Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Lef 2:2YBCV(Bibeli Mimọ)
Ki o si mú u tọ̀ awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni wá: ki alufa si bù ikunwọ kan ninu rẹ̀, ninu iyẹfun na, ati ninu oróro na, pẹlu gbogbo turari rẹ̀; ki o si sun ẹbọ-iranti rẹ̀ lori pẹpẹ, lati ṣe ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA
Pín
Lef 2YBCVLef 2:2BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
kí ó sì gbé lọ fún àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà. Àlùfáà yóò bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú ìyẹ̀fun àti òróró náà, pẹ̀lú gbogbo tùràrí kí ó sì sun ún gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lórí pẹpẹ, ọrẹ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí OLúWA.
Pín
Lef 2BMYOLef 2:2YCE(Yoruba Bible)
Kí ó gbé e tọ àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, lọ, kí alufaa náà bu ẹ̀kúnwọ́ kan ninu ìyẹ̀fun náà, pẹlu òróró ati turari tí ó wà lórí rẹ̀. Ẹ̀kúnwọ́ kan yìí ni alufaa yóo sun fún ìrántí, ẹbọ olóòórùn dídùn, tí a fi iná sun sí OLUWA.
Pín
Lef 2YCE