Ẹk. Jer 3:1-66
Ẹk. Jer 3:1-66 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI ni ọkunrin na ti o ti ri wàhala nipa ọpa ibinu rẹ̀. O ti fà mi, o si mu mi wá sinu òkunkun, kì si iṣe sinu imọlẹ. Lõtọ, o yi ọwọ rẹ̀ pada si mi siwaju ati siwaju li ọjọ gbogbo. O ti sọ ẹran-ara mi ati àwọ mi di ogbó, o ti fọ́ egungun mi. O ti mọdi tì mi, o fi orõrò ati ãrẹ̀ yi mi ka. O ti fi mi si ibi òkunkun, bi awọn ti o ti kú pẹ. O ti sọgba yi mi ka, ti emi kò le jade; o ti ṣe ẹ̀wọn mi wuwo. Bi emi ti kigbe pẹlu, ti emi si npariwo, o sé adura mi mọ. O ti fi okuta gbigbẹ sọgba yi ọ̀na mi ka, o ti yi ipa ọ̀na mi po. On jẹ bi ẹranko beari ti o ba dè mi, bi kiniun ni ibi ìkọkọ. O ti mu mi ṣina li ọ̀na mi, o si fà mi ya pẹrẹpẹrẹ: o ti sọ mi di ahoro. O ti fà ọrun rẹ̀, o si fi mi ṣe itasi fun ọfa rẹ̀. O ti mu ki ọfà apó rẹ̀ wọ inu-ẹdọ mi lọ. Emi jẹ ẹni ẹsin fun gbogbo enia mi; orin wọn ni gbogbo ọjọ. O ti fi ìkoro mu mi yo, o ti mu mi mu omi wahala. O ti fi ọta ṣẹ́ ehín mi, o tẹ̀ mi mọlẹ ninu ẽru. Iwọ si ti mu ọkàn mi jina réré si alafia; emi gbagbe rere. Emi si wipe, Agbara mi ati ireti mi ṣègbe kuro lọdọ Oluwa. Ranti wahala mi ati inilara mi, ani ìkoro ati orõro. Lõtọ, nigbati ọkàn mi nṣe iranti wọn, o si tẹriba ninu mi. Eyi ni emi o rò li ọkàn mi, nitorina emi o ma reti. Ãnu Oluwa ni, ti awa kò parun tan, nitori irọnu-ãnu rẹ kò li opin. Ọtun ni li orowurọ; titobi ni otitọ rẹ. Oluwa ni ipin mi, bẹ̃li ọkàn mi wi; nitorina ni emi ṣe reti ninu rẹ̀. Oluwa ṣe rere fun gbogbo ẹniti o duro dè e, fun ọkàn ti o ṣafẹri rẹ̀. O dara ti a ba mã reti ni idakẹjẹ fun igbala Oluwa. O dara fun ọkunrin, ki o gbe àjaga ni igba-ewe rẹ̀. Ki o joko on nikan, ki o si dakẹ, nitori Ọlọrun ti gbe e le ori rẹ̀. Ki o fi ẹnu rẹ̀ sinu ẽkuru; pe bọya ireti le wà: Ki o fi ẹ̀rẹkẹ fun ẹniti o lù u; ki o kún fun ẹ̀gan patapata. Nitoriti Oluwa kì yio ṣá ni tì lailai: Bi o tilẹ mu ibanujẹ wá, sibẹ on o ni irọnu gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀. Nitori on kì ifẹ ipọn-ni-loju lati ọkàn rẹ̀ wá, bẹ̃ni kì ibà ọmọ enia ninu jẹ. Lati tẹ̀ gbogbo ara-tubu ilẹ-aiye mọlẹ li abẹ ẹsẹ rẹ̀. Lati yi ẹ̀tọ enia sapakan niwaju Ọga-ogo julọ. Lati yi ọ̀ran idajọ enia pada, Oluwa kò fẹ ri i? Tali ẹniti iwi, ti isi iṣẹ, nigbati Oluwa kò paṣẹ rẹ̀. Ibi ati rere kò ha njade lati ẹnu Ọga-ogo-julọ wá? Ẽṣe ti enia alãye nkùn? ti o wà lãye, ki olukuluku ki o kùn nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀! Jẹ ki a wádi, ki a si dán ọ̀na wa wò, ki a si tun yipada si Oluwa. Jẹ ki a gbe ọkàn ati ọwọ wa soke si Ọlọrun li ọrun. Awa ti dẹṣẹ, a si ti ṣọtẹ: iwọ kò ti dariji. Iwọ ti fi ibinu bora, o si ṣe inunibini si wa: iwọ ti pa, o kò si ti dasi. Iwọ ti fi awọsanma bo ara rẹ, ki adura má le là kọja. Iwọ ti ṣe