Luk 10:17-21
Luk 10:17-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn adọrin na si fi ayọ̀ pada, wipe, Oluwa, awọn ẹmi èṣu tilẹ foribalẹ fun wa li orukọ rẹ. O si wi fun wọn pe, Emi ri Satani ṣubu bi manamana lati ọrun wá. Kiyesi i, emi fun nyin li aṣẹ lati tẹ̀ ejò ati akẽkẽ mọlẹ, ati lori gbogbo agbara ọtá: kò si si ohunkan bi o ti wù ki o ṣe, ti yio pa-nyin-lara. Ṣugbọn ki ẹ máṣe yọ̀ si eyi, pe, awọn ẹmi nforibalẹ fun nyin; ṣugbọn ẹ kuku yọ̀, pe, a kọwe orukọ nyin li ọrun. Ni wakati kanna Jesu yọ̀ ninu Ẹmi Mimọ́ o si wipe, Mo dupẹ lọwọ rẹ, Baba, Oluwa ọrun on aiye, pe, iwọ pa nkan wọnyi mọ́ kuro lọdọ awọn ọlọ́gbọn ati amoye, iwọ si fi wọn hàn fun awọn ọmọ-ọwọ: bẹ̃ni, Baba, bẹ̃li o sá yẹ li oju rẹ.
Luk 10:17-21 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejilelaadọrin pada dé pẹlu ayọ̀. Wọ́n ní, “Oluwa, àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbọ́ràn sí wa lẹ́nu ní orúkọ rẹ.” Ó bá sọ fún wọn pé, “Mo rí Satani tí ó ti ọ̀run já bọ́ bí ìràwọ̀. Mo fun yín ní àṣẹ láti tẹ ejò ati àkeekèé mọ́lẹ̀. Mo tún fun yín ní àṣẹ lórí gbogbo agbára ọ̀tá. Kò sí ohunkohun tí yóo pa yín lára. Ẹ má yọ̀ ní ti pé àwọn ẹ̀mí èṣù gbọ́ràn si yín lẹ́nu; ṣugbọn ẹ máa yọ̀ nítorí a ti kọ orúkọ yín sí ọ̀run.” Ní àkókò náà Jesu láyọ̀ ninu Ẹ̀mí Mímọ́. Ó ní, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Oluwa ọ̀run ati ayé, nítorí o ti pa nǹkan wọnyi mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n ati àwọn olóye; ṣugbọn o fi wọ́n han àwọn òpè. Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí bí ó ti tọ́ ní ojú rẹ ni.
Luk 10:17-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn àádọ́rin náà sì fi ayọ̀ padà, wí pé, “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù tilẹ̀ foríbalẹ̀ fún wa ní orúkọ rẹ.” Ó sì wí fún wọn pé, “Èmí rí Satani ṣubú bí mọ̀nàmọ́ná láti ọ̀run wá. Kíyèsi i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèe mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá: kò sì ṣí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára. Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe yọ̀ nítorí èyí pé, àwọn ẹ̀mí ń foríbalẹ̀ fún yín; ṣùgbọ́n ẹ kúkú yọ̀, pé; a kọ̀wé orúkọ yín ní ọ̀run!” Ní wákàtí kan náà Jesu yọ̀ nínú Ẹ̀mí mímọ́ ó sì wí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ pa nǹkan wọ̀nyí mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, ìwọ sì fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ ọwọ́: bẹ́ẹ̀ ni, Baba, bẹ́ẹ̀ ni ó sá à yẹ ní ojú rẹ.