Lef 14:1-57

Lef 14:1-57 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA si sọ fun Mose pe, Eyi ni yio ma ṣe ofin adẹ́tẹ li ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀: ki a mú u tọ̀ alufa wá: Ki alufa ki o si jade sẹhin ibudó; ki alufa ki o si wò o, si kiyesi i, bi àrun ẹ̀tẹ na ba jiná li ara adẹ́tẹ na: Nigbana ni ki alufa ki o paṣẹ pe, ki a mú ãye ẹiyẹ meji mimọ́ wá, fun ẹniti a o wẹ̀numọ́, pẹlu igi opepe, ati ododó, ati ewe-hissopu: Ki alufa ki o paṣẹ pe ki a pa ọkan ninu ẹiyẹ nì ninu ohunèlo àmọ li oju omi ti nṣàn: Niti ẹiyẹ alãye, ki o mú u, ati igi opepe, ati ododó, ati ewe-hissopu, ki o si fi wọn ati ẹiyẹ alãye nì bọ̀ inu ẹ̀jẹ ẹiyẹ ti a pa li oju omi ti nṣàn: Ki o si fi wọ́n ẹniti a o wẹ̀numọ́ kuro ninu ẹ̀tẹ nigba meje, ki o si pè e ni mimọ́, ki o si jọwọ ẹiyẹ alãye nì lọwọ lọ si gbangba oko. Ki ẹniti a o wẹ̀numọ́ nì ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si fá gbogbo irun ori rẹ̀ kuro, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o le mọ́: lẹhin eyinì ni ki o wọ̀ ibudó, ṣugbọn ki o gbé ẹhin ode agọ́ rẹ̀ ni ijọ́ meje. Yio si ṣe ni ijọ́ keje, ni ki o fá gbogbo irun ori rẹ̀ kuro li ori rẹ̀, ati irungbọn rẹ̀, ati ipenpeju rẹ̀, ani gbogbo irun rẹ̀ ni ki o fá kuro: ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ pẹlu ninu omi, on o si di mimọ́. Ni ijọ́ kẹjọ ki o mú ọdọ-agutan meji akọ alailabùku wá, ati ọdọ-agutan kan abo ọlọdún kan alailabùku, ati idamẹwa mẹta òṣuwọn deali iyẹfun didara fun ẹbọ ohunjijẹ, ti a fi oróro pò, ati òṣuwọn logu oróro kan. Ki alufa ti o sọ ọ di mimọ́ ki o mú ọkunrin na ti a o sọ di mimọ́, ati nkan wọnni wá, siwaju OLUWA, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: Ki alufa ki o mú akọ ọdọ-agutan kan, ki o si fi i ru ẹbọ ẹbi, ati òṣuwọn logu oróro, ki o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA: Ki o si pa akọ ọdọ-agutan na ni ibiti on o gbé pa ẹbọ ẹ̀ṣẹ ati ẹbọ sisun, ní ibi mimọ́ nì: nitoripe bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ ti jẹ́ ti alufa, bẹ̃ si ni ẹbọ irekọja: mimọ́ julọ ni: Ki alufa ki o si mú ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹbi na, ki alufa ki o si fi i si eti ọtún ẹniti a o wẹ̀numọ́, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀: Ki alufa ki o si mú ninu oróro òṣuwọn logu na, ki o si dà a si atẹlẹwọ òsi ara rẹ̀: Ki alufa ki o si tẹ̀ ika rẹ̀ ọtún bọ̀ inu oróro na ti mbẹ li ọwọ́ òsi rẹ̀, ki o si fi ika rẹ̀ ta ninu oróro na nigba meje niwaju OLUWA: Ati ninu oróro iyokù ti mbẹ li ọwọ́ rẹ̀ ni ki alufa ki o fi si etí ọtún ẹniti a o wẹ̀numọ́, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀, lori ẹ̀jẹ ẹbọ ẹbi: Ati oróro iyokù ti mbẹ li ọwọ́ alufa ni ki o dà si ori ẹniti a o wẹ̀numọ́: ki alufa ki o si ṣètutu fun u niwaju OLUWA. Ki alufa ki o si ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ki o si ṣètutu fun ẹniti a o wẹ̀numọ́ kuro ninu aimọ́ rẹ̀; lẹhin eyinì ni ki o pa ẹran ẹbọ sisun. Ki alufa ki o si ru ẹbọ sisun, ati ẹbọ ohunjijẹ lori pẹpẹ: ki alufa ki o ṣètutu fun u, on o si di mimọ́. Bi o ba si ṣe talaka, ti kò le mú tobẹ̃ wá, njẹ ki o mú akọ ọdọ-agutan kan wá fun ẹbọ ẹbi lati