Lef 18:24-30
Lef 18:24-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ máṣe bà ara nyin jẹ́ ninu gbogbo nkan wọnyi: nitoripe ninu gbogbo nkan wọnyi li awọn orilẹ-ède, ti mo lé jade niwaju nyin dibajẹ́: Ilẹ na si dibajẹ́: nitorina ni mo ṣe bẹ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ wò lori rẹ̀, ilẹ tikararẹ̀ si bì awọn olugbé rẹ̀ jade. Nitorina ni ki ẹnyin ki o ṣe ma pa ìlana ati ofin mi mọ́, ki ẹnyin ki o máṣe ṣe ọkan ninu irira wọnyi; tabi ẹnikan ninu ibilẹ nyin, tabi alejò ti nṣe atipo ninu nyin: Nitoripe gbogbo irira wọnyi li awọn ọkunrin ilẹ na ṣe, ti o ti wà ṣaju nyin, ilẹ na si dibajẹ́; Ki ilẹ na ki o má ba bì nyin jade pẹlu, nigbati ẹnyin ba bà a jẹ́, bi o ti bì awọn orilẹ-ède jade, ti o ti wà ṣaju nyin. Nitoripe ẹnikẹni ti o ba ṣe ọkan ninu irira wọnyi, ani ọkàn wọnni ti o ba ṣe wọn li a o ke kuro lãrin awọn enia wọn. Nitorina ni ki ẹnyin ki o pa aṣẹ mi mọ́, ki ẹnyin ki o máṣe ọkan ninu irira wọnyi, ti nwọn ti ṣe ṣaju nyin, ki ẹnyin ki o má si bà ara nyin jẹ́ ninu rẹ̀: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
Lef 18:24-30 Yoruba Bible (YCE)
“Má ṣe fi èyíkéyìí ninu àwọn nǹkan tí a dárúkọ wọnyi ba ara rẹ jẹ́, nítorí pé, nǹkan wọnyi ni àwọn orílẹ̀-èdè tí mò ń lé jáde kúrò níwájú yín fi ba ara wọn jẹ́. Ilẹ̀ náà di ìbàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ ẹ́, ilẹ̀ náà sì ń ti àwọn eniyan inú rẹ̀ jáde. Ẹ gbọdọ̀ pa àwọn ìlànà, ati àwọn òfin mi wọnyi mọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyíkéyìí ninu àwọn ohun ìríra wọnyi, kì báà jẹ́ onílé ninu yín, tabi àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin yín. Nítorí pé gbogbo àwọn ohun ìríra wọnyi ni àwọn tí wọ́n ti gbé ilẹ̀ náà ṣáájú yín ti ṣe, tí wọ́n sì fi ba ilẹ̀ náà jẹ́. Kí ilẹ̀ náà má baà ti ẹ̀yin náà jáde nígbà tí ẹ bá bà á jẹ́, bí ó ti ti àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ ṣáájú yín jáde. Nítorí pé, a óo yọ àwọn tí wọ́n bá ṣe àwọn ohun ìríra kúrò láàrin àwọn eniyan wọn. “Nítorí náà, ẹ pa àwọn àṣẹ mi mọ́, kí ẹ má sì ṣe èyíkéyìí ninu àwọn ohun ìríra wọnyi, tí àwọn tí wọ́n ṣáájú yín ṣe, kí ẹ má fi wọ́n ba ara yín jẹ́. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”
Lef 18:24-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“ ‘Má ṣe fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ba ara rẹ jẹ́, torí pé nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí mo lé kúrò níwájú yín ti ba ara wọn jẹ́. Nítorí pé ilẹ̀ náà di àìmọ́ nítorí náà mo fi ìyà jẹ ẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ilẹ̀ náà sì pọ àwọn olùgbé ibẹ̀ jáde. Ṣùgbọ́n kí ẹ máa pa àṣẹ àti òfin mi mọ́. Onílé tàbí àjèjì tó ń gbé láàrín yín kò gbọdọ̀ ṣe ọ̀kan nínú àwọn ohun ìríra wọ̀nyí. Nítorí pé gbogbo ohun ìríra wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ti gbé ilẹ̀ náà ṣáájú yín ti ṣe tí ó sì mú kí ilẹ̀ náà di aláìmọ́. Bí ẹ bá sọ ilẹ̀ náà di àìmọ́ yóò pọ̀ yín jáde bí ó ti pọ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti wá ṣáájú yín jáde. “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ohun ìríra wọ̀nyí, kí ẹ gé irú ẹni náà kúrò láàrín àwọn ènìyàn. Nítorí náà ẹ gbọdọ̀ ṣe ohun tí mo fẹ́, kí ẹ má sì lọ́wọ́ nínú àṣà ìríra wọ̀nyí, tí wọn ń ṣe kí ẹ tó dé. Ẹ má ṣe fi wọ́n ba ara yín jẹ́. Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín.’ ”