Lef 13:1-17

Lef 13:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, Nigbati enia kan ba ní iwú, apá, tabi àmi didán kan li awọ ara rẹ̀, ti o si mbẹ li awọ ara rẹ̀ bi àrun ẹ̀tẹ; nigbana ni ki a mú u tọ̀ Aaroni alufa wá, tabi ọkan ninu awọn ọmọ rẹ̀, alufa: Alufa yio si wò àrun ti mbẹ li awọ ara rẹ̀: bi irun ti mbẹ li oju àrun na ba si di funfun, ati ti àrun na li oju rẹ̀ ba jìn jù awọ ara rẹ̀ lọ, àrun ẹ̀tẹ ni: ki alufa ki o si wò o, ki o si pè e li alaimọ́. Bi àmi didán na ba funfun li awọ ara rẹ̀, ati li oju rẹ̀ ti kò si jìn jù awọ lọ, ti irun rẹ̀ kò di funfun, nigbana ni ki alufa ki o sé alarun na mọ́ ni ijọ́ meje: Ki alufa ki o si wò o ni ijọ́ keje: si kiyesi i, bi àrun na ba duro li oju rẹ̀, ti àrun na kò ba si ràn li ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o sé e mọ́ ni ijọ́ meje si i: Ki alufa ki o si tun wò o ni ijọ́ keje: si kiyesi i, bi àrun na ba ṣe bi ẹni wodú, ti àrun na kò si ràn si i li awọ ara, ki alufa ki o pè e ni mimọ́: kìki apá ni: ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o jẹ́ mimọ́. Ṣugbọn bi apá na ba ràn pupọ̀ si i li awọ ara, lẹhin igbati alufa ti ri i tán fun mimọ́ rẹ̀, alufa yio si tun wò o. Alufa yio wò o, kiyesi i, apá na ràn li awọ ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e li alaimọ́: ẹ̀tẹ ni. Nigbati àrun ẹ̀tẹ ba mbẹ li ara enia, nigbana ni ki a mú u tọ̀ alufa wá; Ki alufa ki o si wò o, si kiyesi i, bi iwú na ba funfun li awọ ara rẹ̀, ti o si sọ irun rẹ̀ di funfun, ti õju si mbẹ ninu iwú na, Ẹ̀tẹ lailai ni li awọ ara rẹ̀, ki alufa ki o pè e li alaimọ́: ki o máṣe sé e mọ́; nitoripe alaimọ́ ni. Bi ẹ̀tẹ ba si sọ jade kakiri li awọ ara, ti ẹ̀tẹ na ba si bò gbogbo ara ẹniti o ní àrun na, lati ori rẹ̀ titi dé ẹsẹ̀ rẹ̀, nibikibi ti alufa ba wò; Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi ẹ̀tẹ na ba bò gbogbo ara rẹ̀, ki o pè àlarun na ni mimọ́; gbogbo rẹ̀ di funfun: mimọ́ li on. Ṣugbọn ni ijọ́ ti õju na ba hàn ninu rẹ̀, ki o jẹ́ alaimọ́. Ki alufa ki o wò õju na, ki o si pè e li alaimọ́: nitoripe aimọ́ li õju: ẹ̀tẹ ni. Tabi bi õju na ba yipada, ti o si di funfun, ki o si tọ̀ alufa wá, Alufa yio si wò o: si kiyesi i, bi àrun na ba di funfun, nigbana ni ki alufa ki o pè àlarun na ni mimọ́: mimọ́ li on.

Lef 13:1-17 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, “Nígbà tí ibìkan bá lé lára eniyan, tabi tí ara eniyan bá wú tí ọ̀gangan ibẹ̀ sì ń dán, tí ó bá jọ ẹ̀tẹ̀ ní ara rẹ̀, kí wọ́n mú olúwarẹ̀ tọ Aaroni, alufaa wá; tabi kí wọ́n mú un wá sí ọ̀dọ̀ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Aaroni, tí ó jẹ́ alufaa. Kí alufaa náà yẹ ọ̀gangan ibi tí àrùn náà wà lára ẹni náà wò. Bí irun ọ̀gangan ibẹ̀ bá di funfun, tí àrùn náà bá jẹ wọ inú ara ẹni náà lọ, tí ó jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. Nígbà tí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, kí ó pè é ní aláìmọ́. Ṣugbọn bí ọ̀gangan ibẹ̀ bá funfun tí kò sì jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, tí irun ọ̀gangan ibẹ̀ kò sì di funfun, kí alufaa ti abirùn náà mọ́lé fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ keje, alufaa náà yóo yẹ abirùn náà wò, bí àrùn náà kò bá tàn káàkiri ara rẹ̀, kí alufaa tún tì í mọ́lé fún ọjọ́ meje sí i. Nígbà tí ó bá tún di ọjọ́ keje, kí alufaa tún yẹ̀ ẹ́ wò. Bí ọ̀gangan ibi tí àrùn náà wà bá bẹ̀rẹ̀ sí wòdú, tí àrùn náà kò sì tàn káàkiri ara rẹ̀, kí alufaa pe ẹni náà ní mímọ́, ara rẹ̀ wú lásán ni; kí ó fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì di mímọ́. Ṣugbọn bí ibi tí ó wú náà bá bẹ̀rẹ̀ sí tàn káàkiri ní ara rẹ̀, lẹ́yìn tí ó fi ara rẹ̀ han alufaa fún ìwẹ̀nùmọ́, kí ó tún pada lọ fi ara han alufaa. Kí alufaa tún yẹ̀ ẹ́ wò, bí ibi tí ó wú náà bá tàn káàkiri sí i ní ara rẹ̀, kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. “Nígbà tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú ẹnìkan, kí wọ́n mú olúwarẹ̀ tọ alufaa lọ. Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ibìkan bá wú ní ara rẹ̀, tí ó funfun, tí ó sì sọ irun ọ̀gangan ibẹ̀ di funfun, bí ibi tí ó wú yìí bá di egbò, a jẹ́ pé àrùn ẹ̀tẹ̀ gan-an ni ó wà ní ara ẹni náà. Kí alufaa pè é ní aláìmọ́; kí ó má wulẹ̀ tì í mọ́lé, nítorí pé aláìmọ́ ni. Bí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá bo gbogbo ara eniyan láti orí dé àtẹ́lẹsẹ̀ níwọ̀n bí alufaa ti lérò pé ó lè mọ lára eniyan, nígbà náà kí alufaa yẹ olúwarẹ̀ wò, bí àrùn ẹ̀tẹ̀ yìí bá ti bo gbogbo ara rẹ̀ patapata, kí ó pè é ní mímọ́. Bí gbogbo ara rẹ̀ patapata bá ti di funfun, ó di mímọ́. Ṣugbọn gbàrà tí egbò kan bá ti hàn lára rẹ̀, ó di aláìmọ́. Kí alufaa yẹ ojú egbò náà wò, kí ó sì pe abirùn náà ní aláìmọ́, irú egbò yìí jẹ́ aláìmọ́ nítorí pé ẹ̀tẹ̀ ni. Ṣugbọn tí egbò yìí bá jiná, tí ojú rẹ̀ pada di funfun, kí ẹni náà pada tọ alufaa lọ. Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ojú egbò náà bá ti funfun, nígbà náà ni kí alufaa tó pe abirùn náà ní mímọ́, ó ti di mímọ́.