wa bi idarọ ati ohun alainilãri li ãrin awọn orilẹ-ède. Gbogbo awọn ọta wa ti ya ẹnu wọn si wa. Ẹ̀ru ati ọ̀fin wá sori wa, idahoro ati iparun. Oju mi fi odò omi ṣan silẹ, nitori iparun ọmọbinrin awọn enia mi. Oju mi dà silẹ ni omije, kò si dá, laiṣe isimi. Titi Oluwa fi wò ilẹ, ti o wò lati ọrun wá, Oju mi npọn ọkàn mi loju, nitori gbogbo awọn ọmọbinrin ilu mi. Awọn ọta mi dẹkùn fun mi gidigidi, gẹgẹ bi fun ẹiyẹ laini idi. Nwọn ti ke ẹmi mi kuro ninu iho, nwọn si yi okuta sori mi. Nwọn mu omi ṣan lori mi; emi wipe, Mo gbe! Emi kepe orukọ rẹ, Oluwa, lati iho jijin wá. Iwọ ti gbọ́ ohùn mi: máṣe se eti rẹ mọ si imikanlẹ mi, si igbe mi. Iwọ sunmọ itosi li ọjọ ti emi kigbe pè ọ: iwọ wipe: Má bẹ̀ru! Oluwa, iwọ ti gba ijà mi jà; iwọ ti rà ẹmi mi pada. Oluwa, iwọ ti ri inilara mi, ṣe idajọ ọran mi! Iwọ ti ri gbogbo igbẹsan wọn, gbogbo èro buburu wọn si mi. Iwọ ti gbọ́ ẹ̀gan wọn, Oluwa, gbogbo èro buburu wọn si mi. Ète awọn wọnni ti o dide si mi, ati ipinnu wọn si mi ni gbogbo ọjọ. Kiyesi ijoko wọn ati idide wọn! emi ni orin-ẹsin wọn. San ẹsan fun wọn, Oluwa, gẹgẹ bi iṣẹ ọwọ wọn! Fun wọn ni ifọju ọkàn, ègun rẹ lori wọn! Fi ibinu lepa wọn, ki o si pa wọn run kuro labẹ ọrun Oluwa!
Ẹk. Jer 3:1-66 Yoruba Bible (YCE)
Èmi ni mo mọ bí eniyan tií rí ìpọ́njú, tí mo mọ bí Ọlọrun tií fi ibinu na eniyan ní pàṣán. Ó lé mi wọ inú òkùnkùn biribiri. Dájúdájú, ó ti dojú kọ mí, ó sì bá mi jà léraléra tọ̀sán-tòru. Ó ti jẹ́ kí n rù kan egungun, ó sì ti fọ́ egungun mi. Ó dótì mí, ó fi ìbànújẹ́ ati ìṣẹ́ yí mi káàkiri. Ó fi mí sinu òkùnkùn bí òkú tí ó ti kú láti ọjọ́ pípẹ́. Ó mọ odi yí mi ká, ó sì fi ẹ̀wọ̀n wúwo dè mí, kí n má baà lè sálọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ké pè é fún ìrànlọ́wọ́, sibẹsibẹ kò gbọ́ adura mi. Ó to òkúta gbígbẹ́ dí ọ̀nà mi, ó mú kí ọ̀nà mí wọ́. Ó ba dè mí bí ẹranko ìjàkùmọ̀, ó lúgọ bíi kinniun, Ó wọ́ mi kúrò lójú ọ̀nà mi, ó fà mí ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ó sì ti sọ mí di alailẹnikan. Ó kẹ́ ọfà, ó fa ọrun rẹ̀, ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí. Ó mú gbogbo ọfà tí ó wà ninu apó rẹ̀ ó ta wọ́n mọ́ mi lọ́kàn. Mo wá di ẹni yẹ̀yẹ́ lọ́dọ̀ gbogbo eniyan, ẹni tí wọ́n fi ń kọrin tọ̀sán-tòru. Ó mú kí ọkàn mi kún fún ìbànújẹ́, ó fún mi ní iwọ mu ní àmuyó. Ó fẹnu mi gbolẹ̀, títí yangí fi ká mi léyín; ó gún mi mọ́lẹ̀ ninu eruku Ọkàn mi kò ní alaafia, mo ti gbàgbé ohun tí ń jẹ́ ayọ̀. Nítorí náà, mo wí pé, “Ògo mi ti tán, ati gbogbo ohun tí mò ń retí lọ́dọ̀ OLUWA.” Ranti ìyà ati ìbànújẹ́ mi, ati ìrora ọkàn mi! Mò ń ranti nígbà gbogbo, ọkàn mi sì ń rẹ̀wẹ̀sì. Ṣugbọn mo tún ń ranti nǹkankan, mo sì ní ìrètí. Nítorí pé Ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀ kò nípẹ̀kun, àánú rẹ̀ kò sì lópin; ọ̀tun