Luk 18:18-30

Luk 18:18-30 Yoruba Bible (YCE)

Ìjòyè kan bi Jesu léèrè pé, “Olùkọ́ni rere, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?” Jesu sọ fún un pé, “Ìdí rẹ̀ tí o fi ń pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kan àfi Ọlọrun nìkan ṣoṣo. Ṣé o mọ òfin wọnyi: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè; ìwọ kò gbọdọ̀ paniyan; ìwọ kò gbọdọ̀ jalè; ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké; bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ.’ ” Ìjòyè náà dáhùn pé, “Gbogbo òfin wọnyi ni mo ti ń pamọ́ láti ìgbà tí mo ti wà ní ọdọmọkunrin.” Nígbà tí Jesu gbọ́, ó sọ fún un pé, “Nǹkankan ló kù ọ́ kù. Lọ ta gbogbo ohun tí o ní, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn talaka, ìwọ yóo wá ní ìṣúra ní ọ̀run. Kí o máa wá tọ̀ mí lẹ́yìn.” Nígbà tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, inú rẹ̀ bàjẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ pupọ. Nígbà tí Jesu rí bí inú rẹ̀ ti bàjẹ́, ó ní, “Yóo ṣòro fún àwọn olówó láti wọ ìjọba Ọlọrun. Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá, jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun.” Àwọn tí ó gbọ́ ní, “Ta wá ni a óo gbà là?” Ó dáhùn pé, “Ohun tí kò ṣeéṣe fún eniyan, ó ṣeéṣe fún Ọlọrun.” Peteru sọ fún un pé, “Wò ó ná! Àwa ti fi ohun gbogbo tí a ní sílẹ̀, a sì ti ń tẹ̀lé ọ.” Ó bá sọ fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé kò sí ẹni tí ó fi ilé, iyawo, arakunrin, òbí tabi ọmọ sílẹ̀, nítorí ti ìjọba Ọlọrun, tí kò ní rí ìlọ́po-ìlọ́po gbà ní ayé yìí, yóo sì ní ìyè ainipẹkun ní ayé tí ń bọ̀.”

Luk 18:18-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ìjòyè kan sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, wí pé, “Olùkọ́ rere, kín ni èmi ó ṣe tí èmi ó fi jogún ìyè àìnípẹ̀kun?” Jesu wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí bí kò ṣe ẹnìkan, èyí sì ni Ọlọ́run. Ìwọ mọ̀ àwọn òfin: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà, ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe jalè, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe jẹ́rìí èké, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.’ ” Ó sì wí pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti pamọ́ láti ìgbà èwe mi wá.” Nígbà tí Jesu sì gbọ́ èyí, ó wí fún un pé, “Ohun kan ni ó kù fún ọ síbẹ̀: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o sì pín in fún àwọn tálákà, ìwọ ó sì ní ìṣúra ní ọ̀run: sì wá, kí o máa tọ̀ mí lẹ́yìn.” Nígbà tí ó sì gbọ́ èyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi: nítorí tí ó ní ọrọ̀ púpọ̀. Nígbà tí Jesu rí i pé inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi, ó wí pé, “Yóò ti ṣòro tó fún àwọn tí ó ní ọrọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run! Nítorí ó rọrùn fún ìbákasẹ láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run lọ.” Àwọn tí ó sì gbọ́ wí pé, “Ǹjẹ́ ta ni ó ha lè là?” Ó sì wí pé, “Ohun tí ó ṣòro lọ́dọ̀ ènìyàn kò ṣòro lọ́dọ̀ Ọlọ́run.” Peteru sì wí pé, “Sá wò ó, àwa ti fi ilé wa sílẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn!” Ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kò sí ẹni tí ó fi ilé, tàbí aya, tàbí ará, tàbí òbí, tàbí ọmọ sílẹ̀, nítorí ìjọba Ọlọ́run, Tí kì yóò gba ìlọ́po púpọ̀ sí i ní ayé yìí, àti ní ayé tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.”