Lef 6:2-5
Lef 6:2-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi ẹnikan ba ṣẹ̀, ti o dẹ̀ṣẹ si OLUWA, ti o si sẹ́ fun ẹnikeji rẹ̀, li ohun ti o fi fun u pamọ́, tabi li ohun ti a fi dógo, tabi ohun ti a fi agbara gbà, tabi ti o rẹ ẹnikeji rẹ̀ jẹ; Tabi ti o ri ohun ti o nù he, ti o si ṣeké nitori rẹ̀, ti o si bura eké; li ọkan ninu gbogbo ohun ti enia ṣe, ti o ṣẹ̀ ninu rẹ̀: Yio si ṣe, bi o ba ti ṣẹ̀, ti o si jẹbi, ki o si mú ohun ti o fi agbara gbà pada, tabi ohun ti o fi irẹjẹ ní, tabi ohun ti a fi fun u pamọ́, tabi ohun ti o nù ti o rihe. Tabi gbogbo eyi na nipa eyiti o bura eké; ki o tilẹ mú u pada li oju-owo rẹ̀, ki o si fi idamarun rẹ̀ lé ori rẹ̀, ki o si fi i fun olohun, li ọjọ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
Lef 6:2-5 Yoruba Bible (YCE)
“Bí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA nípa ṣíṣe èyíkéyìí ninu nǹkan wọnyi: kì báà jẹ́ pé ó kọ̀ láti dá ohun tí aládùúgbò rẹ̀ fi dógò pada ni, tabi pé ó ja aládùúgbò rẹ̀ lólè ni, tabi pé ó rẹ́ ẹ jẹ ni, tabi pé ó rí nǹkan rẹ̀ tí ó sọnù he, tí ó sì ṣe bí ẹni pé òun kò rí i, tabi tí ó búra èké nípa ohunkohun, ẹ̀ṣẹ̀ ni ó dá. Bí ẹnikẹ́ni bá dá irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí, kí ó dá ohun tí ó jí pada, tabi ohun tí ó fi ìrẹ́jẹ gbà, tabi ohun tí wọ́n fi dógò lọ́dọ̀ rẹ̀, tabi ohun tí ó sọnù tí ó rí he, tabi ohunkohun tí ó ti búra èké sí. Kí ó san án pé pérépéré kí ó sì fi ìdámárùn-ún lé e, nígbà tí ó bá dá ohun náà pada fún olúwarẹ̀, ní ọjọ́ tí yóo bá rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi.
Lef 6:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Bí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe àìṣòótọ́ sí OLúWA nípa títan ẹnìkejì rẹ̀ lórí ohun tí wọ́n fi sí ìkáwọ́ tàbí tí wọ́n fi pamọ́ sí i lọ́wọ́, tàbí bí ó bá jalè, tàbí kí ó yan ẹnìkejì rẹ̀ jẹ, tàbí kí ó rí ohun tó sọnù he tó sì parọ́ tàbí kí ó búra èké, tàbí kí ó tilẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ kan, irú èyí tí ènìyàn lè ṣẹ̀. Bí ó bá dẹ́ṣẹ̀ báyìí tó sì jẹ̀bi, ó gbọdọ̀ dá ohun tó jí tàbí ohun tó fi agbára gbà, tàbí ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ̀, tàbí ohun tó sọnù tó rí he, tàbí ohunkóhun tó búra èké lé lórí. Ó gbọdọ̀ dá gbogbo rẹ̀ padà ní pípé, kí ó fi ìdámárùn-ún iye rẹ̀ kún, kí ó sì dá gbogbo rẹ̀ padà fún ẹni tí ó ni í, ní ọjọ́ tó bá ń rú ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀.