Lef 22:1-16
Lef 22:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, ki nwọn ki o yà ara wọn sọ̀tọ kuro ninu ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o má si ṣe bà orukọ mimọ́ mi jẹ́ ninu ohun wọnni, ti nwọn yàsimimọ́ fun mi: Emi li OLUWA, Wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ninu gbogbo irú-ọmọ nyin ninu awọn iran nyin, ti o ba sunmọ ohun mimọ́, ti awọn ọmọ Israeli yàsimimọ́ fun OLUWA, ti o ní aimọ́ rẹ̀ lara rẹ̀, ọkàn na li a o ke kuro niwaju mi: Emi li OLUWA. Ẹnikẹni ninu irú-ọmọ Aaroni ti iṣe adẹtẹ, tabi ti o ní isun; ki o máṣe jẹ ninu ohun mimọ́, titi on o fi di mimọ́. Ati ẹnikẹni ti o farakàn ohun ti iṣe aimọ́, bi okú, tabi ọkunrin ti ohun-irú nti ara rẹ̀ jade; Tabi ẹniti o ba farakàn ohun ti nrakò kan, ti yio sọ ọ di aimọ́, tabi enia kan ti yio sọ ọ di aimọ́, irú aimọ́ ti o wù ki o ní; Ọkàn ti o ba farakàn ọkan ninu irú ohun bẹ̃ ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ, ki o má si ṣe jẹ ninu ohun mimọ́, bikoṣepe o ba fi omi wẹ̀ ara rẹ̀. Nigbati õrùn ba si wọ̀, on o di mimọ́; lẹhin eyinì ki o si ma jẹ ninu ohun mimọ́, nitoripe onjẹ rẹ̀ ni. On kò gbọdọ jẹ ẹran ti o kú fun ara rẹ̀, tabi eyiti ẹranko fàya, lati fi i bà ara rẹ̀ jẹ́: Emi li OLUWA. Nitorina ki nwọn ki o ma pa ìlana mi mọ́, ki nwọn ki o máṣe rù ẹ̀ṣẹ nitori rẹ̀, nwọn a si kú nitorina, bi nwọn ba bà a jẹ́: Emi li OLUWA ti o yà wọn simimọ́. Alejò kan kò gbọdọ jẹ ninu ohun mimọ́: alabagbé alufa, tabi alagbaṣe kò gbọdọ jẹ ninu ohun mimọ́ na. Ṣugbọn bi alufa ba fi owo rẹ̀ rà ẹnikan, ki o jẹ ninu rẹ̀; ẹniti a si bi ninu ile rẹ̀, ki nwọn ki o ma jẹ ninu onjẹ rẹ̀. Bi ọmọbinrin alufa na ba si ní alejò kan li ọkọ, obinrin na kò le jẹ ninu ẹbọ fifì ohun mimọ́. Ṣugbọn bi ọmọbinrin alufa na ba di opó, tabi ẹni-ikọsilẹ, ti kò si lí ọmọ, ti o si pada wá si ile baba rẹ̀, bi ìgba ewe rẹ̀, ki o ma jẹ ninu onjẹ baba rẹ̀: ṣugbọn alejò kan kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀. Bi ẹnikan ba si jẹ ninu ohun mimọ́ li aimọ̀, njẹ ki o fi idamarun rẹ̀ lé e, ki o si fi i fun alufa pẹlu ohun mimọ́ na. Nwọn kò si gbọdọ bà ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli jẹ́, ti nwọn mú fun OLUWA wá: Tabi lati jẹ ki nwọn ki o rù aiṣedede ti o mú ẹbi wá, nigbati nwọn ba njẹ ohun mimọ́ wọn: nitoripe Emi li OLUWA ti o yà wọn simimọ́.