fì, lati ṣètutu fun u, ati ọkan ninu idamẹwa òṣuwọn deali iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ, ati òṣuwọn logu oróro kan; Ati àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji, irú eyiti ọwọ́ rẹ̀ ba to; ki ọkan ki o si ṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ki ekeji ki o si ṣe ẹbọ sisun. Ki o si mú wọn tọ̀ alufa wá ni ijọ́ kẹjọ fun ìwẹnumọ́ rẹ̀, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, niwaju OLUWA. Ki alufa ki o si mú ọdọ-agutan ẹbọ ẹbi, ati òṣuwọn logu oróro, ki alufa ki o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA. Ki o si pa ọdọ-agutan ẹbọ ẹbi, ki alufa ki o si mú ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹbi na, ki o si fi i si etí ọtún ẹniti a o wẹ̀numọ́, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀. Ki alufa ki o si dà ninu oróro na si atẹlẹwọ òsi ara rẹ̀: Ki alufa ki o si fi iká rẹ̀ ọtún ta ninu oróro na ti mbẹ li ọwọ́ òsi rẹ̀ nigba meje niwaju OLUWA: Ki alufa ki o si fi ninu oróro na ti mbẹ li ọwọ́ rẹ̀ si eti ọtún ẹniti a o wẹ̀numọ́, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀, si ibi ẹ̀jẹ ẹbọ ẹbi: Ati oróro iyokù ti mbẹ li ọwọ́ alufa ni ki o fi si ori ẹniti a o wẹ̀numọ́, lati ṣètutu fun u niwaju OLUWA. Ki o si fi ọkan ninu àdaba nì rubọ, tabi ọkan ninu ọmọ ẹiyẹle nì, iru eyiti ọwọ́ rẹ̀ ba to: Ani irú eyiti apa rẹ̀ ka, ọkan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji fun ẹbọ sisun, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ: ki alufa ki o si ṣètutu fun ẹniti a o wẹ̀numọ́ niwaju OLUWA. Eyi li ofin rẹ̀ li ara ẹniti àrun ẹ̀tẹ wà, apa ẹniti kò le ka ohun ìwẹnumọ́ rẹ̀. OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ Kenaani, ti mo fi fun nyin ni ilẹ-iní, ti mo ba si fi àrun ẹ̀tẹ sinu ile kan ninu ilẹ-iní nyin; Ti onile na si wá ti o si wi fun alufa pe, O jọ li oju mi bi ẹnipe àrun mbẹ ninu ile na: Nigbana ni ki alufa ki o fun wọn li aṣẹ, ki nwọn ki o kó ohun ile na jade, ki alufa ki o to wọ̀ inu rẹ̀ lọ lati wò àrun na, ki ohun gbogbo ti mbẹ ninu ile na ki o máṣe jẹ́ alaimọ́: lẹhin eyinì ni ki alufa ki o wọ̀ ọ lati wò ile na: Ki o si wò àrun na, si kiyesi i, bi àrun na ba mbẹ lara ogiri ile na pẹlu ìla gbòrogbòro, bi ẹni ṣe bi ọbẹdò tabi pupa rusurusu, ti o jìn li oju jù ogiri lọ; Nigbana ni ki alufa ki o jade ninu ile na si ẹnu-ọ̀na ile na, ki o si há ilẹkun ile na ni ijọ́ meje: Ki alufa ki o tun wá ni ijọ́ keje, ki o si wò o: si kiyesi i, bi àrun na ba ràn lara ogiri ile na; Nigbana ni ki alufa ki o paṣẹ ki nwọn ki o yọ okuta na kuro lara eyiti àrun na gbé wà, ki nwọn ki o si kó wọn lọ si ibi aimọ́ kan lẹhin ilu na: Ki o si mu ki nwọn ki o ha inu ile na yiká kiri, ki nwọn ki o kó erupẹ ti a ha nì kuro lọ si ẹhin ilu na si ibi aimọ́ kan: Ki nwọn ki o si mú okuta miran, ki nwọn ki o si fi i di ipò okuta wọnni, ki nwọn ki o si mú ọrọ miran ki nwọn ki o si fi rẹ́ ile na. Bi àrùn na ba si tun pada wá, ti o si tun sọ jade ninu ile na, lẹhin igbati nwọn ba yọ okuta wọnni kuro, ati lẹhin igbati nwọn ba ha ile na, ati lẹhin igbati nwọn ba rẹ́ ẹ; Nigbana ni ki alufa ki o wá, ki o wò o, si kiyesi i, bi àrun ba ràn si i ninu ile