ni wọ́n láràárọ̀, òtítọ́ rẹ̀ pọ̀. Ọkàn mi wí pé, “OLUWA ni ìpín mi, nítorí náà lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi wà.” OLUWA a máa ṣe oore fún àwọn tí wọn dúró dè é, tí wọn sì ń wá ojurere rẹ̀. Ó dára kí eniyan dúró jẹ́ẹ́, de ìgbàlà OLUWA. Ó dára kí eniyan foríti àjàgà ìtọ́sọ́nà ní ìgbà èwe. Kí ó fi ọwọ́ lẹ́rán, kí ó dákẹ́, kí ó sì máa wòye, nítorí Ọlọrun ni ó gbé àjàgà náà kọ́ ọ lọ́rùn. Kí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, bóyá ìrètí lè tún wà fún un. Kí ó kọ etí rẹ̀ sí ẹni tí ó fẹ́ gbá a létí, kí wọ́n sì fi àbùkù kàn án. Nítorí OLUWA kò ní ta wá nù títí lae. Bí ó tilẹ̀ mú kí ìbànújẹ́ dé bá wa, yóo ṣàánú wa, yóo tù wá ninu, gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Nítorí pé kì í kàn déédé ni eniyan lára tabi kí ó mú ìbànújẹ́ dé bá eniyan láìní ìdí. OLUWA kò faramọ́ pé kí á máa ni àwọn ẹlẹ́wọ̀n lára lórí ilẹ̀ ayé, kí á máa já ẹ̀tọ́ olódodo gbà lọ́wọ́ rẹ̀ níwájú Ọ̀gá Ògo, tabi kí á du eniyan ní ìdájọ́ òdodo. Ta ló pàṣẹ nǹkankan rí tí ó sì rí bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé OLUWA ló fi ọwọ́ sí i? Àbí kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá Ògo ni rere ati burúkú ti ń jáde? Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè kan yóo fi máa ráhùn nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀? Ẹ jẹ́ kí á yẹ ara wa wò, kí á tún ọ̀nà wa ṣe, kí á sì yipada sí ọ̀dọ̀ OLUWA. Ẹ jẹ́ kí á gbé ojú wa sókè, kí á ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọrun ọ̀run: “A ti ṣẹ̀, a sì ti ṣoríkunkun, ìwọ OLUWA kò sì tíì dáríjì wá. “O gbé ibinu wọ̀ bí ẹ̀wù, ò ń lépa wa, o sì ń pa wá láì ṣàánú wa. O ti fi ìkùukùu bo ara rẹ, tóbẹ́ẹ̀ tí adura kankan kò lè kọjá sọ́dọ̀ rẹ. O ti sọ wá di ààtàn ati ohun ẹ̀gbin láàrin àwọn eniyan. “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ń wẹnu sí wa lára. Ẹ̀rù ati ìṣubú, ìsọdahoro ati ìparun ti dé bá wa. Omijé ń dà pòròpòrò lójú mi, nítorí ìparun àwọn eniyan mi. “Omijé yóo máa dà pòròpòrò lójú mi láì dáwọ́ dúró, ati láìsinmi. Títí OLUWA yóo fi bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run wá, tí yóo sì rí wa. Ìbànújẹ́ bá mi, nígbà tí mo rí ibi tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọbinrin ìlú mi. “Àwọn tí ń bá mi ṣọ̀tá láìnídìí ń dọdẹ mi bí ìgbà tí eniyan ń dọdẹ ẹyẹ. Wọ́n jù mí sinu ihò láàyè, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ òkúta lù mí mọ́lẹ̀. Omi bò mí mọ́lẹ̀, mo ní, ‘Mo ti gbé.’ “Mo ké pe orúkọ rẹ, OLUWA, láti inú kòtò jíjìn. O gbọ́ ẹ̀bẹ̀ tí mò ń bẹ̀ pé, ‘Má ṣe di etí rẹ sí igbe tí mò ń ké fún ìrànlọ́wọ́.’ O súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi nígbà tí mo pè ọ́, o dá mi lóhùn pé, ‘Má bẹ̀rù.’ “OLUWA, o ti gba ìjà mi jà, o ti ra ẹ̀mí mi pada. O ti rí nǹkan burúkú tí wọ́n ṣe sí mi, OLUWA, dá mi láre. O ti rí gbogbo ìgbẹ̀san wọn, ati gbogbo ète wọn lórí mi. “O ti gbọ́ bí wọn tí ń pẹ̀gàn mi, OLUWA, ati gbogbo ète wọn lórí mi. Gbogbo ọ̀rọ̀ ati èrò àwọn ọ̀tá mi sí mi: ibi ni lojoojumọ. Kíyèsí i, wọn ìbáà jókòó, wọn ìbáà dìde dúró, èmi ni wọ́n máa fi ń kọrin. “O óo san ẹ̀san fún wọn, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Jẹ́ kí ojú inú wọn fọ́, kí ègún rẹ sì wà lórí wọn. Fi ibinu lépa wọn, OLUWA, sì pa wọ́n run láyé yìí.”
Ẹk. Jer 3:1-66 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi ni ọkùnrin tí ó rí ìpọ́njú pẹ̀lú ọ̀pá ìbínú rẹ. Ó ti lé mi jáde ó sì mú mi rìn nínú òkùnkùn ju ti ìmọ́lẹ̀; Nítòótọ́, ó ti yí ọwọ́ padà sí mi síwájú àti síwájú sí i ní gbogbo ọjọ́. Ó jẹ́ kí àwọ̀ mi àti ẹran-ara mi gbó ó sì tún ṣẹ́ egungun mi. Ó ti fi mí sí ìgbèkùn, ó sì ti yí mi ká pẹ̀lú ìkorò àti làálàá. Ó mú mi gbé nínú òkùnkùn, bí ti àwọn tó ti kú fún ìgbà pípẹ́. Ó ti tì mí mọ́ ilé, nítorí náà n kò le è sálọ; ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀. Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́, ó kọ àdúrà mi. Ó fi ògiri òkúta dí ọ̀nà mi; ó sì mú ọ̀nà mi wọ́. Bí i beari tí ó dùbúlẹ̀, bí i kìnnìún tí ó sápamọ́. Ó wọ́ mi kúrò ní ọ̀nà, ó tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ ó fi mi sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́. Ó fa ọfà rẹ̀ yọ ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí. Ó fa ọkàn mí ya pẹ̀lú ọfà nínú àkọ̀ rẹ̀. Mo di ẹni yẹ̀yẹ́ láàrín àwọn ènìyàn mi; wọn yẹ̀yẹ́ mi pẹ̀lú orin ní gbogbo ọjọ́. Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkorò àti ìdààmú bí omi. Ó ti fi òkúta kán eyín mi; ó ti tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ nínú eruku. Mo ti jìnnà sí àlàáfíà; mo ti gbàgbé ohun tí àṣeyege ń ṣe. Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọ àti ìrètí mi nínú OLúWA.” Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi, ìkorò àti ìbànújẹ́. Mo ṣèrántí wọn, ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi. Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn àti nítorí náà ní mo nírètí. Nítorí ìfẹ́ OLúWA tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé, nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà. Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀; títóbi ni òdodo rẹ̀. Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni OLúWA; nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́. Dídára ni OLúWA fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀, sí àwọn tí ó ń wá a. Ó dára kí a ní sùúrù fún ìgbàlà OLúWA. Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgà nígbà tí ó wà ní èwe. Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, nítorí OLúWA ti fi fún un. Jẹ́ kí ó bo ojú rẹ̀ sínú eruku— ìrètí sì lè wà. Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a, sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì. Ènìyàn kò di ìtanù lọ́dọ̀ Olúwa títí láé. Lóòtítọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn, nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀. Nítorí kò mọ̀ ọ́n mọ̀ mú ìpọ́njú wá tàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn. Láti tẹ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ilẹ̀ náà. Láti ṣẹ́ ọmọ ènìyàn fún ẹ̀tọ́ rẹ̀ níwájú Ọ̀gá-ògo jùlọ. Láti yí ìdájọ́ ènìyàn padà, Ǹjẹ́ Olúwa kò rí ohun bẹ́ẹ̀. Ta ni yóò sọ̀rọ̀ tí yóò rí bẹ́ẹ̀ tí Olúwa kò bá fi àṣẹ sí i. Ǹjẹ́ kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá-ògo jùlọ ni rere àti búburú tí ń wá? Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè ṣe ń kùn nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀? Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀nà wa, kí a sì dán an wò, kí a sì tọ OLúWA lọ. Ẹ jẹ́ kí a gbé ọkàn àti ọwọ́ wa sókè sí Ọlọ́run ní ọ̀run, kí a wí pé: “Àwa ti ṣẹ̀ a sì ti ṣọ̀tẹ̀ ìwọ kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. “Ìwọ fi ìbínú bo ara rẹ ìwọ sì ń lépa wa; ìwọ ń parun láìsí àánú. Ìwọ ti fi àwọsánmọ̀ bo ara rẹ pé kí àdúrà wa má ba à dé ọ̀dọ̀ rẹ. Ó ti sọ wá di èérí àti ààtàn láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo. “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọn gbòòrò sí wa. Àwa ti jìyà àti ìparun, nínú ìbẹ̀rù àti ewu.” Omijé ń sàn ní ojú mi bí odò nítorí a pa àwọn ènìyàn mi run. Ojú mi kò dá fún omijé, láì sinmi, títí ìgbà tí OLúWA yóò ṣíjú wolẹ̀ láti òkè ọ̀run tí yóò sì rí i. Ohun tí mo rí mú ìbẹ̀rù wá ọkàn mi nítorí gbogbo àwọn obìnrin ìlú mi. Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí dẹ mí bí ẹyẹ. Wọ́n gbìyànjú láti mú òpin dé bá ayé mi nínú ihò wọ́n sì ju òkúta lù mí. Orí mi kún fún omi, mo sì rò pé ìgbẹ̀yìn dé. Mo pe orúkọ rẹ, OLúWA, láti ọ̀gbun ìsàlẹ̀ ihò. Ìwọ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi: “Má ṣe di etí rẹ sí igbe ẹ̀bẹ̀ mi fún ìtura.” O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́, o sì wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù.” OLúWA, ìwọ gba ẹjọ́ mi rò, o ra ẹ̀mí mi padà. O ti rí i, OLúWA, búburú tí a ṣe sí mi Gbé ẹjọ́ mi ró! Ìwọ ti rí ọ̀gbun ẹ̀san wọn, gbogbo ìmọ̀ wọn sí mi. OLúWA ìwọ ti gbọ́ ẹ̀gàn wọn àti ìmọ̀ búburú wọn sí mi— Ohun tí àwọn ọ̀tá mi ń sọ sí mi ní gbogbo ọjọ́. Wò wọ́n! Ní jíjòkòó tàbí ní dídìde, wọ́n ń ṣẹlẹ́yà mi nínú orin wọn. OLúWA san wọ́n lẹ́san ohun tí ó tọ́ sí wọn fún ohun tí ọwọ́ wọn ti ṣe. Fi ìbòjú bò wọ́n ní ọkàn, kí o sì fi wọ́n ré. Ni wọ́n lára kí o sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìbínú, lábẹ́ ọ̀run OLúWA.