Jud 1:17-23
Jud 1:17-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ẹnyin olufẹ, ẹ ranti awọn ọ̀rọ ti a ti sọ ṣaju lati ọwọ́ awọn Aposteli Oluwa wa Jesu Kristi; Bi nwọn ti wi fun nyin pe, awọn ẹlẹgàn yio wà nigba ikẹhin, ti nwọn o mã rìn gẹgẹ bi ifẹkufẹ aiwa-bi-Ọlọrun ti ara wọn. Awọn wọnyi ni awọn ẹniti nya ara wọn si ọtọ, awọn ẹni ti ara, ti nwọn kò ni Ẹmí. Ṣugbọn ẹnyin, olufẹ, ti ẹ ngbe ara nyin ró lori ìgbagbọ́ nyin ti o mọ́ julọ, ti ẹ ngbadura ninu Ẹmí Mimọ́, Ẹ mã pa ara nyin mọ́ ninu ifẹ Ọlọrun, ẹ mã reti ãnu Oluwa wa Jesu Kristi titi di iye ainipẹkun. Ẹ mã ṣãnu awọn ẹlomiran, ẹ mã fi ìyatọ han: Ẹ mã fi ẹ̀ru gba awọn ẹlomiran là, ẹ mã fà wọn yọ kuro ninu iná; ẹ tilẹ mã korira ẹ̀wu tí ara ti sọ di ẽri.
Jud 1:17-23 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, ẹ̀yin ẹ ranti ohun tí Oluwa wa Jesu Kristi ti ti ẹnu àwọn aposteli rẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀. Wọ́n kìlọ̀ fun yín pé ní àkókò ìkẹyìn, àwọn kan yóo máa fi ẹ̀sìn ṣe ẹlẹ́yà, wọn yóo máa tẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn láì bẹ̀rù Ọlọrun. Àwọn wọnyi ni wọ́n ń ya ara wọn sọ́tọ̀. Wọ́n hùwà bí ẹranko, wọn kò ní Ẹ̀mí Mímọ́. Ṣugbọn ẹ̀yin, àyànfẹ́ mi, ẹ fi igbagbọ yín tí ó mọ́ jùlọ ṣe odi fún ara yín, kí ẹ máa gbadura nípa agbára tí ó wà ninu Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ pa ara yín mọ́ ninu ìfẹ́ Ọlọrun. Ẹ máa retí ìyè ainipẹkun tí Oluwa wa Jesu Kristi yóo fun yín ninu àánú rẹ̀. Ẹ máa ṣàánú àwọn tí ó ń ṣiyèméjì. Inú iná ni ẹ ti níláti yọ àwọn mìíràn kí ẹ tó lè gbà wọ́n là. Ìbẹ̀rù-bojo ni kí ẹ fi máa ṣàánú àwọn mìíràn. Ẹ níláti kórìíra aṣọ tí ìfẹ́ ara ti da àbààwọ́n sí.
Jud 1:17-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin olùfẹ́, ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti sọ ṣáájú láti ọwọ́ àwọn aposteli Olúwa wa Jesu Kristi. Bí wọn ti wí fún yín pé, “Nígbà ìkẹyìn àwọn ẹlẹ́gàn yóò wà, tí wọn yóò máa rìn gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run ti ara wọn.” Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni àwọn ẹni tí ń ya ara wọn sí ọ̀tọ̀, àwọn ẹni ti ara, tí wọn kò ni Ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, olùfẹ́, ti ẹ ń gbé ara yín ró lórí ìgbàgbọ́ yín tí ó mọ́ jùlọ, ti ẹ ń gbàdúrà nínú Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ máa pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, bí ẹ̀yin ti ń retí àánú Olúwa wa Jesu Kristi tí yóò mú yín dé ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ máa ṣàánú fún àwọn tí ń ṣe iyèméjì. Ẹ máa gba àwọn ẹlòmíràn là, nípa fífà wọ́n yọ kúrò nínú iná; kí ẹ sì máa ṣàánú pẹ̀lú ìbẹ̀rù kí ẹ sì kórìíra ẹ̀wù tí ara ti sọ di èérí.