Lef 10:1-3
Lef 10:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
ATI Nadabu ati Abihu, awọn ọmọ Aaroni, olukuluku nwọn mú awo-turari rẹ̀, nwọn si fi iná sinu wọn, nwọn si fi turari sori wọn, nwọn si mú ajeji iná wá siwaju OLUWA, ti on kò fi aṣẹ fun wọn. Iná si ti ọdọ OLUWA jade, o si run wọn, nwọn si kú niwaju OLUWA. Nigbana ni Mose wi fun Aaroni pe, Eyiyi li OLUWA wipe, A o yà mi simimọ́ ninu awọn ti nsunmọ mi, ati niwaju awọn enia gbogbo li a o yìn mi li ogo. Aaroni si dakẹ.
Lef 10:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọmọ Aaroni meji kan, ọkunrin, tí wọn ń jẹ́ Nadabu ati Abihu, mú àwo turari wọn, olukuluku fọn ẹ̀yinná sinu tirẹ̀, wọ́n da turari lé e lórí, wọ́n sì fi rúbọ níwájú OLUWA, ṣugbọn iná yìí kì í ṣe irú iná mímọ́ tí OLUWA pa láṣẹ fún wọn. OLUWA bá rán iná kan jáde, iná náà jó wọn pa, wọ́n sì kú níwájú OLUWA. Mose bá pe Aaroni, ó wí fún un pé, “Ohun tí OLUWA wí nìyí, ‘N óo fi ara mi hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́ láàrin àwọn tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ mi, n óo sì gba ògo níwájú gbogbo àwọn eniyan’ ” Aaroni dákẹ́, kò sọ̀rọ̀.
Lef 10:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Nadabu àti Abihu tí í ṣe ọmọ Aaroni sì mú àwo tùràrí kọ̀ọ̀kan, wọ́n fi iná àti tùràrí sínú rẹ̀, wọ́n sì rú iná àjèjì níwájú OLúWA, èyí tó lòdì sí àṣẹ OLúWA. Torí èyí, iná jáde láti ọ̀dọ̀ OLúWA, ó sì jó wọn pa, wọ́n sì kú níwájú OLúWA. Mose sì sọ fún Aaroni pé, “Ohun tí OLúWA ń sọ nípa rẹ̀ nìyìí nígbà tó wí pé, “ ‘Ní àárín àwọn tó súnmọ́ mi, Èmi yóò fi ara mi hàn ní mímọ́ ojú gbogbo ènìyàn Ní a ó ti bu ọlá fún mi.’ ” Aaroni sì dákẹ́.