Jud 1:14-16
Jud 1:14-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn wọnyi pẹlu ni Enoku, ẹni keje lati ọdọ Adamu, sọtẹlẹ fun, wipe Kiyesi i, Oluwa mbọ̀ pẹlu ẹgbẹgbãrun awọn enia rẹ̀ mimọ́, Lati ṣe idajọ gbogbo enia, lati dá gbogbo awọn alaiwa-bi-Ọlorun lẹbi niti gbogbo iṣe aiwa-bi-Ọlorun wọn, ti nwọn ti fi aiwa-bi-Ọlorun ṣe, ati niti gbogbo ọ̀rọ lile ti awọn ẹlẹṣẹ aiwa-bi-Ọlọrun ti sọ si i. Awọn wọnyi li awọn ti nkùn, awọn alaroye, ti nrìn nipa ifẹkufẹ ara wọn; ẹnu wọn a mã sọ ọ̀rọ ìhalẹ, nwọn a mã ṣojuṣãjú nitori ere.
Jud 1:14-16 Yoruba Bible (YCE)
Nípa àwọn wọnyi ni Enọku tí ó jẹ́ ìran keje sí Adamu sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé, “Mo rí Oluwa tí ó dé pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun àwọn angẹli rẹ̀ mímọ́, láti ṣe ìdájọ́ lórí gbogbo ẹ̀dá. Yóo bá gbogbo àwọn eniyan burúkú wí fún gbogbo ìwà burúkú tí wọ́n ti hù, ati gbogbo ọ̀rọ̀ líle tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò bẹ̀rù Ọlọrun ti sọ sí òun Oluwa.” Àwọn wọnyi ni àwọn tí wọn ń kùn ṣá, nǹkan kì í fi ìgbà kan tẹ́ wọn lọ́rùn. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn ni wọ́n ń lépa. Ẹnu wọn gba ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà. Kò sí ohun tí wọn kò lè ṣe láti rí ohun tí wọ́n fẹ́. Wọn á máa wá ojú rere àwọn tí wọ́n bá lè rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn.
Jud 1:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ni Enoku, ẹni keje láti ọ̀dọ̀ Adamu, sọtẹ́lẹ̀ nípa wọn pé “Kíyèsi i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn rẹ̀ mímọ́, láti ṣe ìdájọ́ gbogbo ènìyàn, láti dá gbogbo àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run lẹ́bi ní ti gbogbo iṣẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run wọn, ti wọ́n ti fi àìwà-bí-Ọlọ́run ṣe, àti ní ti gbogbo ọ̀rọ̀ líle tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìwà-bí-Ọlọ́run ti sọ sí i.” Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní àwọn ti ń kùn, àwọn aláròyé, ti ń rìn nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn; wọn ń gbéraga nípa ara wọn, wọ́n sì ń ṣátá àwọn ènìyàn mìíràn fún èrè ara wọn.