náà. Ọ̀pọ̀ àwọn eniyan láti inú ìlú wá pẹlu obinrin náà. Nígbà tí Oluwa rí obinrin náà, àánú rẹ̀ ṣe é. Ó sọ fún un pé, “Má sunkún mọ́.” Ni ó bá lọ, ó fi ọwọ́ kan pósí. Àwọn tí wọ́n gbé pósí bá dúró. Ó bá sọ pé, “Ọdọmọkunrin, mo sọ fún ọ, dìde.” Ọdọmọkunrin tí ó ti kú yìí bá dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀. Jesu bà fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́. Ẹ̀rù ba gbogbo eniyan, wọ́n fi ògo fún Ọlọrun, wọ́n ní, “Wolii ńlá ti dìde ni ààrin wa. Ọlọrun ti bojúwo àwọn eniyan rẹ̀.” Ìròyìn ohun tí ó ṣe yìí tàn ká gbogbo Judia ati gbogbo agbègbè ibẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ròyìn gbogbo nǹkan wọnyi fún un. Johanu bá pe meji ninu wọn, ó rán wọn sí Oluwa láti bi í pé, “Ṣé ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀ ni, tabi kí á máa retí ẹlòmíràn?” Nígbà tí àwọn ọkunrin náà dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n ní, “Johanu Onítẹ̀bọmi ni ó rán wa sí ọ láti bi ọ́ pé, ‘Ṣé ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀ ni, tabi kí á máa retí ẹlòmíràn?’ ” Ní àkókò náà, Jesu ń wo ọpọlọpọ eniyan sàn ninu àìsàn ati àrùn. Ó ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọpọlọpọ àwọn afọ́jú ni ó jẹ́ kí wọ́n ríran. Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ lọ sọ ohun tí ẹ rí ati ohun tí ẹ gbọ́ fún Johanu: àwọn afọ́jú ń ríran; àwọn arọ ń rìn, ara àwọn adẹ́tẹ̀ ń di mímọ́; àwọn adití ń gbọ́ràn, à ń jí àwọn òkú dìde; à ń waasu ìyìn rere fún àwọn talaka. Ẹni tí kò bá ṣiyèméjì nípa mi ṣe oríire!” Lẹ́yìn tí àwọn oníṣẹ́ Johanu lọ tán, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ nípa Johanu fún àwọn eniyan. Ó ní, “Kí ni ẹ jáde lọ wò ní aṣálẹ̀? Igi légbélégbé tí afẹ́fẹ́ ń tì sọ́tùn-ún, ati sósì ni bí? Kí ni ẹ jáde lọ wò? Ọkunrin tí ó wọ aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ olówó iyebíye ni bí? Bí ẹ bá fẹ́ rí àwọn tí ó wọ aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ olówó iyebíye, ẹ lọ sí ààfin ọba. Àní, kí ni ẹ lọ wò? Wolii ni bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Mo sọ fun yín, ó tilẹ̀ ju wolii lọ! Òun ni a kọ nípa rẹ̀ pé, ‘Wò ó! Mo rán oníṣẹ́ mi ṣiwaju rẹ, òun ni yóo palẹ̀ mọ́ dè ọ́.’ Mo sọ fun yín pé, kò sí ẹnikẹ́ni jákèjádò ayé yìí tí ó ṣe pataki ju Johanu lọ. Sibẹ, ẹni tí ó kéré jùlọ ninu ìjọba ọ̀run ṣe pataki jù ú lọ.” Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan gbọ́, tí ó fi mọ́ àwọn agbowó-odè pàápàá, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọrun, wọ́n lọ ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ètò ìrìbọmi Johanu. Ṣugbọn àwọn Farisi ati àwọn amòfin kọ ìlànà Ọlọrun fún wọn, wọn kò ṣe ìrìbọmi ti Johanu. Jesu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ̀, ó ní, “Ta ni èmi ìbá fi àwọn eniyan òde òní wé? Ta ni kí a wí pé wọ́n jọ? Wọ́n jọ àwọn ọmọde tí wọ́n jókòó ní ọjà. Àwọn kan ń pe àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn pé, ‘A lù fun yín, ẹ kò jó, A sun rárà òkú fun yín, ẹ kò sunkún.’ Nítorí Johanu Onítẹ̀bọmi dé, kò jẹ, kò mu, ẹ sọ pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù ni.’ Ọmọ-Eniyan dé, ó ń jẹ, ó ń mu, ẹ ní, ‘Ẹ kò rí ọkunrin yìí, oníjẹkújẹ ati ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’ Sibẹ a mọ̀ pé ọgbọ́n Ọlọrun tọ̀nà nípa ìṣesí gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀.”
Luk 7:1-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ó sì parí gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ fun àwọn ènìyàn, ó wọ Kapernaumu lọ. Ọmọ ọ̀dọ̀ balógun ọ̀rún kan, tí ó ṣọ̀wọ́n fún un, ṣàìsàn, ó sì ń kú lọ. Nígbà tí ó sì gbúròó Jesu, ó rán àwọn àgbàgbà Júù sí i, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá mú ọmọ ọ̀dọ̀ òun láradá. Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n fi ìtara bẹ̀ ẹ́, pé, “Ó yẹ ní ẹni tí òun ìbá ṣe èyí fún: Nítorí tí ó fẹ́ràn orílẹ̀-èdè wa, ó sì ti kọ́ Sinagọgu kan fún wa.” Jesu sì ń bá wọn lọ. Nígbà tí kò sì jìn sí etí ilé mọ́, balógun ọ̀rún náà rán àwọn ọ̀rẹ́ sí i, pé, “Olúwa, má ṣe yọ ara rẹ lẹ́nu: nítorí tí èmi kò yẹ tí ìwọ ìbá fi wọ abẹ́ òrùlé mi: Nítorí náà èmi kò sì rò pé èmi náà yẹ láti tọ̀ ọ́ wá: ṣùgbọ́n sọ ní gbólóhùn kan, a ó sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ mi láradá. Nítorí èmi náà pẹ̀lú jẹ́ ẹni tí a fi sí abẹ́ àṣẹ, tí ó ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi, mo sì wí fún ọ̀kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ; àti fún òmíràn pé, ‘Wá,’ a sì wá; àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.” Nígbà tí Jesu gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu sì yà, ó sì yípadà sí ìjọ ènìyàn tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó wí pé, “Mo wí fún yín pé èmi kò rí irú ìgbàgbọ́ ńlá bí èyí nínú àwọn ènìyàn Israẹli.” Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ sì padà sí ilé, wọ́n bá ọmọ ọ̀dọ̀ náà tí ń ṣàìsàn, ara rẹ̀ ti dá. Ní ọjọ́ kejì, ó lọ sí ìlú kan tí a ń pè ní Naini, àwọn púpọ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń bá a lọ àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn. Bí ó sì ti súnmọ́ ẹnu ibodè ìlú náà, sì kíyèsi i, wọ́n ń gbé òkú ọkùnrin kan jáde, ọmọ kan ṣoṣo náà tí ìyá rẹ̀ bí, ó sì jẹ́ opó: ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ìlú náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí Olúwa sì rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé, “Má sọkún mọ́.” Ó sì wá, ó sì fi ọwọ́ tọ́ pósí náà: àwọn tí ń rù ú dúró jẹ́. Ó sì wí pé, “Ọ̀dọ́mọkùnrin, mo wí fún ọ, dìde!” Ẹni tí ó kú náà sì dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí i fọhùn. Ó sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́. Ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn: wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, pé, “Wòlíì ńlá dìde nínú wa,” àti pé, “Ọlọ́run sì wá bẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò!” Òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo Judea, àti gbogbo agbègbè tí ó yí i ká. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu sì sọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún un. Nígbà tí Johanu sì pe àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rán wọn sọ́dọ̀ Olúwa, wí pé, “ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?” Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé, “Johanu onítẹ̀bọmi rán wa sọ́dọ̀ rẹ, pé, ‘Ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?’ ” Ní wákàtí náà, ó sì ṣe ìmúláradá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú àìsàn, àti ààrùn, àti ẹ̀mí búburú; ó sì fi ìríran fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn afọ́jú. Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹ padà lọ, ẹ ròyìn nǹkan tí ẹ̀yin rí, tí ẹ̀yin sì gbọ́ fún Johanu: àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúnkùn ún rìn, a sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́rọ̀, a ń jí àwọn òkú dìde, àti fún àwọn òtòṣì ni à ń wàásù ìhìnrere. Alábùkún fún sì ni ẹnikẹ́ni tí kò kọsẹ̀ lára mi.” Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Johanu padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ìjọ ènìyàn ní ti Johanu pé, “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ sí ijù lọ wò? Ewéko tí afẹ́fẹ́ ń mì? Ṣùgbọ́n kín ni ẹ̀yin jáde lọ wò? Ọkùnrin tí a wọ̀ ní aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́? Wò ó, àwọn tí á wọ̀ ní aṣọ ògo, tí wọ́n sì ń jayé, ń bẹ ní ààfin ọba! Ṣùgbọ́n kí ni ẹ̀yin jáde lọ wò? Wòlíì? Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ! Èyí yìí ni ẹni tí a ti kọ̀wé nítorí rẹ̀ pé: “ ‘Wò ó, èmi yóò rán oníṣẹ́ mi síwájú rẹ; ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe níwájú rẹ.’ Mo wí fún yín nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí wòlíì tí ó pọ̀ ju Johanu Onítẹ̀bọmi lọ: ṣùgbọ́n ẹni tí ó kéré jùlọ ní ìjọba Ọlọ́run, ó pọ̀jù ú lọ.” (Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó gbọ́ àti àwọn agbowó òde, wọ́n dá Ọlọ́run láre, nítorí tí a fi ìtẹ̀bọmi Johanu tẹ̀ wọn bọ mi. Ṣùgbọ́n àwọn Farisi àti àwọn amòfin kọ ète Ọlọ́run fún ara wọn, a kò bamitiisi wọn lọ́dọ̀ rẹ̀.) Olúwa sì wí pé, “Kí ni èmi ìbá fi àwọn ènìyàn ìran yìí wé? Kí ni wọ́n sì jọ? Wọ́n dàbí àwọn ọmọ kékeré tí ó jókòó ní ibi ọjà, tí wọ́n sì ń kọ sí ara wọn, tí wọ́n sì ń wí pé: “ ‘Àwa fọn fèrè fún yín, ẹ̀yin kò jó àwa sì ṣọ̀fọ̀ fún yín, ẹ̀yin kò sọkún!’ Nítorí Johanu Onítẹ̀bọmi wá, kò jẹ àkàrà, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu ọtí wáìnì; ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù?’ Ọmọ ènìyàn dé, ó ń jẹ, ó sì ń mu; ẹ̀yin sì wí pé, ‘Wò ó, ọ̀jẹun, àti ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn “ẹlẹ́ṣẹ̀!” ’ Ṣùgbọ́n ọgbọ́n ni a dá láre nípasẹ̀ ọmọ rẹ.”