Luk 1:67-80

Luk 1:67-80 Yoruba Bible (YCE)

Sakaraya, baba ọmọ náà, kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ó bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé, Kí á yin Oluwa Ọlọrun Israẹli nítorí ó ti mú ìrànlọ́wọ́ wá fún àwọn eniyan rẹ̀, ó sì ti dá wọn nídè. Ó ti gbé Olùgbàlà dìde fún wa ní ìdílé Dafidi, iranṣẹ rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀ mímọ́, láti ọjọ́ pípẹ́; pé yóo gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa ati lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí ó kórìíra wa; pé yóo fi àánú bá àwọn baba wa lò, ati pé yóo ranti majẹmu rẹ̀ mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún Abrahamu baba wa, pé yóo gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, ati pé yóo fún wa ní anfaani láti máa sìn ín láì fòyà, pẹlu ọkàn kan ati pẹlu òdodo níwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. “Ìwọ, ọmọ mi, wolii Ọ̀gá Ògo ni a óo máa pè ọ́, nítorí ìwọ ni yóo ṣáájú Oluwa láti palẹ̀ mọ́ dè é, láti fi ìmọ̀ ìgbàlà fún àwọn eniyan rẹ̀, nípa ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí àánú Ọlọrun wa, nípa èyí tí oòrùn ìgbàlà fi ràn lé wa lórí láti òkè wá, láti tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn tí ó wà ní òkùnkùn ati àwọn tí ó jókòó níbi òjìji ikú, láti fi ẹsẹ̀ wa lé ọ̀nà alaafia.” Ọmọ náà ń dàgbà, ó sì ń lágbára sí i lára ati lẹ́mìí. Ilẹ̀ aṣálẹ̀ ni ó ń gbé títí di àkókò tí ó fara han àwọn eniyan Israẹli.

Luk 1:67-80 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Sekariah baba rẹ̀ sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì sọtẹ́lẹ̀, ó ní: “Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli; nítorí tí ó ti bojú wò, tí ó sì ti dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè, Ó sì ti gbé ìwo ìgbàlà sókè fún wa ní ilé Dafidi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀; (bí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tipẹ́tipẹ́), Pé, a ó gbà wá là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa àti lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wá. Láti ṣe àánú tí ó ṣèlérí fún àwọn baba wa, àti láti rántí májẹ̀mú rẹ̀ mímọ́, ìbúra tí ó ti bú fún Abrahamu baba wa, láti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, kí àwa kí ó lè máa sìn láìfòyà, ni ìwà mímọ́ àti ní òdodo níwájú rẹ̀, ní ọjọ́ ayé wa gbogbo. “Àti ìwọ, ọmọ mi, wòlíì Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó máa pè ọ́: nítorí ìwọ ni yóò ṣáájú Olúwa láti tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe; láti fi ìmọ̀ ìgbàlà fún àwọn ènìyàn rẹ̀ fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí ìyọ́nú Ọlọ́run wà; nípa èyí tí ìlà-oòrùn láti òkè wá bojú wò wá, Láti fi ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó jókòó ní òkùnkùn àti ní òjìji ikú, àti láti fi ẹsẹ̀ wa lé ọ̀nà àlàáfíà.” Ọmọ náà sì dàgbà, ó sì le ní ọkàn, ó sì ń gbé ní ijù títí ó fi di ọjọ́ ìfihàn rẹ̀ fún Israẹli.