Jud 1:5-11

Jud 1:5-11 Yoruba Bible (YCE)

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti mọ gbogbo nǹkan wọnyi, sibẹ mo fẹ́ ran yín létí pé lẹ́yìn tí Oluwa ti gba àwọn eniyan là kúrò ní ilẹ̀ Ijipti tán, nígbà tí ó yá, ó tún pa àwọn tí kò gbàgbọ́ run. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn angẹli tí wọn kọjá ààyè wọn àkọ́kọ́, tí wọ́n kúrò ní ipò tí Ọlọrun kọ́ fi wọ́n sí. Ẹ̀wọ̀n ayérayé ni Ọlọrun fi dè wọ́n mọ́ inú òkùnkùn biribiri títí di ọjọ́ ńlá nnì tíí ṣe ọjọ́ ìdájọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìlú Sodomu ati ìlú Gomora ati àwọn ìlú tí ó yí wọn ká. Àwọn náà ṣe bí àwọn angẹli tí wọ́n kọjá ààyè wọn, wọ́n ṣe àgbèrè ati oríṣìíríṣìí ohun ìbàjẹ́ tí kò bá ìwà eniyan mu. Ọlọrun fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ fún gbogbo eniyan nígbà tí wọ́n jìyà iná ajónirun. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí fún àwọn eniyan wọnyi lónìí. Àlá tí wọn ń lá, fún ìbàjẹ́ ara wọn ni. Wọ́n tàpá sí àwọn aláṣẹ. Wọ́n ń sọ ìsọkúsọ sí àwọn ẹ̀dá ọ̀run tí ó lógo. Nígbà tí Mikaeli, olórí àwọn angẹli pàápàá ń bá Èṣù jiyàn, tí wọ́n ń jìjàdù òkú Mose, kò tó sọ ìsọkúsọ sí i. Ohun tí ó sọ ni pé, “Oluwa yóo bá ọ wí.” Ṣugbọn àwọn eniyan wọnyi a máa sọ ìsọkúsọ nípa ohunkohun tí kò bá ti yé wọn. Àwọn nǹkan tí ó bá sì yé wọn, bí nǹkan tíí yé ẹranko ni. Ohun tí ń mú ìparun bá wọn nìyí. Ó ṣe fún wọn! Wọ́n ń rìn ní ọ̀nà Kaini. Wọ́n tẹra mọ́ ọ̀nà ẹ̀tàn Balaamu nítorí ohun tí wọn yóo rí gbà. Wọ́n dá ọ̀tẹ̀ sílẹ̀ bíi Kora, wọ́n sì parun.

Jud 1:5-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítòótọ́, ẹ ti mọ nǹkan wọ̀nyí ní ẹ̀ẹ̀kan rí, mo fẹ́ rán an yín létí pé, lẹ́yìn tí Olúwa ti gba àwọn kan là láti ilẹ̀ Ejibiti wá, lẹ́yìn náà ni ó run àwọn tí kò gbàgbọ́. Àti àwọn angẹli tí kò tọ́jú ipò ọlá wọn, ṣùgbọ́n tí wọn fi ipò wọn sílẹ̀, àwọn tí ó pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n àìnípẹ̀kun ní ìsàlẹ̀ òkùnkùn de ìdájọ́ ọjọ́ ńlá nì. Àní bí Sodomu àti Gomorra, àti àwọn ìlú agbègbè wọn, ti fi ara wọn fún àgbèrè ṣíṣe, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé ará àjèjì lẹ́yìn, àwọn ni ó fi lélẹ̀ bí àpẹẹrẹ, àwọn tí ó ń jìyà iná àìnípẹ̀kun. Bákan náà ni àwọn wọ̀nyí ń sọ ara wọn di èérí nínú àlá wọn, wọ́n ń gan ìjòyè, wọn sì ń sọ̀rọ̀ búburú sí àwọn ọlọ́lá. Ṣùgbọ́n Mikaeli, olórí àwọn angẹli, nígbà tí ó ń bá Èṣù jiyàn nítorí òkú Mose, kò sọ ọ̀rọ̀-òdì sí i; Ṣùgbọ́n ó wí pé, “Olúwa bá ọ wí.” Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí n sọ̀rọ̀-òdì sí ohun gbogbo ti kò yé wọn: ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí wọn mọ̀ nípa èrò ara ni, bí ẹranko tí kò ní ìyè, nípasẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n di ẹni ìparun. Ègbé ni fún wọn! Nítorí tí wọ́n ti rìn ní ọ̀nà Kaini, wọ́n sì fi ìwọra súré sínú ìṣìnà Balaamu nítorí ère, wọn ṣègbé nínú ìṣọ̀tẹ̀ Kora.