Lef 4:13-31

Lef 4:13-31 Bibeli Mimọ (YBCV)

Bi gbogbo ijọ enia Israeli ba si fi aimọ̀ ṣẹ̀, ti ohun na si pamọ́ li oju ijọ, ti nwọn si ṣì ohun kan ṣe si ọkan ninu ofin OLUWA, ti a ki ba ṣe, ti nwọn si jẹbi; Nigbati ẹ̀ṣẹ ti nwọn ba ti ṣẹ̀ si i, ba di mimọ̀, nigbana ni ki ijọ enia ki o mú ẹgbọrọ akọmalu kan wá nitori ẹ̀ṣẹ na, ki nwọn ki o si mú u wá siwaju agọ́ ajọ. Ki awọn àgbagba ijọ enia ki o fi ọwọ́ wọn lé ori akọmalu na niwaju OLUWA: ki a si pa akọmalu na niwaju OLUWA. Ki alufa ti a fi oróro yàn ki o si mú ninu ẹ̀jẹ akọmalu na wá si agọ́ ajọ: Ki alufa na ki o si tẹ̀ iká rẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ na, ki o si wọ́n ọ nigba meje niwaju OLUWA, niwaju aṣọ-ikele. Ki o si fi diẹ ninu ẹ̀jẹ na sara iwo pẹpẹ ti mbẹ niwaju OLUWA, ti mbẹ ninu agọ́ ajọ, ki o si dà gbogbo ẹ̀jẹ na si isalẹ pẹpẹ ẹbọsisun, ti mbẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. Ki o si mú gbogbo ọrá rẹ̀ lara rẹ̀, ki o si sun u lori pẹpẹ. Ki o si fi akọmalu na ṣe; bi o ti fi akọmalu ẹbọ ẹ̀ṣẹ ṣe, bẹ̃ni ki o si fi eyi ṣe: ki alufa na ki o si ṣètutu fun wọn, a o si dari rẹ̀ jì wọn. Ki o si gbé akọmalu na jade lọ sẹhin ibudó, ki o si sun u bi o ti sun akọmalu iṣaju: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni fun ijọ enia. Nigbati ijoye kan ba ṣẹ̀, ti o si fi aimọ̀ rú ọkan ninu ofin OLUWA Ọlọrun rẹ̀, ti a ki ba rú, ti o si jẹbi; Tabi bi ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ninu eyiti o ti ṣẹ̀, ba di mímọ̀ fun u; ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá, ọmọ ewurẹ kan, akọ alailabùku: Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ewurẹ na, ki o si pa a ni ibiti nwọn gbé npa ẹbọ sisun niwaju OLUWA: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni. Ki alufa na ki o si fi iká rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ na, ki o si fi i sara iwo pẹpẹ ẹbọsisun, ki o si dà ẹ̀jẹ si isalẹ pẹpẹ ẹbọsisun. Ki o si sun gbogbo ọrá rẹ̀ li ori pẹpẹ, bi ti ọrá ẹbọ alafia: ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀, a o si dari rẹ̀ jì i. Bi ọkan ninu awọn enia ilẹ na ba fi aimọ̀ sẹ̀, nigbati o ba ṣì ohun kan ṣe si ọkan ninu ofin OLUWA ti a ki ba ṣe, ti o si jẹbi; Tabi bi ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ti o ti ṣẹ̀, ba di mimọ̀ fun u, nigbana ni ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá, ọmọ ewurẹ kan, abo alailabùku, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀. Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ẹbọ ẹ̀ṣẹ na, ki o si pa ẹbọ ẹ̀ṣẹ na ni ibi ẹbọsisun. Ki alufa ki o si fi iká rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ na, ki o si fi i sara iwo pẹpẹ ẹbọsisun, ki o si dà gbogbo ẹ̀jẹ rẹ̀ si isalẹ pẹpẹ. Ki o si mú gbogbo ọrá rẹ̀ kuro, bi a ti imú ọrá kuro ninu ẹbọ ọrẹ-ẹbọ alafia; ki alufa ki o si sun u lori pẹpẹ fun õrùn didùn si OLUWA; ki alufa na ki o si ṣètutu fun u, a o si dari rẹ̀ jì i.

