Luk 24:1-12

Luk 24:1-12 Yoruba Bible (YCE)

Ní kutukutu òwúrọ̀ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, wọ́n wá sí ibojì, wọ́n mú òróró olóòórùn dídùn tí wọ́n ti tọ́jú lọ́wọ́. Wọ́n rí i pé wọ́n ti yí òkúta kúrò ní ẹnu ibojì. Nígbà tí wọ́n wọ inú ibojì, wọ́n kò rí òkú Jesu Oluwa. Bí wọ́n ti dúró tí wọn kò mọ ohun tí wọn yóo ṣe, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkunrin meji kan bá yọ sí wọn, wọ́n wọ aṣọ dídán. Ẹ̀rù ba àwọn obinrin náà, wọ́n bá dojúbolẹ̀. Àwọn ọkunrin náà wá bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń wá alààyè láàrin àwọn òkú? Kò sí níhìn-ín; ó ti jí dìde. Ẹ ranti bí ó tí sọ fun yín nígbà tí ó wà ní Galili pé, ‘Dandan ni kí á fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn eniyan burúkú lọ́wọ́, kí wọ́n kàn án mọ́ agbelebu, ati pé kí ó jí dìde ní ọjọ́ kẹta.’ ” Wọ́n wá ranti ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n bá kúrò ní ibojì náà, wọ́n pada lọ sọ gbogbo nǹkan tí wọ́n rí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọkanla ati gbogbo àwọn yòókù. Maria Magidaleni, ati Joana, ati Maria ìyá Jakọbu ati gbogbo àwọn yòókù tí ó bá wọn lọ, ni wọ́n sọ nǹkan wọnyi fún àwọn aposteli. Ṣugbọn bíi ìsọkúsọ ni gbogbo ọ̀rọ̀ yìí rí létí wọn. Wọn kò gba ohun tí àwọn obinrin náà sọ gbọ́. [ Ṣugbọn Peteru dìde, ó sáré lọ sí ibojì náà. Nígbà tí ó yọjú wo inú rẹ̀, aṣọ funfun tí wọ́n fi wé òkú nìkan ni ó rí. Ó bá pada sí ilé, ẹnu yà á sí ohun tí ó ṣẹlẹ̀.]

Luk 24:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ ọ̀sẹ̀, àwọn obìnrin wá sí ibojì, wọ́n sì mú ìkunra olóòórùn dídùn ti wọ́n tí pèsè sílẹ̀ wá. Òkúta ti yí kúrò ní ẹnu ibojì. Nígbà tí wọ́n sì wọ inú rẹ̀, wọn kò rí òkú Jesu Olúwa. Bí wọ́n ti dààmú kiri níhà ibẹ̀, kíyèsi i, àwọn ọkùnrin méjì aláṣọ dídán dúró tì wọ́n: Nígbà tí ẹ̀rù ń bà wọ́n, tí wọ́n sì dojúbolẹ̀, àwọn angẹli náà bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá alààyè láàrín àwọn òkú? Kò sí níhìn-ín yìí, ṣùgbọ́n ó jíǹde; ẹ rántí bí ó ti wí fún yín nígbà tí ó wà ní Galili. Pé, ‘A ó fi ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́, a ó sì kàn án mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta yóò sì jíǹde.’ ” Wọ́n sì rántí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n sì padà ti ibojì wá, wọ́n sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún àwọn mọ́kànlá, àti fún gbogbo àwọn ìyókù. Maria Magdalene, àti Joanna, àti Maria ìyá Jakọbu, àti àwọn mìíràn pẹ̀lú wọn sì ni àwọn tí ó ròyìn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn aposteli. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sì dàbí ìsọkúsọ lójú wọn, wọn kò sì gbà wọ́n gbọ́. Nígbà náà ni Peteru dìde, ó súré lọ sí ibojì; nígbà tí ó sì bẹ̀rẹ̀, ó rí aṣọ àlà lọ́tọ̀ fúnrawọn, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀, ẹnu yà á sí ohun tí ó ṣe.