Lef 16:1-3
Lef 16:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si sọ fun Mose lẹhin ikú awọn ọmọ Aaroni meji, nigbati nwọn rubọ niwaju OLUWA, ti nwọn si kú; OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun Aaroni arakunrin rẹ, ki o máṣe wá nigbagbogbo sinu ibi mimọ́, ninu aṣọ-ikele niwaju itẹ́-ãnu, ti o wà lori apoti nì; ki o má ba kú: nitoripe emi o farahàn ninu awọsanma lori itẹ́-ãnu. Bayi ni ki Aaroni ki o ma wá sinu ibi mimọ́: pẹlu ẹgbọrọ akọmalu fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo fun ẹbọ sisun.
Lef 16:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn tí meji ninu àwọn ọmọ Aaroni kú, nígbà tí wọ́n fi iná tí kò mọ́ rúbọ sí OLUWA, OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Sọ fún Aaroni arakunrin rẹ pé kí ó má ṣe máa wọ ibi mímọ́ jùlọ, tí ó wà lẹ́yìn aṣọ títa, níwájú ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí nígbà gbogbo, kí ó má baà kú; nítorí pé n óo fi ara hàn ninu ìkùukùu, lórí ìtẹ́ àánú. Ṣugbọn ohun tí yóo ṣe, nígbà tí yóo bá wọ ibi mímọ́ náà nìyí: kí ó mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan lọ́wọ́ fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati àgbò kan fún ẹbọ sísun.
Lef 16:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sọ fún Mose lẹ́yìn ikú àwọn ọmọ Aaroni méjèèjì tí wọ́n kú nígbà tí wọ́n súnmọ́ OLúWA. OLúWA sì sọ fún Mose pé “Kìlọ̀ fún Aaroni arákùnrin rẹ pé kí ó má ṣe máa wá nígbà gbogbo sí ibi mímọ́ jùlọ tí ó wà lẹ́yìn aṣọ títa ní ibi tí àpótí ẹ̀rí àti ìtẹ́ àánú wà, kí ó má ba à kú” nítorí pé Èmi ó farahàn nínú ìkùùkuu lórí ìtẹ́ àánú. Báyìí ni Aaroni yóò ṣe máa wá sí ibi mímọ́ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti àgbò fún ẹbọ sísun.