na, ẹ̀tẹ kikẹ̀ ni mbẹ ninu ile na: aimọ́ ni. Ki o si wó ile na, okuta rẹ̀, ati ìti igi rẹ̀, ati gbogbo erupẹ ile na; ki o si kó wọn jade kuro ninu ilu na lọ si ibi aimọ́ kan. Ẹniti o ba si wọ̀ ile na ni gbogbo ìgba na ti a sé e mọ́, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. Ẹniti o ba dubulẹ ninu ile na ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀: ẹniti o jẹun ninu ile na ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀. Ati bi alufa ba wọ̀ ile, ti o si wò o, si kiyesi i, ti àrun inu ile na kò ba ràn si i, lẹhin igbati a rẹ́ ile na tán; nigbana ni ki alufa ki o pè ile na ni mimọ́, nitoripe àrun na ti jiná. Ki o si mú ẹiyẹ meji, ati igi opepe, ati ododó, ati ewe-hissopu wá, lati wẹ̀ ile na mọ́: Ki o si pa ọkan ninu ẹiyẹ na, ninu ohunèlo amọ loju omi ti nṣàn: Ki o si mú igi opepe, ati ewe-hissopu, ati ododó, ati ẹiyẹ alãye nì, ki o si tẹ̀ wọn bọ̀ inu ẹ̀jẹ ẹiyẹ ti a pa nì, ati ninu omi ṣiṣàn nì, ki o si fi wọ́n ile na nigba meje: Ki o si fi ẹ̀jẹ ẹiyẹ na wẹ̀ ile na mọ́, ati pẹlu omi ṣiṣàn nì, ati pẹlu ẹiyẹ alãye nì, ati pẹlu igi opepe nì, ati pẹlu ewe-hissopu nì, ati pẹlu ododó: Ṣugbọn ki o jọwọ ẹiyẹ alãye nì lọwọ lọ kuro ninu ilu lọ sinu gbangba oko, ki o si ṣètutu si ile na: yio si di mimọ́. Eyi li ofin fun gbogbo onirũru àrun ẹ̀tẹ, ati ipẹ́; Ati fun ẹ̀tẹ aṣọ, ati ti ile; Ati fun wiwu, ati fun apá, ati fun àmi didán: Lati kọni nigbati o ṣe alaimọ́, ati nigbati o ṣe mimọ́: eyi li ofin ẹ̀tẹ.

Lef 14:1-57 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA sọ fún Mose pé, “Òfin tí ó jẹmọ́ ti ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ adẹ́tẹ̀ nìyí: kí wọ́n mú adẹ́tẹ̀ náà wá sí ọ̀dọ̀ alufaa. Kí alufaa jáde kúrò ninu àgọ́, kí ó sì yẹ̀ ẹ́ wò bí àrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá ti san. Alufaa yóo pàṣẹ pé kí wọ́n bá ẹni tí wọ́n fẹ́ ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún mú ẹyẹ mímọ́ meji wá ati igi kedari, pẹlu aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́ kan, ati ewé hisopu. Alufaa yóo pàṣẹ pé kí wọ́n pa ọ̀kan ninu àwọn ẹyẹ náà sinu ìkòkò amọ̀, lórí odò tí ń ṣàn. Yóo mú ẹyẹ tí ó wà láàyè ati igi kedari, ati aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́, ati ewé hisopu, yóo pa wọ́n pọ̀, yóo sì tì wọ́n bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí wọ́n pa lórí odò tí ń ṣàn. Yóo wọ́n ọn sí ara ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́ kúrò ninu àrùn ẹ̀tẹ̀ náà nígbà meje. Lẹ́yìn náà alufaa yóo pè é ní mímọ́, yóo sì jẹ́ kí ẹyẹ keji tí ó wà láàyè, fò wọ igbó lọ. Kí ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́ náà fọ aṣọ rẹ̀, kí ó fá irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo sì di mímọ́. Lẹ́yìn náà, yóo wá sí ibùdó, ṣugbọn ẹ̀yìn àgọ́ rẹ̀ ni yóo máa gbé fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ keje yóo fá irun orí rẹ̀, ati irùngbọ̀n rẹ̀, ati irun ìpéǹpéjú rẹ̀ ati gbogbo irun ara rẹ̀ patapata, yóo fọ gbogbo aṣọ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, yóo wẹ̀, yóo sì di mímọ́. “Ní ọjọ́ kẹjọ, yóo mú ọ̀dọ́ àgbò meji tí kò lábàwọ́n, ati ọ̀dọ́ abo aguntan ọlọ́dún kan tí kò lábàwọ́n, ati ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, tí a fi òróró pò ati ìwọ̀n ìgò òróró kan fún ẹbọ ohun jíjẹ. Alufaa tí ó ṣe ètò ìwẹ̀nùmọ́ ẹni náà yóo mú adẹ́tẹ̀ náà ati àwọn nǹkan ìwẹ̀nùmọ́ wá siwaju OLUWA lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Lẹ́yìn náà, yóo mú ọ̀kan ninu àwọn ọ̀dọ́ àgbò náà, yóo fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, pẹlu ìwọ̀n ìgò òróró kan, yóo fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA. Alufaa náà yóo pa àgbò náà níbi tí wọ́n ti máa ń pa ẹran fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ti ẹbọ sísun ninu ibi mímọ́, nítorí pé ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi jẹ́ ti alufaa, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀; ohun mímọ́ patapata ni. Alufaa yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi yìí, yóo fi kan ṣóńṣó etí ọ̀tún, ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́. Alufaa yóo mú ninu ìwọ̀n ìgò òróró náà, yóo dà á sí àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀. Yóo ti ìka ọ̀tún rẹ̀ bọ òróró tí ó wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀, yóo sì fi ìka rẹ̀ wọ́n òróró náà níwájú OLUWA ní ìgbà meje. Alufaa yóo mú ninu òróró tí ó kù ní ọwọ́ òsì rẹ̀, yóo fi kan ṣóńṣó etí ọ̀tún ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́, ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀, tí ó ti kọ́ fi ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi kàn. Alufaa yóo fi òróró tí ó kù ní ọwọ́ rẹ̀ ra orí ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́. Lẹ́yìn náà, yóo ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA. “Alufaa yóo rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́, lẹ́yìn náà, yóo pa ẹran ẹbọ sísun náà. Alufaa yóo rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ lórí pẹpẹ. Bẹ́ẹ̀ ni alufaa yóo ṣe ṣe ètùtù fún un, tí yóo sì di mímọ́. “Ṣugbọn bí adẹ́tẹ̀ náà bá talaka tóbẹ́ẹ̀ tí apá rẹ̀ kò ká àwọn nǹkan tí a kà sílẹ̀ wọnyi, ó lè mú àgbò kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, tí alufaa yóo fì, láti fi ṣe ètùtù fún un. Kí ó sì tún mú ìdámẹ́wàá ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun kan tí ó kúnná dáradára, tí wọ́n fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ, pẹlu ìwọ̀n ìgò òróró kan, ati àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji, èyíkéyìí tí apá rẹ̀ bá ká. Wọn yóo fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, wọn yóo sì fi ekeji rú ẹbọ sísun. Ní ọjọ́ kẹjọ, yóo kó wọn tọ alufaa wá ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, níwájú OLUWA fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀. Alufaa yóo mú àgbò ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi ati ìwọ̀n ìgò òróró náà, yóo fì wọ́n bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA. Yóo pa àgbò ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, yóo sì mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi kan ṣóńṣó etí ọ̀tún ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́ ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀. Alufaa yóo bu díẹ̀ ninu òróró náà sí àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀, yóo ti ìka bọ inú òróró tí ó wà ní ọwọ́ òsì yìí, yóo sì wọ́n ọn sílẹ̀ níwájú OLUWA nígbà meje. Alufaa yóo mú díẹ̀ ninu òróró tí ó wà ni ọwọ́ òsì rẹ̀, yóo fi kan ṣóńṣó etí ọ̀tún ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́ ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ tí ó ti kọ́ fi ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi kàn. Alufaa yóo mú òróró tí ó kù ní ọwọ́ rẹ̀ yóo sì fi ra orí ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́, láti fi ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA. Yóo fi èyí tí apá rẹ̀ bá ká rúbọ: yálà àdàbà tabi ẹyẹlé; ọ̀kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ekeji fún ẹbọ sísun, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ. Alufaa yóo sì ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA. Èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ti ẹni tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀, ṣugbọn tí apá rẹ̀ kò ká àwọn ohun ìrúbọ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀.” OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kenaani tí n óo fun yín, tí yóo jẹ́ ohun ìní yín, bí mo bá fi àrùn ẹ̀tẹ̀ sí ilé kan ninu ilẹ̀ yín. Ẹni tí ó ni ilé náà yóo wá sọ fún alufaa pé, ‘Ó dàbí ẹni pé àrùn kan wà ní ilé mi.’ Kí alufaa pàṣẹ pé kí wọn kó gbogbo ohun tí ó wà ninu ilé náà jáde, kí ó tó lọ yẹ àrùn náà wò; kí ó má baà pe gbogbo ohun tí ó wà ninu ilé náà ní aláìmọ́; lẹ́yìn náà, kí alufaa lọ wo ilé náà. Kí ó yẹ àrùn náà wò, bí ó bá jẹ́ pé lára ògiri ilé ni àrùn yìí wà, tí ibi tí ó wà lára ògiri náà dàbí àwọ̀ ewéko tabi tí ó pọ́n, tí ọ̀gangan ibẹ̀ sì jìn ju ara ògiri lọ. Kí alufaa jáde kúrò ninu ilé náà, kí ó lọ síbi ìlẹ̀kùn, kí ó ti ìlẹ̀kùn ilé náà fún ọjọ́ meje. Alufaa yóo pada wá ní ọjọ́ keje láti yẹ ilé náà wò. Bí àrùn bá ti tàn káàkiri lára ògiri ilé náà, yóo pàṣẹ pé kí wọn yọ àwọn òkúta tí àrùn wà lára wọn, kí wọ́n kó wọn sí ibìkan tí kò mọ́ lẹ́yìn ìlú. Yóo pàṣẹ pé kí wọ́n ha gbogbo ògiri ilé náà yípo, kí wọ́n kó gbogbo ohun tí wọ́n fi rẹ́ ilé, tí wọ́n ha kúrò, kí wọ́n dà á sí ibìkan tí kò mọ́ lẹ́yìn ìlú. Wọn yóo wá wá àwọn òkúta mìíràn, wọn yóo fi dípò àwọn tí wọ́n yọ kúrò, yóo sì fi ohun ìrẹ́lé mìíràn tún ilé náà rẹ́. “Bí àrùn yìí bá tún jẹ jáde lára ilé náà, lẹ́yìn tí ó ti yọ àwọn òkúta àkọ́kọ́ jáde, tí ó ti ha ògiri ilé náà, tí ó sì ti tún un rẹ́, alufaa yóo lọ yẹ ilé náà wò. Bí àrùn náà bá tàn káàkiri lára ògiri ilé náà, a jẹ́ pé àrùn ẹ̀tẹ̀ tí í máa ń tàn káàkiri ni; ilé náà kò mọ́. Wọ́n gbọdọ̀ wó o lulẹ̀ ni, kí wọ́n ru gbogbo òkúta rẹ̀ ati igi tí wọ́n fi kọ́ ọ ati ohun ìrẹ́lé tí wọ́n fi rẹ́ ẹ jáde kúrò láàrin ìlú, lọ sí ibi tí kò mọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ ilé náà lẹ́yìn tí alufaa ti tì í pa, yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sùn ninu ilé náà tabi tí ó bá jẹun ninu rẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀. “Ṣugbọn bí alufaa bá wá yẹ ilé náà wò, tí àrùn náà kò bá tàn káàkiri lára ògiri rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti tún un rẹ́, alufaa yóo pe ilé náà ní mímọ́, nítorí àrùn náà ti san. Nígbà tí