Lef 19:19-37

Lef 19:19-37 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ki ẹnyin ki o pa ìlana mi mọ́. Iwọ kò gbọdọ jẹ ki ẹranọ̀sin rẹ ki o ba onirũru dàpọ: iwọ kò gbọdọ fọ́n daru-dàpọ irugbìn si oko rẹ: bẹ̃li aṣọ ti a fi ọ̀gbọ ati kubusu hun pọ̀ kò gbọdọ kan ara rẹ. Ati ẹnikẹni ti o ba bá obinrin dàpọ, ti iṣe ẹrú, ti a fẹ́ fun ọkọ, ti a kò ti ràpada rára, ti a kò ti sọ di omnira; ọ̀ran ìna ni; ki a máṣe pa wọn, nitoriti obinrin na ki iṣe omnira. Ki ọkunrin na ki o si mú ẹbọ ẹbi rẹ̀ wá fun OLUWA, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ani àgbo kan fun ẹbọ ẹbi. Ki alufa ki o si fi àgbo ẹbọ ẹbi ṣètutu fun u niwaju OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o da: a o si dari ẹ̀ṣẹ ti o da jì i. Ati nigbati ẹnyin o ba si dé ilẹ na, ti ẹnyin o si gbìn onirũru igi fun onjẹ, nigbana ni ki ẹnyin kà eso rẹ̀ si alaikọlà: li ọdún mẹta ni ki o jasi bi alaikọlà fun nyin; ki a máṣe jẹ ẹ. Ṣugbọn li ọdún kẹrin, gbogbo eso rẹ̀ na ni yio jẹ́ mimọ́, si ìyin OLUWA. Ati li ọdún karun ni ki ẹnyin ki o ma jẹ ninu eso rẹ̀, ki o le ma mú ibisi rẹ̀ wá fun nyin: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ohun kan ti on ti ẹ̀jẹ: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣe ifaiya, tabi ṣe akiyesi ìgba. Ẹnyin kò gbọdọ gẹ̀ ori nyin, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ tọ́ irungbọn rẹ. Ẹnyin kò gbọdọ sín gbẹ́rẹ kan si ara nyin nitori okú, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ kọ àmi kan si ara nyin: Emi li OLUWA. Máṣe bà ọmọ rẹ obinrin jẹ́, lati mu u ṣe àgbere; ki ilẹ na ki o má ba di ilẹ àgbere, ati ki ilẹ na má ba kún fun ìwabuburu. Ki ẹnyin ki o si ma pa ọjọ́ isimi mi mọ́, ki ẹnyin ki o si bọ̀wọ fun ibi mimọ́ mi: Emi li OLUWA. Máṣe yipada tọ̀ awọn ti o ní ìmọ afọṣẹ, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o má si ṣe wá ajẹ́ kiri, lati fi wọn bà ara nyin jẹ́: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. Ki iwọ ki o si dide duro niwaju ori-ewú, ki o si bọ̀wọ fun oju arugbo, ki o si bẹ̀ru Ọlọrun rẹ: Emi li OLUWA. Ati bi alejò kan ba nṣe atipo pẹlu rẹ ni ilẹ nyin, ẹnyin kò gbọdọ ni i lara. Ki alejò ti mbá nyin gbé ki o jasi fun nyin bi ibilẹ, ki iwọ ki o si fẹ́ ẹ bi ara rẹ; nitoripe ẹnyin ti ṣe alejò ni ilẹ Egipti: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. Ẹnyin kò gbọdọ ṣe aiṣododo ni idajọ, ni ìwọn ọpá, ni òṣuwọn iwuwo, tabi ni òṣuwọn oninu. Oṣuwọn otitọ, òṣuwọn iwuwo otitọ, òṣuwọn efa otitọ, ati òṣuwọn hini otitọ, ni ki ẹnyin ki o ní: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá. Nitorina ni ki ẹnyin ki o si ma kiyesi gbogbo ìlana mi, ati si gbogbo idajọ mi, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: Emi li OLUWA.