Lef 13:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

OLúWA sọ fún Mose àti Aaroni pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá ní ìwú, èélá tàbí àmì dídán kan ní ara rẹ̀, èyí tí ó le di ààrùn awọ ara tí ó le ràn ká. Ẹ gbọdọ̀ mú un tọ́ Aaroni àlùfáà lọ tàbí sí ọ̀dọ̀ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó jẹ́ àlùfáà. Àlùfáà náà ni ó gbọdọ̀ yẹ egbò ara rẹ̀ wò: bí irun egbò náà bá di funfun tí egbò náà sì dàbí i pé ó jinlẹ̀ kọjá awọ ara: èyí jẹ́ ààrùn ara tí ó le è ràn, bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò kí ó sọ ọ́ di mí mọ̀ pé aláìmọ́ ni ẹni náà. Bí àpá ara rẹ̀ bá funfun tí ó sì dàbí ẹni pé kò jinlẹ̀ jù awọ ara, tí irun rẹ̀ kò sì yípadà sí funfun kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje. Ní ọjọ́ keje ni kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí ó bá rí i pé egbò náà wà síbẹ̀ tí kò sì ràn ká àwọ̀ ara, kí ó tún fi pamọ́ fún ọjọ́ méje mìíràn. Ní ọjọ́ keje ni kí àlùfáà tún padà yẹ̀ ẹ́ wò, bí egbò náà bá ti san tí kò sì ràn ká awọ ara rẹ̀. Kí àlùfáà pè é ní mímọ́. Kí ọkùnrin náà fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì mọ́. Ṣùgbọ́n bí èélá náà bá ń ràn ká awọ ara rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó ti fi ara rẹ̀ han àlùfáà láti sọ pé ó ti mọ́. Ó tún gbọdọ̀ fi ara rẹ̀ hàn níwájú àlùfáà. Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí èélá náà bá ràn ká awọ ara rẹ̀, kí àlùfáà fihàn pé kò mọ́. Ààrùn ara tí ń ràn ni èyí. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ààrùn awọ ara tí ń ràn yìí ni kí a mú wá sọ́dọ̀ àlùfáà. Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí ìwú funfun kan bá wà lára rẹ̀, èyí tí ó ti sọ irun ibẹ̀ di funfun, tí a sì rí ojú egbò níbi ìwú náà. Ààrùn ara búburú gbá à ni èyí, kí àlùfáà jẹ́ kí ó di mí mọ̀ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò mọ́: kí ó má ṣe ya ẹni náà sọ́tọ̀ fún àyẹ̀wò torí pé aláìmọ́ ni ẹni náà jẹ́ tẹ́lẹ̀. “Bí ààrùn náà bá ràn yíká gbogbo awọ ara rẹ̀ tí àlùfáà sì yẹ̀ ẹ́ wò, tí ó rí i pé ààrùn náà ti gba gbogbo ara rẹ̀ láti orí títí dé ẹsẹ̀, àlùfáà yóò yẹ̀ ẹ́ wò, bí ààrùn náà bá ti ran gbogbo awọ ara rẹ̀, kí àlùfáà sọ pé ó di mímọ́, torí pé gbogbo ara ẹni náà ti di funfun, ó ti mọ́. Ṣùgbọ́n bí ẹran-ara rẹ̀ bá tún hàn jáde, òun yóò di àìmọ́. Bí àlùfáà bá ti rí ẹran-ara rẹ̀ kan kí ó pè é ni aláìmọ́. Ẹran-ara rẹ̀ di àìmọ́ torí pé ó ní ààrùn tí ń ràn. Bí ẹran-ara rẹ̀ bá yípadà sí funfun, kí o farahan àlùfáà. Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò: bí egbò rẹ̀ bá ti di funfun kí àlùfáà pe ẹni náà ni mímọ́. Òun yóò sì di mímọ́.