alufaa bá fẹ́ sọ ilé náà di mímọ́, yóo mú ẹyẹ kéékèèké meji ati igi kedari ati aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́ kan, ati ewé hisopu, yóo pa ọ̀kan ninu àwọn ẹyẹ náà sinu ìkòkò amọ̀ lórí odò tí ń ṣàn, yóo mú igi Kedari ati ewé hisopu ati aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́ náà, ati ẹyẹ keji, tí ó wà láàyè, yóo tì wọ́n bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí ó pa lórí odò tí ń ṣàn, yóo wọ́n ọn sára ilé náà nígbà meje. Bẹ́ẹ̀ ni yóo ṣe fi ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ náà ati omi tí ń ṣàn, ati ẹyẹ tí ó wà láàyè, ati igi Kedari, ati ewé hisopu, ati aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́ náà sọ ilé náà di mímọ́ pada. Yóo ju ẹyẹ náà sílẹ̀ kí ó lè fò jáde kúrò ninu ìlú, lọ sinu pápá, yóo fi ṣe ètùtù fún ìwẹ̀nùmọ́ ilé náà, ilé náà yóo sì di mímọ́.” Àwọn òfin tí a ti kà sílẹ̀ wọnyi ni òfin tí ó jẹmọ́ oríṣìíríṣìí àrùn ẹ̀tẹ̀ ati ti ẹ̀yi ara; ati ti àrùn ẹ̀tẹ̀ lára aṣọ tabi lára ilé, ati ti oríṣìíríṣìí egbò, ati oówo, ati ti ara wúwú, tabi ti aṣọ tabi ilé tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bò, láti fi hàn bí ó bá jẹ́ mímọ́, tabi kò jẹ́ mímọ́. Àwọn ni òfin tí ó jẹmọ́ àrùn ẹ̀tẹ̀.

Lef 14:1-57 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA sọ fún Mose pé, “Èyí ni àwọn ìlànà fún ẹni tí ààrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú ní àkókò ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, bí a bá mú un tọ àlùfáà wá. Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò ní ẹ̀yìn ibùdó bí ara rẹ̀ bá ti yá kúrò nínú ààrùn ẹ̀tẹ̀ náà. Kí àlùfáà pàṣẹ pé kí a mú ààyè ẹyẹ mímọ́ méjì, igi kedari, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù wá fún ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́. Kí àlùfáà pàṣẹ pé kí wọn pa ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ náà sórí omi tí ó mọ́ tó wà nínú ìkòkò amọ̀. Lẹ́yìn náà kí ó ri ààyè ẹyẹ pẹ̀lú igi kedari, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí a ti pa sínú omi náà. Ìgbà méje ni kí o wọ́n omi yìí sí ara ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́ kúrò nínú ààrùn ara náà kí ó ju ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ ní ìta gbangba. “Ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, fá gbogbo irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, lẹ́yìn èyí ó ti di mímọ́. Lẹ́yìn náà ó le wá sínú ibùdó ṣùgbọ́n kí ó wà lẹ́yìn àgọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ méje. Kí ó fá gbogbo irun rẹ̀ ní ọjọ́ keje: irun orí rẹ̀, irùngbọ̀n rẹ̀, irun ìpéǹpéjú rẹ̀, àti gbogbo irun rẹ̀ tókù. Kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì mọ́. “Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó mú àgbò aláìlábùkù méjì àti abo ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan tí wọn kò ní àlébù wá, pẹ̀lú ìdámẹ́wàá nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun tí à pòpọ̀ mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ àti òṣùwọ̀n lógù òróró kan. Àlùfáà tí ó pè é ní mímọ́: yóò mú ẹni náà tí a ó sọ di mímọ́ àti ọrẹ rẹ̀ wá síwájú OLúWA ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. “Kí