Jud 1:1-8

Jud 1:1-8 Yoruba Bible (YCE)

Èmi Juda, iranṣẹ Jesu Kristi, tí mo jẹ́ arakunrin Jakọbu ni mò ń kọ ìwé yìí sí àwọn tí Ọlọrun Baba fẹ́ràn, tí Jesu Kristi pè láti pamọ́. Kí àánú, alaafia ati ìfẹ́ kí ó máa pọ̀ sí i fun yín. Ẹ̀yin olùfẹ́, mo ti gbìyànjú títí láti kọ ìwé si yín nípa ìgbàlà tí a jọ ní, nígbà tí mo rí i pé ó di dandan pé kí n kọ ìwé si yín, kí n rọ̀ yín pé kí ẹ máa jà fún igbagbọ tí Ọlọrun fi fún àwọn eniyan rẹ̀ mímọ́ lẹ́ẹ̀kan gbọ̀n-ọ́n. Nítorí àwọn kan ti yọ́ wọ inú ìjọ, àwọn tí Ìwé Mímọ́ ti sọ nípa wọn lọ́jọ́ tó ti pẹ́ pé ìdájọ́ ń bọ̀ sórí wọn. Wọ́n jẹ́ aláìbọ̀wọ̀ fún Ọlọrun, wọ́n yí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun wa pada sí àìdára láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ inú wọn, wọ́n sẹ́ Ọ̀gá wa kanṣoṣo ati Oluwa wa Jesu Kristi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti mọ gbogbo nǹkan wọnyi, sibẹ mo fẹ́ ran yín létí pé lẹ́yìn tí Oluwa ti gba àwọn eniyan là kúrò ní ilẹ̀ Ijipti tán, nígbà tí ó yá, ó tún pa àwọn tí kò gbàgbọ́ run. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn angẹli tí wọn kọjá ààyè wọn àkọ́kọ́, tí wọ́n kúrò ní ipò tí Ọlọrun kọ́ fi wọ́n sí. Ẹ̀wọ̀n ayérayé ni Ọlọrun fi dè wọ́n mọ́ inú òkùnkùn biribiri títí di ọjọ́ ńlá nnì tíí ṣe ọjọ́ ìdájọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìlú Sodomu ati ìlú Gomora ati àwọn ìlú tí ó yí wọn ká. Àwọn náà ṣe bí àwọn angẹli tí wọ́n kọjá ààyè wọn, wọ́n ṣe àgbèrè ati oríṣìíríṣìí ohun ìbàjẹ́ tí kò bá ìwà eniyan mu. Ọlọrun fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ fún gbogbo eniyan nígbà tí wọ́n jìyà iná ajónirun. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí fún àwọn eniyan wọnyi lónìí. Àlá tí wọn ń lá, fún ìbàjẹ́ ara wọn ni. Wọ́n tàpá sí àwọn aláṣẹ. Wọ́n ń sọ ìsọkúsọ sí àwọn ẹ̀dá ọ̀run tí ó lógo.

Jud 1:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Juda, ìránṣẹ́ Jesu Kristi àti arákùnrin Jakọbu, Sí àwọn tí a pè, olùfẹ́ nínú Ọlọ́run Baba, tí a pamọ́ fún Jesu Kristi: Kí àánú, àlàáfíà àti ìfẹ́ kí ó máa jẹ́ tiyín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi tòótọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmí ní ìtara láti kọ̀wé sí i yín nípa ìgbàlà tí í ṣe ti gbogbo ènìyàn, n kò gbọdọ̀ má kọ̀wé sí yín, kí ń sì gbà yín ní ìyànjú láti máa jà fitafita fún ìgbàgbọ́, tí a ti fi lé àwọn ènìyàn mímọ́ lọ́wọ́ ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo. Nítorí àwọn ènìyàn kan ń bẹ tí wọ́n ń yọ́ wọlé, àwọn ẹni tí a ti yàn láti ìgbà àtijọ́ sí ẹ̀bi yìí, àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, tí ń yí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run wa padà sí wọ̀bìà, tí wọn sì ń sẹ́ Olúwa wa kan ṣoṣo náà, àní, Jesu Kristi Olúwa. Nítòótọ́, ẹ ti mọ nǹkan wọ̀nyí ní ẹ̀ẹ̀kan rí, mo fẹ́ rán an yín létí pé, lẹ́yìn tí Olúwa ti gba àwọn kan là láti ilẹ̀ Ejibiti wá, lẹ́yìn náà ni ó run àwọn tí kò gbàgbọ́. Àti àwọn angẹli tí kò tọ́jú ipò ọlá wọn, ṣùgbọ́n tí wọn fi ipò wọn sílẹ̀, àwọn tí ó pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n àìnípẹ̀kun ní ìsàlẹ̀ òkùnkùn de ìdájọ́ ọjọ́ ńlá nì. Àní bí Sodomu àti Gomorra, àti àwọn ìlú agbègbè wọn, ti fi ara wọn fún àgbèrè ṣíṣe, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé ará àjèjì lẹ́yìn, àwọn ni ó fi lélẹ̀ bí àpẹẹrẹ, àwọn tí ó ń jìyà iná àìnípẹ̀kun. Bákan náà ni àwọn wọ̀nyí ń sọ ara wọn di èérí nínú àlá wọn, wọ́n ń gan ìjòyè, wọn sì ń sọ̀rọ̀ búburú sí àwọn ọlọ́lá.