Jud 1:5-7
Jud 1:5-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ emi nfẹ lati rán nyin leti bi ẹnyin tilẹ ti mọ̀ gbogbo rẹ̀ lẹ̃kan ri, pe Oluwa, nigbati o ti gbà awọn enia kan là lati ilẹ Egipti wá, lẹhinna o run awọn ti kò gbagbọ́. Ati awọn angẹli ti kò tọju ipò ọla wọn ṣugbọn ti nwọn fi ipò wọn silẹ, awọn ni o pamọ́ ninu ẹ̀wọn ainipẹkun nisalẹ òkunkun de idajọ ọjọ nla nì. Ani bi Sodomu ati Gomorra, ati awọn ilu agbegbe wọn, ti fi ara wọn fun àgbere iṣe bakanna, ti nwọn si ntẹle ara ajeji lẹhin, awọn li a fi lelẹ bi apẹrẹ, nwọn njìya iná ainipẹkun.
Jud 1:5-7 Yoruba Bible (YCE)
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti mọ gbogbo nǹkan wọnyi, sibẹ mo fẹ́ ran yín létí pé lẹ́yìn tí Oluwa ti gba àwọn eniyan là kúrò ní ilẹ̀ Ijipti tán, nígbà tí ó yá, ó tún pa àwọn tí kò gbàgbọ́ run. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn angẹli tí wọn kọjá ààyè wọn àkọ́kọ́, tí wọ́n kúrò ní ipò tí Ọlọrun kọ́ fi wọ́n sí. Ẹ̀wọ̀n ayérayé ni Ọlọrun fi dè wọ́n mọ́ inú òkùnkùn biribiri títí di ọjọ́ ńlá nnì tíí ṣe ọjọ́ ìdájọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìlú Sodomu ati ìlú Gomora ati àwọn ìlú tí ó yí wọn ká. Àwọn náà ṣe bí àwọn angẹli tí wọ́n kọjá ààyè wọn, wọ́n ṣe àgbèrè ati oríṣìíríṣìí ohun ìbàjẹ́ tí kò bá ìwà eniyan mu. Ọlọrun fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ fún gbogbo eniyan nígbà tí wọ́n jìyà iná ajónirun.
Jud 1:5-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítòótọ́, ẹ ti mọ nǹkan wọ̀nyí ní ẹ̀ẹ̀kan rí, mo fẹ́ rán an yín létí pé, lẹ́yìn tí Olúwa ti gba àwọn kan là láti ilẹ̀ Ejibiti wá, lẹ́yìn náà ni ó run àwọn tí kò gbàgbọ́. Àti àwọn angẹli tí kò tọ́jú ipò ọlá wọn, ṣùgbọ́n tí wọn fi ipò wọn sílẹ̀, àwọn tí ó pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n àìnípẹ̀kun ní ìsàlẹ̀ òkùnkùn de ìdájọ́ ọjọ́ ńlá nì. Àní bí Sodomu àti Gomorra, àti àwọn ìlú agbègbè wọn, ti fi ara wọn fún àgbèrè ṣíṣe, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé ará àjèjì lẹ́yìn, àwọn ni ó fi lélẹ̀ bí àpẹẹrẹ, àwọn tí ó ń jìyà iná àìnípẹ̀kun.