àlùfáà mú ọ̀kan nínú àwọn àgbò àti lógù òróró kí ó sì fi rú ẹbọ ẹ̀bi. Kí ó sì fì wọ́n níwájú OLúWA gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì. Kí ó pa àgbò náà ní ibi mímọ́ níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ sísun. Bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ ẹ̀bi náà jẹ́ ti àlùfáà: ó jẹ́ mímọ́ jùlọ. Kí àlùfáà mú nínú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi náà kí ó fi sí etí ọ̀tún ẹni náà tí a ó wẹ̀mọ́, kí ó tún fi sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti orí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀. Àlùfáà yóò sì mú díẹ̀ nínú lógù òróró, yóò sì dà á sí àtẹ́lẹwọ́ òsì ara rẹ̀. Yóò sì ti ìka ìfábẹ̀lá ọ̀tún rẹ̀ bọ inú òróró àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, yóò sì wọ́n díẹ̀ nínú rẹ̀ níwájú OLúWA nígbà méje. Àlùfáà yóò mú lára òróró tí ó kù ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ yóò fi sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí à ó wẹ̀mọ́, lórí ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi. Àlùfáà yóò fi òróró tí ó kù ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ ra orí ẹni tí a ó wẹ̀mọ́, yóò sì ṣe ètùtù fún un níwájú OLúWA. “Àlùfáà yóò sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀: yóò ṣe ètùtù fún ẹni tí a ó wẹ̀ kúrò nínú àìmọ́ rẹ̀, lẹ́yìn náà àlùfáà yóò pa ẹran ọrẹ ẹbọ sísun. Kí àlùfáà kí ó sì rú ẹbọ sísun, àti ẹbọ ohun jíjẹ lórí pẹpẹ, kí àlùfáà kí ó sì ṣe ètùtù fún un: Òun yóò sì di mímọ́. “Bí ẹni náà bá jẹ́ tálákà tí kò sì le è kó gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, kí ó mú ọ̀dọ́ àgbò kan bí ẹbọ ẹ̀bi, tí yóò fì, láti ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun dídára, a pò mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ òṣùwọ̀n lógù òróró àti àdàbà méjì tàbí ẹyẹlé méjì èyí tí agbára rẹ̀ ká, ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun. “Kí ó mú wọn wá ní ọjọ́ kẹjọ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ síwájú àlùfáà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú OLúWA. Àlùfáà náà yóò sì mú ọ̀dọ́-àgùntàn ẹbọ ẹ̀bi pẹ̀lú lógù òróró yóò sì fì wọ́n níwájú OLúWA bí ẹbọ fífì. Kí ó pa ọ̀dọ́-àgùntàn ẹbọ ẹ̀bi kí ó sì mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Kí ó fi sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí a ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún. Àlùfáà yóò sì da díẹ̀ lára òróró náà sí àtẹ́lẹwọ́ òsì ara rẹ̀. Yóò sì fi ìka ìfábẹ̀lá ọ̀tún rẹ̀ wọ́n òróró tí ó wà ní àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀ nígbà méje níwájú OLúWA. Àlùfáà yóò sì mú lára òróró ọwọ́ rẹ̀ sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ní ibi kan náà tí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi sí. Kí àlùfáà fi ìyókù nínú òróró ọwọ́ rẹ̀ sí orí ẹni náà tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún: láti ṣe ètùtù fún un ní iwájú OLúWA. Lẹ́yìn náà kí ó fi àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé rú ẹbọ níwọ̀n tí agbára rẹ̀ mọ. Ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ: Àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù níwájú OLúWA ní ipò ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́.” Òfin nìyí fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ààrùn ara tí ó le ran tí kò sì lágbára láti rú ẹbọ tí ó yẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ bí a ti fi lélẹ̀. OLúWA sọ fún Mose àti Aaroni pé. “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kenaani tí mo fi fún yín ní ìní, tí mo sì fi ààrùn ẹ̀tẹ̀ sínú ilé kan ní ilẹ̀ ìní yín. Kí ẹni tí ó ní ilé náà lọ sọ fún àlùfáà pé, ‘Èmi tí rí ohun tí ó jọ ààrùn ẹ̀tẹ̀ ní ilé mi.’ Àlùfáà yóò pàṣẹ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun má ṣe wà nínú ilé náà, kí ó tó lọ yẹ ẹ̀tẹ̀ náà wò, kí ohunkóhun nínú ilé náà má bá à di àìmọ́. Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wọlé lọ láti yẹ ilé náà wò. Yóò yẹ ààrùn náà wò, bí ààrùn náà bá ti wà lára ògiri ilé náà nípa ààmì àwọ̀ ewé tàbí ààmì pupa tí ó sì jinlẹ̀, ju ara ògiri lọ. Àlùfáà yóò jáde kúrò nínú ilé náà, yóò sì ti ìlẹ̀kùn ilé náà pa fún ọjọ́ méje. Àlùfáà yóò padà wá yẹ ilé náà wò ní ọjọ́ keje. Bí ààrùn náà bá ti tàn ká ara ògiri. Àlùfáà yóò pàṣẹ kí a yọ àwọn òkúta tí ààrùn náà ti bàjẹ́ kúrò kí a sì kó wọn dànù sí ibi tí a kà sí àìmọ́ lẹ́yìn ìlú. Yóò sì mú kí wọ́n ha ògiri inú ilé náà yíká. Gbogbo ohun tí wọ́n fi rẹ́ ilé náà tí ó ti ha ni kí wọ́n kó dànù sí ibi tí a kà sí àìmọ́ lẹ́yìn ìlú náà. Òkúta mìíràn ni kí wọ́n fi dípò àwọn tí a ti yọ dànù, kí wọ́n sì rẹ́ ilé náà pẹ̀lú àwọn ohun ìrẹ́lé tuntun. “Bí ààrùn yìí bá tún farahàn lẹ́yìn tí a ti yọ àwọn òkúta wọ̀nyí tí a sì ti ha ilé náà ti a sì tún rẹ́ ẹ. Àlùfáà yóò tún lọ yẹ̀ ẹ́ wò bí ààrùn náà bá tún gbilẹ̀ sí i nínú ilé náà: ẹ̀tẹ̀ apanirun ni èyí, ilé náà jẹ́ aláìmọ́. Wíwó ni kí a wó o, gbogbo òkúta ilé náà, àwọn igi àti gbogbo ohun tí a fi rẹ́ ẹ ni kí a kó jáde nínú ìlú sí ibi tí a kà sí àìmọ́. “Ẹni tí ó bá wọ inú ilé náà lẹ́yìn tí a ti tì í, yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Ẹni tí ó bá sùn nínú ilé náà tàbí tí ó bá jẹun nínú rẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀. “Bí àlùfáà bá wá yẹ̀ ẹ́ wò tí ààrùn náà kò gbilẹ̀ mọ́ lẹ́yìn tí a ti rẹ́ ilé náà: kí àlùfáà pe ilé náà ní mímọ́, torí pé ààrùn náà ti lọ. Láti sọ ilé yìí di mímọ́. Àlùfáà yóò mú ẹyẹ méjì àti igi kedari òdòdó àti hísópù. Yóò sì pa ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ náà sórí omi tí ó mọ́ nínú ìkòkò amọ̀. Kí ó ri igi kedari, hísópù, òdòdó àti ààyè ẹyẹ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ òkú ẹyẹ àti omi tí ó mọ́ náà kí ó fi wọ́n ilẹ̀ náà lẹ́ẹ̀méje. Yóò fi ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ náà, omi tí ó mọ́, ààyè ẹyẹ, igi kedari, hísópù àti òdòdó sọ ilé náà di mímọ́. Kí àlùfáà ju ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ lẹ́yìn ìlú. Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún ilé náà. Ilé náà yóò sì mọ́.” Àwọn wọ̀nyí ni ìlànà fún èyíkéyìí ààrùn àwọ̀ ara tí ó le è ràn ká (ẹ̀tẹ̀), fún làpálàpá, àti fún ẹ̀tẹ̀ nínú aṣọ, àti ti ilé, fún ìwú, fún èélá àti ibi ara dídán. Láti mú kí a mọ̀ bóyá nǹkan mọ́ tàbí kò mọ́. Ìwọ̀nyí ni àwọn òfin fún ààrùn àwọ̀ ara tí ó ń ràn ká àti ẹ̀tẹ̀.