Lef 22:1-16 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA rán Mose pé, “Sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀ pé, kí wọ́n máa fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ lo àwọn nǹkan mímọ́ tí àwọn eniyan Israẹli yà sọ́tọ̀ fún mi, kí wọ́n má baà ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Èmi ni OLUWA. Bí èyíkéyìí ninu arọmọdọmọ wọn bá súnmọ́ àwọn nǹkan mímọ́ wọ̀n-ọn-nì, tí àwọn eniyan Israẹli ti yà sí mímọ́ fún OLUWA; nígbà tí ó wà ní ipò àìmọ́, a óo mú ẹni náà kúrò lọ́dọ̀ mi. Èmi ni OLUWA. “Ẹnikẹ́ni ninu ìran Aaroni tí ó bá ní àrùn ẹ̀tẹ̀, tabi tí ara rẹ̀ bá ń tú, kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà, títí tí yóo fi di mímọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́, kì báà jẹ́ pé ó fara kan òkú ni, tabi pé ó fara kan ẹni tí nǹkan ọkunrin jáde lára rẹ̀, tabi ẹni tí ó bá fara kan èyíkéyìí ninu àwọn ẹ̀dá alààyè tí ń káàkiri, èyí tí ó lè sọ eniyan di aláìmọ́, tabi ẹnikẹ́ni tí ó lè kó àìmọ́ bá eniyan, ohun yòówù tí àìmọ́ rẹ̀ lè jẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan irú nǹkan bẹ́ẹ̀, tabi irú ẹni bẹ́ẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́; kò sì ní jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà títí tí yóo fi wẹ̀. Nígbà tí oòrùn bá wọ̀, yóo di mímọ́, lẹ́yìn náà, ó lè jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà nítorí oúnjẹ rẹ̀ ni wọ́n jẹ́. Alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá kú fúnrara rẹ̀, tabi tí ẹranko burúkú bá pa; kí ó má baà fi òkú ẹran yìí sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́. Èmi ni OLUWA. “Àwọn alufaa gbọdọ̀ pa àwọn òfin mi mọ́, kí wọ́n má baà dẹ́ṣẹ̀ nítorí rẹ̀, kí wọ́n sì kú nítorí àwọn òfin mi tí wọ́n bá rú. Èmi ni OLUWA tí mo sọ wọ́n di mímọ́. “Àjèjì kankan kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ohun mímọ́, bẹ́ẹ̀ ni àlejò tabi alágbàṣe tí ń gbé ilé alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ninu wọn. Ṣugbọn bí alufaa bá fi owó ra ẹrú fún ara rẹ̀, ẹrú náà lè jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà. Àwọn ọmọ tí ẹrú náà bá sì bí ninu ilé alufaa náà lè jẹ ninu oúnjẹ náà pẹlu. Bí ọmọbinrin alufaa kan bá fẹ́ àjèjì, kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ tí wọ́n bá fi rúbọ. Ṣugbọn bí ọmọbinrin alufaa kan bá jẹ́ opó, tabi tí ó ti kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ láì bímọ fún un, tí ó bá pada sí ilé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ó wà ní ọdọmọbinrin, ó lè jẹ ninu oúnjẹ baba rẹ̀; sibẹsibẹ àjèjì kankan kò gbọdọ̀ jẹ ninu rẹ̀. “Bí ẹnìkan bá jẹ ohun mímọ́ kan ní ìjẹkújẹ yóo san án pada fún alufaa pẹlu ìdámárùn-ún rẹ̀. Àwọn alufaa kò gbọdọ̀ sọ àwọn ohun mímọ́ àwọn eniyan Israẹli tí wọ́n fi ń rúbọ sí OLUWA di aláìmọ́. Kí wọ́n má baà mú àwọn eniyan náà dẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n sì kó ẹ̀bi rù wọ́n nípa jíjẹ àwọn ohun mímọ́ wọn; nítorí èmi ni OLUWA tí mo sọ wọ́n di mímọ́.”