Lef 19:19-37 Yoruba Bible (YCE)

“Ẹ gbọdọ̀ pa àwọn ìlànà mi mọ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí oríṣìí meji ninu àwọn ohun ọ̀sìn yín gun ara wọn, ẹ kò gbọdọ̀ gbin oríṣìí èso meji sinu oko kan náà, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fi oríṣìí aṣọ meji dá ẹ̀wù kan ṣoṣo. “Bí ọkunrin kan bá bá ẹrubinrin tí ó jẹ́ àfẹ́sọ́nà ẹlòmíràn lòpọ̀, tí wọn kò bá tíì ra ẹrubinrin náà pada, tabi kí wọ́n fún un ní òmìnira rẹ̀, kí wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ náà, ṣugbọn wọn kò gbọdọ̀ tìtorí pé ẹrú ni kí wọn pa wọ́n. Ṣugbọn ọkunrin náà gbọdọ̀ mú àgbò kan tọ OLUWA wá ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, kí ó fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi fún ara rẹ̀. Alufaa yóo fi àgbò ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi náà ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, OLUWA yóo sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì í. “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà, tí ẹ bá sì gbin oríṣìíríṣìí igi eléso fún jíjẹ, ẹ ka gbogbo èso tí wọ́n bá so fún ọdún mẹta ti àkọ́kọ́ sí aláìmọ́; èèwọ̀ ni, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́. Ní ọdún kẹrin, ẹ ya gbogbo àwọn èso náà sọ́tọ̀ fún rírú ẹbọ ọpẹ́ sí OLUWA. Ṣugbọn ní ọdún karun-un, ẹ lè jẹ èso wọn, kí wọ́n lè máa so sí i lọpọlọpọ. Èmi ni OLUWA. “Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran pẹlu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ lọ máa woṣẹ́, tabi kí ẹ gba àjẹ́. Diut 18:10 Ẹ kò gbọdọ̀ gé ẹsẹ̀ irun orí yín tabi kí ẹ gé ẹsẹ̀ irùngbọ̀n yín. Ẹ kò gbọdọ̀ ya ara yín lábẹ nítorí òkú, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fín ara yín rárá. Èmi ni OLUWA. “Ẹ kò gbọdọ̀ ba ọmọbinrin yín jẹ́, nípa fífi ṣe aṣẹ́wó; kí ilẹ̀ náà má baà di ilẹ̀ àgbèrè, kí ó sì kún fún ìwà burúkú. Ẹ gbọdọ̀ pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, kí ẹ sì fi ọ̀wọ̀ wọ ilé mímọ́ mi. Èmi ni OLUWA. “Ẹ kò gbọdọ̀ kó ọ̀rọ̀ yín lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn aláyẹ̀wò tabi àwọn abókùúsọ̀rọ̀, kí wọ́n má baà sọ yín di aláìmọ́. Èmi ni OLUWA. “Ẹ máa bu ọlá fún àwọn ogbó, kí ẹ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbà; kí ẹ sì máa bẹ̀rù Ọlọrun yín. Èmi ni OLUWA. “Nígbà tí àlejò kan bá wọ̀ tì yín ninu ilẹ̀ yín, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe é ní ibi. Bí ẹ ti ń ṣe sí ọmọ onílé ni kí ẹ máa ṣe sí àlejò tí ó wọ̀ sọ́dọ̀ yín, ẹ fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara yín, nítorí pé ẹ̀yin pàápàá ti jẹ́ àlejò rí ní ilẹ̀ Ijipti. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín. “Ẹ kò gbọdọ̀ ṣèrú nígbà tí ẹ bá ń wọn nǹkan fún eniyan, kì báà jẹ́ ohun tí a fi ọ̀pá wọ̀n, tabi ohun tí a fi òṣùnwọ̀n wọ̀n, tabi ohun tí a kà, òṣùnwọ̀n yín gbọdọ̀ péye: ìwọ̀n efa tí ó péye ati ìwọ̀n hini tí ó péye ni ẹ gbọdọ̀ máa lò. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó kó yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá. Ẹ gbọdọ̀ máa pa gbogbo ìlànà mi mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀lé gbogbo òfin mi. Èmi ni OLUWA.”

