Jud 1:11-16

Jud 1:11-16 Yoruba Bible (YCE)

Ó ṣe fún wọn! Wọ́n ń rìn ní ọ̀nà Kaini. Wọ́n tẹra mọ́ ọ̀nà ẹ̀tàn Balaamu nítorí ohun tí wọn yóo rí gbà. Wọ́n dá ọ̀tẹ̀ sílẹ̀ bíi Kora, wọ́n sì parun. Bàsèjẹ́ ni wọ́n jẹ́ ninu àsè ìfẹ́ ìjọ, wọn kò ní ọ̀wọ̀ nígbà tí ẹ bá jọ ń jẹ, tí ẹ jọ ń mu. Ara wọn nìkan ni wọ́n ń tọ́jú bí olùṣọ́-aguntan tí ń tọ́jú ara rẹ̀ dípò aguntan. Wọ́n dàbí ìkùukùu tí afẹ́fẹ́ ń gbá kiri tí kò rọ òjò. Igi tí kò ní èso ní àkókò ìkórè ni wọ́n, wọ́n ti kú sára. Nígbà tí ó bá ṣe, wọn á wó lulẹ̀ tigbòǹgbò-tigbòǹgbò. Ìgbì omi òkun líle ni wọ́n, tí ó ń rú ìwà ìtìjú wọn jáde. Ìràwọ̀ tí kò gbébìkan ni wọ́n. Ààyè wọn ti wà nílẹ̀ fún wọn, ninu òkùnkùn biribiri títí ayé ainipẹkun. Nípa àwọn wọnyi ni Enọku tí ó jẹ́ ìran keje sí Adamu sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé, “Mo rí Oluwa tí ó dé pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun àwọn angẹli rẹ̀ mímọ́, láti ṣe ìdájọ́ lórí gbogbo ẹ̀dá. Yóo bá gbogbo àwọn eniyan burúkú wí fún gbogbo ìwà burúkú tí wọ́n ti hù, ati gbogbo ọ̀rọ̀ líle tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò bẹ̀rù Ọlọrun ti sọ sí òun Oluwa.” Àwọn wọnyi ni àwọn tí wọn ń kùn ṣá, nǹkan kì í fi ìgbà kan tẹ́ wọn lọ́rùn. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn ni wọ́n ń lépa. Ẹnu wọn gba ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà. Kò sí ohun tí wọn kò lè ṣe láti rí ohun tí wọ́n fẹ́. Wọn á máa wá ojú rere àwọn tí wọ́n bá lè rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn.

Jud 1:11-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ègbé ni fún wọn! Nítorí tí wọ́n ti rìn ní ọ̀nà Kaini, wọ́n sì fi ìwọra súré sínú ìṣìnà Balaamu nítorí ère, wọn ṣègbé nínú ìṣọ̀tẹ̀ Kora. Àwọn wọ̀nyí ní ó jẹ́ àbàwọ́n nínú àsè ìfẹ́ yín, nígbà tí wọ́n ń bá yín jẹ àsè, àwọn olùṣọ́-àgùntàn ti ń bọ́ ara wọn láìbẹ̀rù. Wọ́n jẹ́ ìkùùkuu láìrọ òjò, tí a ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ gbá kiri; àwọn igi aláìléso ní àkókò èso, wọ́n kú lẹ́ẹ̀méjì, a sì fà wọ́n tú tigbòǹgbò tigbòǹgbò. Wọ́n jẹ́ ìjì líle ti ń ru ní ojú omi Òkun, ti ń hó ìfófó ìtìjú wọn jáde; alárìnkiri ìràwọ̀, àwọn tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè láéláé. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ni Enoku, ẹni keje láti ọ̀dọ̀ Adamu, sọtẹ́lẹ̀ nípa wọn pé “Kíyèsi i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn rẹ̀ mímọ́, láti ṣe ìdájọ́ gbogbo ènìyàn, láti dá gbogbo àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run lẹ́bi ní ti gbogbo iṣẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run wọn, ti wọ́n ti fi àìwà-bí-Ọlọ́run ṣe, àti ní ti gbogbo ọ̀rọ̀ líle tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìwà-bí-Ọlọ́run ti sọ sí i.” Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní àwọn ti ń kùn, àwọn aláròyé, ti ń rìn nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn; wọn ń gbéraga nípa ara wọn, wọ́n sì ń ṣátá àwọn ènìyàn mìíràn fún èrè ara wọn.