Lef 13:45-46
Lef 13:45-46 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati adẹ́tẹ na, li ara ẹniti àrun na gbé wà, ki o fà aṣọ rẹ̀ ya, ki o si fi ori rẹ̀ silẹ ni ìhoho, ki o si fi ìbo bò ète rẹ̀ òke, ki o si ma kepe, Alaimọ́, alaimọ́. Ni gbogbo ọjọ́ ti àrun na mbẹ li ara rẹ̀ ni ki o jẹ́ elẽri; alaimọ́ ni: on nikan ni ki o ma gbé; lẹhin ibudó ni ibujoko rẹ̀ yio gbé wà.
Lef 13:45-46 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹni tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ yìí gbọdọ̀ wọ aṣọ tí ó ya, kí ó fi apá kan irun orí rẹ̀ sílẹ̀ játijàti, kí ó bo ètè rẹ̀ òkè, kí ó sì máa ké pé, ‘Aláìmọ́! Aláìmọ́!’ Yóo jẹ́ aláìmọ́, níwọ̀n ìgbà tí àrùn yìí bá wà lára rẹ̀. Ó jẹ́ aláìmọ́; òun nìkan ni yóo sì máa dá gbé lẹ́yìn ibùdó.
Lef 13:45-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Kí ẹni tí ààrùn náà wà ní ara rẹ̀ wọ àkísà. Kí ó má ṣe gé irun rẹ̀, kí ó daṣọ bo ìsàlẹ̀ ojú rẹ̀ kí ó sì máa ké wí pé, ‘Aláìmọ́! Aláìmọ́!’ Gbogbo ìgbà tí ààrùn náà bá wà ní ara rẹ̀; aláìmọ́ ni: kí ó máa dágbé. Kí ó máa gbé lẹ́yìn ibùdó.