Lef 4:13-31 Yoruba Bible (YCE)

“Tí ó bá jẹ́ pé gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ni ó ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn tí ẹ̀ṣẹ̀ náà kò hàn sí ìjọ eniyan, tí wọ́n bá ṣe ọ̀kan ninu àwọn ohun gbogbo tí OLUWA ti pa láṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ ṣe, tí wọ́n sì jẹ̀bi, nígbà tí wọ́n bá mọ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá, tí wọ́n sì rí àṣìṣe wọn, gbogbo ìjọ eniyan náà yóo fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, wọn yóo fà á wá síbi Àgọ́ Àjọ. Àwọn àgbààgbà ninu àwọn eniyan náà yóo gbé ọwọ́ wọn lé orí akọ mààlúù yìí níwájú OLUWA, wọn óo sì pa á níbẹ̀. Lẹ́yìn náà ni alufaa tí a fi òróró yàn yóo mú ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù yìí wá sinu Àgọ́ Àjọ. Yóo sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, yóo wọ́n ọn sílẹ̀ nígbà meje níwájú OLUWA, níwájú aṣọ ìbòjú tí ó wà níbi mímọ́. Yóo mú ninu ẹ̀jẹ̀ tí ó kù, yóo fi sára àwọn ìwo pẹpẹ tí ó wà níwájú OLUWA ninu Àgọ́ Àjọ, yóo sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sílẹ̀ ní ìdí pẹpẹ ẹbọ sísun tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Yóo yọ gbogbo ọ̀rá rẹ̀ yóo sì sun ún lórí pẹpẹ. Bí ó ti ṣe akọ mààlúù tí wọ́n fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni yóo ṣe akọ mààlúù yìí pẹlu. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún wọn, OLUWA yóo sì dáríjì wọ́n. Lẹ́yìn náà, alufaa yóo gbé mààlúù yìí jáde kúrò ninu àgọ́, yóo sì sun ún bí ó ti sun mààlúù ti àkọ́kọ́; ó jẹ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo ìjọ eniyan náà. “Bí ìjòyè kan bá dẹ́ṣẹ̀, tí ó ṣèèṣì ṣe ọ̀kankan ninu àwọn ohun tí OLUWA Ọlọrun rẹ̀ pa láṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe, tí ó sì jẹ̀bi, nígbà tí wọ́n bá fi ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá yìí hàn án, yóo mú òbúkọ kan tí kò ní àbààwọ́n wá, yóo fi rúbọ. Yóo gbé ọwọ́ lé orí òbúkọ yìí, yóo sì pa á níbi tí wọ́n ti máa ń pa ẹran ẹbọ sísun níwájú OLUWA; ó jẹ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Alufaa yóo ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹran tí wọ́n fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóo fi sí ara àwọn ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun; yóo sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sílẹ̀ nídìí pẹpẹ. Yóo sun gbogbo ọ̀rá òbúkọ náà lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rá ẹran tí wọ́n bá fi rú ẹbọ alaafia. Bẹ́ẹ̀ ni alufaa yóo ṣe ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, OLUWA yóo sì dáríjì í. “Bí ẹnìkan lásán ninu àwọn eniyan náà bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, tí ó ṣe ọ̀kan ninu àwọn ohun tí OLUWA ti pa láṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe, tí ó sì jẹ̀bi, lẹ́yìn tí wọ́n bá fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó dá hàn án, yóo mú abo ewúrẹ́ tí kò ní àbààwọ́n wá, yóo fi rúbọ fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá. Yóo gbé ọwọ́ lé orí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ yìí, yóo sì pa á, níbi tí wọ́n ti ń rú ẹbọ sísun. Alufaa yóo sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi sí ara ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, yóo sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ìdí pẹpẹ. Yóo yọ gbogbo ọ̀rá ewúrẹ́ náà, bí wọ́n ti ń yọ ọ̀rá ẹran tí wọ́n bá fi rú ẹbọ alaafia, alufaa yóo sì sun ún níná lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún un, OLUWA yóo sì dáríjì í.

