Luk 6:43-45
Luk 6:43-45 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori igi rere kì iso eso buburu; bẹ̃ni igi buburu kì iso eso rere. Olukuluku igi li a ifi eso rẹ̀ mọ̀; nitori lori ẹgún oṣuṣu, enia kì iká eso ọpọtọ bẹ̃ni lori ẹgún ọgàn a kì iká eso ajara. Enia rere lati inu iṣura rere ọkàn rẹ̀ ni imu ohun rere jade wá; ati enia buburu lati inu iṣura buburu ọkàn rẹ̀ ni imu ohun buburu jade wá: nitori lati ọ̀pọlọpọ ohun ọkàn li ẹnu rẹ̀ isọ.
Luk 6:43-45 Yoruba Bible (YCE)
“Igi rere kò lè so èso burúkú. Bẹ́ẹ̀ ni igi burúkú kò lé so èso rere. Èso tí igi kan bá so ni a óo fi mọ̀ ọ́n. Nítorí eniyan kò lè ká èso ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi ẹlẹ́gùn-ún. Bẹ́ẹ̀ ni eniyan kò lè rí èso ọsàn lórí igi ọdán. Eniyan rere ń mú ohun rere wá láti inú orísun rere ọkàn rẹ̀. Eniyan burúkú ń mú nǹkan burúkú jáde láti inú ọkàn burúkú rẹ̀. Nítorí ohun tí ó bá wà ninu ọkàn ẹni ni ẹnu ẹni ń sọ jáde.
Luk 6:43-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
“Nítorí igi rere kì í so èso búburú; bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kì í so èso rere. Olúkúlùkù igi ni a ń fi èso rẹ̀ mọ̀ ọn; nítorí lórí ẹ̀gún òṣùṣú, ènìyàn kì í ká èso ọ̀pọ̀tọ́ bẹ́ẹ̀ ni lórí ẹ̀gún ọ̀gàn a kì í ká èso àjàrà. Ènìyàn rere láti inú yàrá ìṣúra rere ọkàn rẹ̀ ní mú ohun rere jáde wá; àti ènìyàn búburú láti inú ìṣúra búburú ọkàn rẹ̀ ní í mú ohun búburú jáde wá: nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọkàn ní ẹnu ti máa sọ jáde.