Luk 4:1-41
Luk 4:1-41 Bibeli Mimọ (YBCV)
JESU si kún fun Ẹmí Mimọ́, o pada ti Jordani wá, a si ti ọwọ́ Ẹmí dari rẹ̀ si ijù; Ogoji ọjọ li a fi dán a wò lọwọ Èṣu. Kò si jẹ ohunkohun li ọjọ wọnni: nigbati nwọn si pari, lẹhinna li ebi wá npa a. Eṣu si wi fun u pe, Bi iwọ ba ṣe Ọmọ Ọlọrun, paṣẹ fun okuta yi ki o di akara. Jesu si dahùn wi fun u pe, A ti kọwe rẹ pe, Enia kì yio wà lãye nipa akara nikan, bikoṣe nipa gbogbo ọ̀rọ Ọlọrun. Èṣu si mu u re ori òke giga, o si fi gbogbo ilẹ-ọba aiye hàn a ni iṣẹju kan. Èṣu si wi fun u pe, Iwọ li emi o fi gbogbo agbara yi ati ogo wọn fun: gbogbo rẹ̀ li a sá ti fifun mi; ẹnikẹni ti o ba si wù mi, emi a fi i fun. Njẹ bi iwọ ba foribalẹ fun mi, gbogbo rẹ̀ ni yio jẹ tirẹ. Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Kuro lẹhin mi, Satani, nitoriti a kọwe rẹ̀ pe, Iwọ foribalẹ fun Oluwa Ọlọrun rẹ, on nikanṣoṣo ni ki iwọ ki o si ma sìn. O si mu u lọ si Jerusalemu, o si gbé e le ṣonṣo tẹmpili, o si wi fun u pe, Bi iwọ ba ṣe Ọmọ Ọlọrun, bẹ́ silẹ fun ara rẹ lati ihinyi lọ: A sá ti kọwe rẹ̀ pe, Yio paṣẹ fun awọn angẹli rẹ̀ nitori rẹ, lati ma ṣe itọju rẹ: Ati pe li ọwọ́ wọn ni nwọn o gbé ọ soke, ki iwọ ki o má ba fi ẹsẹ rẹ gbún okuta. Jesu si dahùn o wi fun u pe, A ti sọ pe, Iwọ kò gbọdọ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò. Nigbati Èṣu si pari idanwò na gbogbo, o fi i silẹ lọ di sã kan. Jesu si fi agbara Ẹmí pada wá si Galili: okikí rẹ̀ si kàn kalẹ ni gbogbo àgbegbe ti o yiká. O si nkọni ninu sinagogu wọn; a nyìn i logo lati ọdọ gbogbo awọn enia wá. O si wá si Nasareti, nibiti a gbé ti tọ́ ọ dàgba: bi iṣe rẹ̀ ti ri, o si wọ̀ inu sinagogu lọ li ọjọ isimi, o si dide lati kàwe. A si fi iwe woli Isaiah fun u. Nigbati o si ṣí iwe na, o ri ibiti a gbé kọ ọ pe, Ẹmi Oluwa mbẹ lara mi, nitoriti o fi àmi oróro yàn mi lati wasu ihinrere fun awọn òtoṣi; o ti rán mi wá lati ṣe iwosan awọn ọkàn onirobinujẹ, lati wasu idasilẹ fun awọn igbekun, itunriran fun awọn afọju, ati lati jọwọ awọn ti a pa lara lọwọ. Lati kede ọdún itẹwọgba Oluwa. O si pa iwe na de, o tun fi i fun iranṣẹ, o si joko. Gbogbo awọn ti o mbẹ ninu sinagogu si tẹjumọ ọ. O si bẹ̀rẹ si iwi fun wọn pe, Loni ni Iwe-mimọ yi ṣẹ li etí nyin. Gbogbo wọn si jẹri rẹ̀, ha si ṣe wọn si