Luk 11:14-23
Luk 11:14-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si nlé ẹmi èṣu kan jade, ti o si yadi. O si ṣe, nigbati ẹmi èṣu na jade, odi sọrọ; ẹnu si yà ijọ enia. Ṣugbọn awọn ẹlomiran ninu wọn wipe, Nipa Beelsebubu olori awọn ẹmi èṣu li o fi nlé awọn ẹmi èṣu jade. Awọn ẹlomiran si ndan a wò, nwọn fẹ àmi lọdọ rẹ̀ lati ọrun wá. Ṣugbọn on mọ̀ ìro inu wọn, o wi fun wọn pe, Gbogbo ijọba ti o yà ara rẹ̀ ni ipa, a sọ ọ di ahoro; ile ti o si yà ara rẹ̀ ni ipa, a wó. Bi Satani si yàpa si ara rẹ̀, ijọba rẹ̀ yio ha ṣe duro? nitori ẹnyin wipe, Nipa Beelsebubu li emi fi nle awọn ẹmi èṣu jade. Bi o ba si ṣepe nipa Beelsebubu li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, nipa tali awọn ọmọ nyin fi nlé wọn jade? nitorina awọn ni yio ṣe onidajọ nyin. Ṣugbọn bi o ba ṣepe ika Ọlọrun li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, kò si aniani, ijọba Ọlọrun de ba nyin. Nigbati ọkunrin alagbara ti o hamọra ba nṣọ afin rẹ̀, ẹrù rẹ̀ a wà li alãfia: Ṣugbọn nigbati ẹniti o li agbara jù u ba kọlù u, ti o si ṣẹgun rẹ̀, a gbà gbogbo ihamọra rẹ̀ ti o gbẹkẹle lọwọ rẹ̀, a si pín ikogun rẹ̀. Ẹniti kò ba wà pẹlu mi, o lodi si mi: ẹniti kò ba si bá mi kopọ̀, o nfunká.
Luk 11:14-23 Yoruba Bible (YCE)
Ní ìgbà kan, Jesu ń lé ẹ̀mí èṣù kan tí ó yadi jáde. Nígbà tí ẹ̀mí Èṣù náà ti jáde tán ọkunrin odi náà sọ̀rọ̀, ẹnu wá ya àwọn eniyan. Ṣugbọn àwọn kan ninu wọn ń sọ pé, “Agbára Beelisebulu, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù, ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.” Àwọn ẹlòmíràn ń dẹ ẹ́, wọ́n ń bèèrè àmì ọ̀run láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ṣugbọn Jesu mọ èrò wọn, ó sọ fún wọn pé, “Gbogbo ìjọba tí ó bá gbé ogun ti ara rẹ̀ yóo parun, ilé tí ó bá dìde sí ara rẹ̀ yóo tú ká. Bí Satani bá gbé ogun ti ara rẹ̀, báwo ni ìjọba rẹ̀ ṣe lè dúró? Nítorí ẹ̀ ń sọ pé agbára Beelisebulu ni mo fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Bí ó bá jẹ́ agbára Beelisebulu ni èmi fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, agbára wo ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde? Ní ti èrò yín yìí, àwọn ọmọ yín ni yóo ṣe onídàájọ́ yín. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ ọwọ́ Ọlọrun ni mo fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọrun ti dé ba yín. “Nígbà tí ọkunrin alágbára bá wà ní ihamọra, tí ó ń ṣọ́ ilé rẹ̀, kò sí ohun tí ó lè ṣe dúkìá rẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí ẹni tí ó lágbára jù ú lọ bá dé, tí ó ṣẹgun rẹ̀, a gba ohun ìjà tí ó gbẹ́kẹ̀lé, a sì pín dúkìá rẹ̀ tí ó jí kó. “Ẹni tí kò bá sí lẹ́yìn mi, olúwarẹ̀ lòdì sí mi ni, ẹni tí kò bá ti bá mi kó nǹkan jọ, a jẹ́ pé títú ni ó ń tú wọn ká.
Luk 11:14-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì ń lé ẹ̀mí èṣù kan jáde, tí ó sì yadi. Nígbà tí ẹ̀mí èṣù náà jáde, odi sọ̀rọ̀; ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn wí pé, “Nípa Beelsebulu olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.” Àwọn ẹlòmíràn sì ń dán an wò, wọ́n ń fẹ́ ààmì lọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọ̀run wá. Ṣùgbọ́n òun mọ èrò inú wọn, ó wí fún wọn pé, “Gbogbo ìjọba tí ó ya ara rẹ̀ ní ipá, ni a ń sọ di ahoro; ilé tí ó sì ya ara rẹ̀ nípá yóò wó. Bí Satani ba yapa sí ara rẹ̀, ìjọba rẹ̀ yóò ha ṣe dúró? Nítorí ẹ̀yin wí pé, nípa Beelsebulu ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Bí ó ba ṣe pé nípa Beelsebulu ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, nípa ta ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde, nítorí náà àwọn ni yóò ṣe onídàájọ́ yín. Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe pé nípa ìka ọwọ́ Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ǹjẹ́ ìjọba Ọlọ́run dé bá yín tán. “Nígbà tí alágbára ọkùnrin tí ó ni ìhámọ́ra bá ń ṣọ́ ààfin rẹ̀, ẹrù rẹ̀ yóò wà ní àlàáfíà. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹni tí ó ní agbára jù ú bá kọlù ú, tí ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ a gba gbogbo ìhámọ́ra rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé lọ́wọ́ rẹ̀, a sì pín ìkógun rẹ̀. “Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, ó lòdì sí mi: ẹni tí kò bá sì bá mi kójọpọ̀, ó fọ́nká.