Lef 19:19-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“ ‘Máa pa àṣẹ mi mọ́. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ohun ọ̀sìn rẹ máa gùn pẹ̀lú ẹ̀yà mìíràn. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbin dàrúdàpọ̀ oríṣìí irúgbìn méjì sínú oko kan. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ wọ aṣọ èyí tí a fi oríṣìí ohun èlò ìhunṣọ méjì ṣe. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá obìnrin tí ó jẹ́ ẹrú lòpọ̀, ẹni tí a ti mọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn tí a kò sì tí ì rà á padà tàbí sọ ọ́ di òmìnira. Ẹ gbọdọ̀ ṣe ìwádìí kí ẹ sì jẹ wọ́n ní ìyà tó tọ́ ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ pa wọ́n, torí pé kò ì tí ì di òmìnira. Kí ọkùnrin náà mú àgbò kan wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé bí i ẹbọ ẹ̀bi sí OLúWA. Àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú àgbò ẹbọ ẹ̀bi náà níwájú OLúWA fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀. A ó sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ náà jì í. “ ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí ẹ sì gbin igi eléso, kí ẹ ká èso wọn sí ohun èèwọ̀. Fún ọdún mẹ́ta ni kí ẹ kà á sí èèwọ̀, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́ Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹrin, gbogbo èso wọ̀nyí yóò jẹ́ mímọ́, ọrẹ fún ìyìn OLúWA. Ní ọdún karùn-ún ni ẹ̀yin tó lè jẹ nínú èso igi náà, kí èso wọn ba à le máa pọ̀ sí i. Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín. “ ‘Ẹ má ṣe jẹ ẹrankẹ́ran pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. “ ‘Ẹ kò gbọdọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ yẹ̀míwò tàbí oṣó. “ ‘Ẹ má ṣe dá òṣù sí àárín orí yín (fífá irun ẹ̀gbẹ́ orí, tí a ó sì dá irun àárín orí sí) tàbí kí ẹ ré orí irùngbọ̀n yín bí àwọn aláìkọlà ti ń ṣe. “ ‘Ẹ má ṣe tìtorí òkú, gé ibi kankan nínú ẹ̀yà ara yín, Ẹ kò sì gbọdọ̀ sín gbẹ́rẹ́ kankan. Èmi ni OLúWA. “ ‘Ẹ má ṣe ba ọmọbìnrin yín jẹ́ láti sọ ọ́ di panṣágà, kí ilẹ̀ yín má ba à di ti àgbèrè, kí ó sì kún fún ìwà búburú. “ ‘Ẹ gbọdọ̀ máa pa ìsinmi mi mọ́ kí ẹ sì fi ọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi, Èmi ni OLúWA. “ ‘Ẹ má ṣe tọ abókùúsọ̀rọ̀ tàbí àwọn àjẹ́ lọ, ẹ kò gbọdọ̀ tọ̀ wọ́n lẹ́yìn láti jẹ́ kí wọ́n sọ yín di aláìmọ́. Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín. “ ‘Fi ọ̀wọ̀ fún ọjọ́ orí arúgbó kí ẹ sì bu ọlá fún àwọn àgbàlagbà. Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run yín: Èmi ni OLúWA. “ ‘Nígbà tí àjèjì kan bá ń gbé pẹ̀lú yín ní ilẹ̀ yín, ẹ má ṣe ṣe é ní ibi kí àjèjì tí ń gbé pẹ̀lú yín dàbí onílé láàrín yín kí ẹ sì fẹ́ràn rẹ̀ bí i ara yín, torí pé ẹ̀yin ti jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Ejibiti rí. Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín. “ ‘Ẹ má ṣe lo òṣùwọ̀n èké, nígbà tí ẹ bá ń díwọ̀n yálà nípa òṣùwọ̀n ọ̀pá, òṣùwọ̀n ìwúwo tàbí òṣùwọ̀n onínú. Ẹ jẹ́ olódodo pẹ̀lú àwọn òṣùwọ̀n yín òṣùwọ̀n ìtẹ̀wọ̀n, òṣùwọ̀n wíwúwo, òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun àti òṣùwọ̀n nǹkan olómi yín ní láti jẹ́ èyí tí kò ní èrú nínú. Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti. “ ‘Ẹ ó sì máa pa gbogbo àṣẹ àti òfin mi mọ́, ẹ ó sì máa ṣe wọ́n. Èmi ni OLúWA.’ ”