Lef 22:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ kí wọ́n fi ọ̀wọ̀ fún ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli yà sọ́tọ̀ fún mi, kí wọ́n má ba à ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Èmi ni OLúWA. “Sọ fún wọn pé: ‘Fún àwọn ìran tí ń bọ̀. Bí ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ yín tí kò mọ́ bá wá sí ibi ọrẹ mímọ́ tí àwọn ara Israẹli ti yà sọ́tọ̀ fún OLúWA, kí ẹ yọ ẹni náà kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà ní iwájú mi. Èmi ni OLúWA. “ ‘Bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Aaroni bá ní ààrùn ara tí ń ran ni, tàbí ìtújáde nínú ara. Ó lè má jẹ ọrẹ mímọ́ náà títí di ìgbà tí a ó fi wẹ̀ ẹ́ mọ́. Òun tún lè di aláìmọ́ bí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí òkú nǹkan bá sọ di àìmọ́ tàbí bí ó bá farakan ẹnikẹ́ni tí ó ní ìtújáde. Tàbí bí ó bá fọwọ́ kan èyíkéyìí nínú ohun tí ń rákò, tí ó sọ ọ́ di aláìmọ́, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó sọ ọ́ di àìmọ́, ohunkóhun yówù kí àìmọ́ náà jẹ́. Ẹni náà tí ó fọwọ́ kan irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Kò gbọdọ̀ jẹ èyíkéyìí nínú ọrẹ mímọ́ àyàfi bí ó bá wẹ ara rẹ̀. Bí oòrùn bá wọ̀, ẹni náà di mímọ́, lẹ́yìn náà ni ó tó le jẹ ọrẹ mímọ́, torí pé wọ́n jẹ́ oúnjẹ rẹ̀. Kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ó bá ti kú sílẹ̀, tàbí tí ẹranko fàya, kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di aláìmọ́. Èmi ni OLúWA. “ ‘Kí àwọn àlùfáà pa ìlànà mi mọ́, kí wọn má ba à jẹ̀bi, kí wọn sì kú nítorí pé wọ́n ṣe ọrẹ wọ̀nyí pẹ̀lú fífojútẹ́ńbẹ́lú wọn. Èmi ni OLúWA tí ó sọ wọ́n di mímọ́. “ ‘Kò sí ẹnikẹ́ni lẹ́yìn ìdílé àlùfáà tí ó le jẹ ọrẹ mímọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni, àlejò àlùfáà tàbí alágbàṣe rẹ̀ kò le jẹ ẹ́. Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá ra ẹrú, pẹ̀lú owó, tàbí tí a bí ẹrú kan nínú ìdílé rẹ̀, ẹrú náà lè jẹ oúnjẹ rẹ̀. Bí ọmọbìnrin àlùfáà bá fẹ́ ẹni tí kì í ṣe àlùfáà, kò gbọdọ̀ jẹ nínú èyíkéyìí nínú ohun ọrẹ mímọ́. Ṣùgbọ́n bí ọmọbìnrin àlùfáà bá jẹ́ opó tàbí tí a ti kọ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò lọ́mọ tí ó sì padà sínú ilé baba rẹ̀ láti máa gbé bẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀, ó le jẹ oúnjẹ baba rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, àlejò tí kò lẹ́tọ̀ọ́ (láṣẹ) kò gbọdọ̀ jẹ èyíkéyìí nínú oúnjẹ náà. “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ṣèèṣì jẹ ọrẹ mímọ́ kan, ó gbọdọ̀ ṣe àtúnṣe lórí ẹbọ náà fún àlùfáà, kí ó sì fi ìdámárùn-ún ohun tí ọrẹ náà jẹ́ kún un. Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ sọ ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli mú wá síwájú OLúWA di àìmọ́. Nípa fífi ààyè fún wọn láti jẹ ọrẹ mímọ́ náà, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ẹ̀bi tí wọn yóò san nǹkan fún wá sórí wọn. Èmi ni OLúWA, tí ó sọ wọ́n di mímọ́.’ ”