Lef 4:13-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

“ ‘Bí gbogbo àpapọ̀ ènìyàn Israẹli bá ṣèèṣì ṣẹ̀, tí wọ́n sì ṣe ohun tí kò yẹ kí wọ́n ṣe sí ọ̀kan nínú àwọn òfin OLúWA, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àpapọ̀ ènìyàn náà kò mọ̀ sí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n jẹ̀bi. Nígbà tí wọ́n bá mọ̀, gbogbo ìjọ ènìyàn yóò mú akọ màlúù wá sí àgọ́ ìpàdé gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Kí àwọn àgbàgbà ìjọ Israẹli gbé ọwọ́ lórí akọ ọmọ màlúù náà níwájú OLúWA. Kí àlùfáà tí a fi òróró yàn sì mú díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ akọ ọmọ màlúù náà wá sínú àgọ́ ìpàdé. Kí ó ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà kí ó sì wọn ní ẹ̀ẹ̀méje níwájú OLúWA níbi aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà. Kí ó sì mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ náà sórí ìwo pẹpẹ tó wà níwájú OLúWA nínú àgọ́ ìpàdé. Ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà ni kí ó dà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ ẹbọ sísun ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. Kí ó yọ gbogbo ọ̀rá kúrò lára rẹ̀, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ. Kí ó sì ṣe akọ ọmọ màlúù yìí gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣe akọ màlúù tó wà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ṣe ètùtù fún wọn, á ó sì dáríjì wọ́n. Lẹ́yìn náà ni yóò sun màlúù yìí lẹ́yìn ibùdó, yóò sì sun ún gẹ́gẹ́ bó ṣe sun màlúù àkọ́kọ́. Èyí ni ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli. “ ‘Bí olórí kan bá ṣèèṣì ṣẹ̀ láìmọ̀ tí ó sì ṣe ohun tí kò yẹ kí ó ṣe sí ọ̀kan nínú àwọn òfin OLúWA Ọlọ́run rẹ̀, ó jẹ̀bi. Nígbà tí a bá sì sọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún un, ó gbọdọ̀ mú akọ ewúrẹ́ tí kò ní àbùkù wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ rẹ̀. Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lórí ewúrẹ́ náà, kí ó sì pa á níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ sísun níwájú OLúWA. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. Lẹ́yìn èyí, kí àlùfáà ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, kí ó fi sí orí ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, kí ó sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. Kí ó sun gbogbo ọ̀rá rẹ̀ lórí pẹpẹ bí ó ṣe sun ọ̀rá ọrẹ àlàáfíà. Báyìí ní àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin náà, a ó sì dáríjì í. “ ‘Bí ènìyàn nínú àwọn ará ìlú bá ṣèèṣì ṣẹ̀ láìmọ̀ tí ó sì ṣe ohun tí kò yẹ sí ọ̀kan nínú àwọn òfin OLúWA, ó jẹ̀bi. Nígbà tí a bá sọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún un, ó gbọdọ̀ mú abo ewúrẹ́ tí kò ní àbùkù wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lórí ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, kí ó sì pa á níbi ẹbọ sísun. Àlùfáà yóò sì ti ìka rẹ̀ bọ́ ẹ̀jẹ̀ náà, yóò fi sí orí ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, kí ó sì da ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. Kí ó yọ gbogbo ọ̀rá ẹran náà gẹ́gẹ́ bó ṣe yọ ọ̀rá ẹran fún ọrẹ àlàáfíà. Kí àlùfáà sì sun ọ̀rá yìí lórí pẹpẹ bí òórùn dídùn sí OLúWA. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà, a ó sì dáríjì í.