ọ̀rọ ore-ọfẹ ti njade li ẹnu rẹ̀. Nwọn si wipe, Ọmọ Josefu kọ́ yi? O si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin o pa owe yi si mi pe, Oniṣegun, wò ara rẹ sàn: ohunkohun ti awa gbọ́ pe o ti ọwọ́ rẹ ṣe ni Kapernaumu, ṣe e nihinyi pẹlu ni ilẹ ara rẹ. O si wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Kò si woli ti a tẹwọgbà ni ilẹ baba rẹ̀. Ṣugbọn mo wi fun nyin nitõtọ, opó pipọ li o wà ni Israeli nigba ọjọ woli Elijah, nigbati ọrun fi sé li ọdún mẹta on oṣù mẹfa, nigbati ìyan nla fi mu ká ilẹ gbogbo; Kò si si ẹnikan ninu wọn ti a rán Elijah si, bikoṣe si obinrin opó kan ni Sarefati, ilu kan ni Sidoni. Ati adẹtẹ̀ pipọ ni mbẹ ni Israeli nigba woli Eliṣa; kò si si ọkan ninu wọn ti a wẹnumọ́, bikoṣe Naamani ara Siria. Nigbati gbogbo awọn ti o wà ninu sinagogu gbọ́ nkan wọnyi, inu ru wọn ṣùṣù, Nwọn si dide, nwọn tì i sode si ẹhin ilu, nwọn si fà a lọ si bèbe òke nibiti nwọn gbé tẹ̀ ilu wọn do, ki nwọn ba le tari rẹ̀ li ogedengbe. Ṣugbọn o kọja larin wọn, o ba tirẹ̀ lọ. O si sọkalẹ wá si Kapernaumu, ilu kan ni Galili, o si nkọ́ wọn li ọjọ isimi. Ẹnu si yà wọn si ẹkọ́ rẹ̀: nitori taṣẹ-taṣẹ li ọ̀rọ rẹ̀. Ọkunrin kan si wà ninu sinagogu, ẹniti o li ẹmi aimọ́, o kigbe li ohùn rara, O ni, Jọwọ wa jẹ; kini ṣe tawa tirẹ, Jesu ara Nasareti? iwọ wá lati pa wa run? emi mọ̀ ẹniti iwọ iṣe; Ẹni Mimọ́ Ọlọrun. Jesu si ba a wi, o ni, Pa ẹnu rẹ mọ́, ki o si jade lara rẹ̀. Nigbati ẹmí eṣu na si gbé e ṣanlẹ li awujọ, o jade kuro lara rẹ̀, kò si pa a lara. Hà si ṣe gbogbo wọn nwọn si mba ara wọn sọ, wipe, Ọ̀rọ kili eyi! nitori pẹlu aṣẹ ati agbara li o fi ba awọn ẹmi aimọ́ wi, nwọn si jade kuro. Okikí rẹ̀ si kàn nibi gbogbo li àgbegbe ilẹ na yiká. Nigbati o si dide kuro ninu sinagogu, o si wọ̀ ile Simoni lọ; ibà si ti dá iya aya Simoni bulẹ; nwọn si bẹ̀ ẹ nitori rẹ̀. O si duro tirisi i, o ba ibà na wi; ibà si jọwọ rẹ̀ lọwọ: o si dide lọgan, o nṣe iranṣẹ fun wọn. Nigbati õrùn si nwọ̀, gbogbo awọn ẹniti o ni olokunrun ti o li arunkarun, nwọn mu wọn tọ̀ ọ wá; o si fi ọwọ́ le olukuluku wọn, o si mu wọn larada. Awọn ẹmi eṣu si jade lara ẹni pipọ pẹlu, nwọn nkigbe, nwọn si nwipe, Iwọ ni Kristi Ọmọ Ọlọrun. O si mba wọn wi, kò si jẹ ki nwọn ki o fọhun: nitoriti nwọn mọ̀ pe Kristi ni iṣe.
Luk 4:1-41 Yoruba Bible (YCE)
Jesu pada láti odò Jọdani, ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀mí bá darí rẹ̀ lọ sí aṣálẹ̀. Ogoji ọjọ́ ni èṣù fi dán an wò. Kò jẹ ohunkohun ní gbogbo àkókò náà. Lẹ́yìn náà, ebi wá ń pa á. Èṣù sọ fún un pé, “Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni ọ́ nítòótọ́, sọ fún òkúta yìí pé kí ó di àkàrà.” Jesu dá a lóhùn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ni yóo mú kí eniyan wà láàyè.’ ” Èṣù bá mú un lọ sí orí òkè kan, ó fi gbogbo ìjọba ayé hàn án ní ìṣẹ́jú kan. Ó sọ fún Jesu pé, “Ìwọ ni n óo fún ní gbogbo àṣẹ yìí ati ògo rẹ̀, nítorí èmi ni a ti fi wọ́n lé lọ́wọ́, ẹni tí ó bá sì wù mí ni mo lè fún. Tí o bá júbà mi, tìrẹ ni gbogbo rẹ̀ yóo dà.” Jesu dá a lóhùn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Oluwa Ọlọrun rẹ ni kí o máa júbà, òun nìkan ni kí o sì máa sìn!’ ” Èṣù tún mú un lọ sí Jerusalẹmu. Ó gbé e ka téńté òrùlé Tẹmpili. Ó ní, “Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni ọ́ nítòótọ́, bẹ́ sílẹ̀ láti ìhín. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Yóo pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí rẹ pé kí wọn pa ọ́ mọ́.’ Ati pé, ‘Kí wọn tẹ́wọ́ gbà ọ́ kí o má baà fi ẹsẹ̀ gbún òkúta.’ ” Jesu dá a lóhùn pé, “A ti sọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò.’ ” Nígbà tí Satani parí gbogbo ìdánwò yìí, ó fi Jesu sílẹ̀ títí di àkókò tí ó bá tún wọ̀. Jesu pada sí Galili pẹlu agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo ìgbèríko. Ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu àwọn ilé ìpàdé wọn. Gbogbo eniyan sì ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní rere. Ó wá dé Nasarẹti, ìlú tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, nígbà tí ó di ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sí ilé ìpàdé. Ó bá dìde láti ka Ìwé Mímọ́. Wọ́n fún un ní ìwé wolii Aisaya. Nígbà tí ó ṣí i, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé, “Ẹ̀mí Oluwa wà pẹlu mi nítorí ó ti fi òróró yàn mí láti waasu ìyìn rere fún àwọn talaka. Ó rán mi láti waasu ìtúsílẹ̀ fún àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn, ati láti mú kí àwọn afọ́jú ríran; láti jẹ́ kí àwọn tí a ni lára lọ ní alaafia, ati láti waasu ọdún tí Oluwa yóo gba àwọn eniyan rẹ̀ là.” Ó bá pa ìwé náà dé, ó fi í fún olùtọ́jú ilé ìpàdé, ó bá jókòó. Gbogbo àwọn eniyan tí ó wà ninu ilé ìpàdé tẹjú mọ́ ọn; ó bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wọn pé, “Lónìí ni àkọsílẹ̀ yìí ṣẹ ní ojú yín.” Gbogbo wọn ni wọ́n gbà fún un, ẹnu sì yà wọ́n fún ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ó ń sọ jáde, wọ́n wá ń sọ pé, “Àbí ọmọ Josẹfu kọ́ nìyí ni?” Ó sọ fún wọn pé, “Ní òtítọ́ ẹ lè pa òwe yìí fún mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ sàn! Ohun gbogbo tí a gbọ́ pé o ṣe ní Kapanaumu, ṣe wọ́n níhìn-ín, ní ìlú baba rẹ.’ ” Ó tún fi kún un pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé kò sí wolii kan tíí ní iyì ní ìlú baba rẹ̀. “Òtítọ́ ni mo sọ fun yín pé opó pọ̀ ní Israẹli ní àkókò Elija, nígbà tí kò fi sí òjò fún ọdún mẹta ati oṣù mẹfa, tí ìyàn fi mú níbi gbogbo. A kò rán Elija sí ọ̀kankan ninu wọn. Ọ̀dọ̀ ẹni tí a rán an sí ni opó kan ní Sarefati ní agbègbè Sidoni. Àwọn adẹ́tẹ̀ pọ̀ ní Israẹli ní àkókò wolii Eliṣa. Kò sí ọ̀kan ninu wọn tí a wòsàn, àfi Naamani ará Siria.” Nígbà tí àwọn tí ó wà ninu ilé ìpàdé gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, inú bí gbogbo wọn. Wọ́n dìde, wọ́n tì í sẹ́yìn odi ìlú, wọ́n sì fà á lọ sí ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ibi tí ìlú wọn wà, wọ́n fẹ́ taari rẹ̀ ní ogedengbe. Ṣugbọn ó la ààrin wọn kọjá, ó bá tirẹ̀ lọ. Jesu bá lọ sí Kapanaumu, ìlú kan ní ilẹ̀ Galili. Ó ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀, nítorí pẹlu àṣẹ ni ó fi ń sọ̀rọ̀. Ọkunrin kan wà ninu ilé ìpàdé tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ó bá kígbe tòò, ó ní, “Háà! Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, Jesu ará Nasarẹti? Ṣé o wá pa wá run ni? Mo mọ ẹni tí o jẹ́. Ẹni Mímọ́ ti Ọlọrun ni ọ́.” Jesu bá bá a wí, ó ní, “Pa ẹnu mọ́, kí o jáde kúrò ninu ọkunrin yìí!” Ẹ̀mí èṣù náà bá gbé ọkunrin náà ṣánlẹ̀ lójú gbogbo wọn, ó bá jáde kúrò lára rẹ̀, láì pa á lára. Ẹnu ya gbogbo eniyan. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Irú ọ̀rọ̀ wo ni èyí? Nítorí pẹlu àṣẹ ati agbára ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí èṣù wí, wọ́n sì ń jáde!” Òkìkí Jesu sì kàn ká gbogbo ìgbèríko ibẹ̀. Nígbà tí Jesu dìde kúrò ní ilé ìpàdé, ó wọ ilé Simoni lọ. Ìyá iyawo Simoni ń ṣàìsàn akọ ibà. Wọ́n bá sọ fún Jesu. Ó bá lọ dúró lẹ́bàá ibùsùn ìyá náà, ó bá ibà náà wí, ibà sì fi ìyá náà sílẹ̀. Lẹsẹkẹsẹ ó dìde, ó bá tọ́jú oúnjẹ fún wọn. Nígbà tí oòrùn wọ̀, gbogbo àwọn tí wọ́n ní oríṣìíríṣìí àrùn ni wọ́n mú wá sọ́dọ̀ Jesu. Ó bá gbé ọwọ́ lé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ó wò wọ́n sàn. Àwọn ẹ̀mí èṣù jáde kúrò ninu ọpọlọpọ eniyan, wọ́n ń kígbe pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọrun.” Jesu ń bá wọn wí, kò jẹ́ kí wọ́n sọ̀rọ̀, nítorí wọ́n mọ̀ pé Jesu ni Mesaya.
Luk 4:1-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jesu sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó padà ti Jordani wá, a sì ti ọwọ́ Ẹ̀mí darí rẹ̀ sí ijù; Ogójì ọjọ́ ni a fi dán an wò lọ́wọ́ èṣù. Kò sì jẹ ohunkóhun ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì: nígbà tí wọ́n sì parí, lẹ́yìn náà ni ebi wá ń pa á. Èṣù sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ fún òkúta yìí kí ó di àkàrà.” Jesu sì dáhùn, ó wí fún un pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ènìyàn kì yóò wà láààyè nípa àkàrà nìkan.’ ” Lójúkan náà, èṣù sì mú un lọ sí orí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé hàn án. Èṣù sì wí fún un pé, “Ìwọ ni èmi ó fi gbogbo agbára yìí àti ògo wọn fún: nítorí á sá ti fi fún mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù mí, èmi a fi í fún. Ǹjẹ́ bí ìwọ bá foríbalẹ̀ fún mi, gbogbo rẹ̀ ni yóò jẹ́ tìrẹ.” Jesu sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Kúrò lẹ́yìn mi, Satani, nítorí tí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ìwọ foríbalẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ kí ó sì máa sìn.’ ” Èṣù sì mú un lọ sí Jerusalẹmu, ó sì gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹmpili, ó sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ láti ibí yìí: A sá ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí rẹ, láti máa ṣe ìtọ́jú rẹ: Àti pé ní ọwọ́ wọn ni wọn ó gbé ọ sókè, kí ìwọ kí ó má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ” Jesu sì dáhùn ó wí fún un pé, “A ti kọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ” Nígbà tí èṣù sì parí ìdánwò náà gbogbo, ó fi í sílẹ̀ lọ fun sá à kan. Jesu sì fi agbára Ẹ̀mí padà wá sí Galili: òkìkí rẹ̀ sì kàn kálẹ̀ ní gbogbo agbègbè tí ó yí i ká. Ó sì ń kọ́ni nínú Sinagọgu wọn; a ń yìn ín lógo láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn wá. Ó sì wá sí Nasareti, níbi tí a gbé ti tọ́ ọ dàgbà: bí ìṣe rẹ̀ ti rí, ó sì wọ inú Sinagọgu lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì dìde láti kàwé. A sì fi ìwé wòlíì Isaiah fún un. Nígbà tí ó sì ṣí ìwé náà, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé: “Ẹ̀mí Olúwa ń bẹ lára mi, Nítorí tí ó fi ààmì òróró yàn mí láti wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòṣì. Ó ti rán mi wá láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn, àti ìmúnríran fún àwọn afọ́jú, àti láti jọ̀wọ́ àwọn tí a pa lára lọ́wọ́, láti kéde ọdún ojúrere Olúwa.” Ó sì pa ìwé náà dé, ó fi í fún ìránṣẹ́, ó sì jókòó. Gbogbo àwọn tí ó ń bẹ nínú Sinagọgu sì tẹjúmọ́ ọn. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wí fún wọn pé, “Lónìí ìwé mímọ́ yìí ṣẹ ní etí yín.” Gbogbo wọn sì jẹ́rìí rẹ̀, háà sì ṣe wọ́n sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ń jáde ní ẹnu rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ọmọ Josẹfu kọ́ yìí?” Jesu sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó pa òwe yìí sí mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ̀ sàn! Àwọn ohun tí àwa gbọ́ pé o ti ọwọ́ rẹ ṣe ní Kapernaumu, ṣe é níhìn-ín yìí pẹ̀lú ní ilẹ̀ ara rẹ.’ ” Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, kò sí wòlíì tí a tẹ́wọ́gbà ní ilẹ̀ baba rẹ̀. Ṣùgbọ́n mo wí fún un yín nítòótọ́, opó púpọ̀ ni ó wà ní Israẹli nígbà ọjọ́ wòlíì Elijah, nígbà tí ọ̀run fi sé ní ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà, nígbà tí ìyàn ńlá fi mú ká ilẹ̀ gbogbo; Kò sì sí ẹnìkan nínú wọn tí a rán Elijah sí, bí kò ṣe sí obìnrin opó kan ní Sarefati, ìlú kan ní Sidoni. Adẹ́tẹ̀ púpọ̀ ní sì ń bẹ ní Israẹli nígbà wòlíì Eliṣa; kò sì ṣí ọ̀kan nínú wọn tí a wẹ̀nùmọ́, bí kò ṣe Naamani ará Siria.” Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó wà nínú Sinagọgu gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, inú bi wọ́n gidigidi, Wọ́n sì dìde, wọ́n tì í sóde sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n sì fà á lọ sí bèbè òkè níbi tí wọ́n gbé tẹ ìlú wọn dó, kí wọn bá à lè sọ sílẹ̀ ní ògèdèǹgbé. Ṣùgbọ́n ó kọjá láàrín wọn, ó bá tirẹ̀ lọ. Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Kapernaumu, ìlú kan ní Galili, ó sì ń kọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi. Ẹnu sì yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀: nítorí tàṣẹtàṣẹ ni ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọkùnrin kan sì wà nínú Sinagọgu, ẹni tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, ó kígbe ní ohùn rara, “Ó wí pé, kín ni ṣe tàwa tìrẹ, Jesu ará Nasareti? Ìwọ́ wá láti pa wá run bí? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.” Jesu sì bá a wí gidigidi, ó wí fun pe, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí o sì jáde lára rẹ̀.” Nígbà tí ẹ̀mí èṣù náà sì gbé e ṣánlẹ̀ ní àwùjọ, ó jáde kúrò lára rẹ̀, kò sì pa á lára. Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ wí pé, “irú ẹ̀kọ́ kín ni èyí? Nítorí pẹ̀lú àṣẹ àti agbára ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí àìmọ́ wí, wọ́n sì jáde kúrò.” Òkìkí rẹ̀ sì kàn níbi gbogbo ní agbègbè ilẹ̀ náà yíká. Nígbà tí ó sì dìde kúrò nínú Sinagọgu, ó sì wọ̀ ilé Simoni lọ; ibà sì ti dá ìyá ìyàwó Simoni dùbúlẹ̀, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ nítorí rẹ̀. Ó sì súnmọ́ ọ, ó bá ibà náà wí; ibà sì náà sì fi sílẹ̀. O sì dìde lọ́gán, ó ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn. Nígbà tí oòrùn sì ń wọ̀, àwọn ènìyàn gbe àwọn aláìsàn, tó ní onírúurú àìsàn wá sọ́dọ̀ Jesu; ó sì fi ọwọ́ lé olúkúlùkù wọn, ó sì mú wọn láradá. Àwọn ẹ̀mí èṣù sì jáde lára ẹni púpọ̀ pẹ̀lú, wọ́n ń kígbe, wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run!” Ó sì ń bá wọn wí kò sì jẹ́ kí wọn kí ó fọhùn: nítorí tí wọ́n mọ̀ pé òun ni Kristi náà.