Lef 18:1-5
Lef 18:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. Ẹnyin kò gbọdọ hùwa bi ìwa ilẹ Egipti nibiti ẹnyin ti ngbé: ẹnyin kò si gbọdọ hùwa ìwa ilẹ Kenaani, nibiti emi o mú nyin lọ: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ rìn nipa ìlana wọn. Ki ẹnyin ki o ma ṣe ofin mi, ki ẹnyin si ma pa ìlana mi mọ́, lati ma rìn ninu wọn: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. Ẹnyin o si ma pa ìlana mi mọ́, ati ofin mi: eyiti bi enia ba ṣe, on o ma yè ninu wọn: Emi li OLUWA.
Lef 18:1-5 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní kí Mose, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ ti gbé rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní ilẹ̀ Kenaani níbi tí mò ń ko yín lọ. Ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ìlànà wọn. Àwọn òfin mi ni ẹ gbọdọ̀ pamọ́, àwọn ìlànà mi sì ni ẹ gbọdọ̀ máa tẹ̀lé, tí ẹ sì gbọdọ̀ máa tọ̀. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín. Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ máa tẹ̀lé ìlànà mi kí ẹ sì máa pa àwọn òfin mi mọ́. Ẹni tí ó bá ń pa wọ́n mọ́ yóo wà láàyè. Èmi ni OLUWA.
Lef 18:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sọ fún Mose pé: “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: ‘èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní Ejibiti níbi tí ẹ ti gbé rí: bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní ilẹ̀ Kenaani níbi tí èmi ń mú yín lọ. Ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ìṣe wọn. Kí ẹ̀yin kí ó sì máa ṣe òfin mi, kí ẹ̀yin sì máa pa ìlànà mi mọ́, láti máa rìn nínú wọn, Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín. Ẹ̀yin ó sì máa pa ìlànà mi mọ́ àti òfin mi; Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn: Èmi ni OLúWA.