Lef 7:11-15
Lef 7:11-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Eyi si ni ofin ẹbọ alafia, ti on o ru si OLUWA. Bi o ba mú u wá fun idupẹ́, njẹ ki o mú adidùn àkara alaiwu wá ti a fi oróro pò, pẹlu ẹbọ ọpẹ́ rẹ̀, ati àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si, ati adidùn àkara iyẹfun didara, ti a fi oróro pò, ti a din. Pẹlu adidùn àkara wiwu ki o mú ọrẹ-ẹbọ pẹlu ẹbọ alafia rẹ̀ wa fun idupẹ́. Ati ninu rẹ̀ ni ki o mú ọkan kuro ninu gbogbo ọrẹ-ẹbọ na fun ẹbọ agbesọsoke si OLUWA; ki o si jẹ́ ti alufa ti o nwọ́n ẹ̀jẹ ẹbọ alafia. Ati ẹran ẹbọ alafia rẹ̀ fun idupẹ́, ki a jẹ ẹ li ọjọ́ na ti a fi rubọ; ki o máṣe kù ninu rẹ̀ silẹ titi di owurọ̀.
Lef 7:11-15 Yoruba Bible (YCE)
“Èyí ni òfin ẹbọ alaafia, tí eniyan lè rú sí OLUWA. Tí ó bá rú u fún ìdúpẹ́, yóo rú u pẹlu àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, tí a fi òróró pò, ati àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà, tí a da òróró lé lórí, pẹlu àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun kíkúnná ṣe, tí a fi òróró pò dáradára. Ẹni tí ó bá rú ẹbọ alaafia fún ìdúpẹ́ yóo mú ẹbọ rẹ̀ wá pẹlu àkàrà tí ó ní ìwúkàrà. Kí ó yọ àkàrà kọ̀ọ̀kan kúrò lára ẹbọ kọ̀ọ̀kan, kí ó fi rúbọ sí OLUWA; yóo jẹ́ ti alufaa tí ó wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran ẹbọ alaafia náà sára pẹpẹ. Wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ ẹran ẹbọ alaafia tí ó fi ṣe ẹbọ ọpẹ́ tán ní ọjọ́ tí ó bá rú ẹbọ náà, kò gbọdọ̀ ṣẹ́kù di ọjọ́ keji.
Lef 7:11-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
“ ‘Wọ̀nyí ni àwọn ìlànà fún ọrẹ àlàáfíà tí ẹnikẹ́ni bá gbé wá síwájú OLúWA. “ ‘Bí ẹni náà bá gbé e wá gẹ́gẹ́ bí àfihàn ọkàn ọpẹ́, pẹ̀lú ẹbọ ọpẹ́ yìí, ó gbọdọ̀ mú àkàrà aláìwú tí a fi òróró pò wá àti àkàrà aláìwú fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a dà òróró sí àti àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò ṣe. Pẹ̀lú ọrẹ àlàáfíà rẹ̀, kí ó tún mú àkàrà wíwú wá fún ọpẹ́, kí ó mú ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú oríṣìíríṣìí ọrẹ àlàáfíà rẹ wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún OLúWA, ó jẹ́ tí àlùfáà tí ó wọ́n ẹ̀jẹ̀ ọrẹ àlàáfíà. Ẹran ọrẹ àlàáfíà ti ọpẹ́ yìí ni wọ́n gbọdọ̀ jẹ ní ọjọ́ gan an tí wọ́n rú ẹbọ, kò gbọdọ̀ ṣẹ́ ẹran kankan kù di àárọ̀ ọjọ́ kejì.