Joṣ 9:16-27
Joṣ 9:16-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe li opin ijọ́ mẹta, lẹhin ìgbati nwọn bá wọn dá majẹmu, ni nwọn gbọ́ pe aladugbo wọn ni nwọn, ati pe làrin wọn ni nwọn gbé wà. Awọn ọmọ Israeli si dide, nwọn si dé ilu wọn ni ijọ́ kẹta. Njẹ ilu wọn ni Gibeoni, ati Kefira, ati Beerotu, ati Kiriati-jearimu. Awọn ọmọ Israeli kò pa wọn, nitoriti awọn olori ijọ awọn enia ti fi OLUWA, Ọlọrun Israeli, bura fun wọn. Gbogbo ijọ awọn enia si kùn si awọn olori. Ṣugbọn gbogbo awọn olori wi fun gbogbo ijọ pe, Awa ti fi OLUWA, Ọlọrun Israeli, bura fun wọn: njẹ nitorina awa kò le fọwọkàn wọn. Eyi li awa o ṣe si wọn, ani awa o da wọn si, ki ibinu ki o má ba wà lori wa, nitori ibura ti a bura fun wọn. Awọn olori si wi fun wọn pe, Ẹ da wọn si: nwọn si di aṣẹ́gi ati apọnmi fun gbogbo ijọ; gẹgẹ bi awọn olori ti sọ fun wọn. Joṣua si pè wọn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi tàn wa wipe, Awa jìna rére si nyin; nigbati o jẹ́ pe lãrin wa li ẹnyin ngbé? Njẹ nitorina ẹnyin di ẹni egún, ẹrú li ẹnyin o si ma jẹ́ titi, ati aṣẹ́gi ati apọnmi fun ile Ọlọrun mi. Nwọn si da Joṣua lohùn wipe, Nitoriti a sọ fun awọn iranṣẹ rẹ dajudaju, bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti paṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ̀, lati fun nyin ni gbogbo ilẹ na, ati lati pa gbogbo awọn ara ilẹ na run kuro niwaju nyin; nitorina awa bẹ̀ru nyin gidigidi nitori ẹmi wa, a si ṣe nkan yi. Njẹ nisisiyi, kiyesi i, li ọwọ́ rẹ li awa wà: bi o ti dara si ati bi o ti tọ́ si li oju rẹ lati ṣe wa, ni ki iwọ ki o ṣe. Bẹ̃li o si ṣe wọn, o si gbà wọn li ọwọ́ awọn ọmọ Israeli, nwọn kò si pa wọn. Joṣua si ṣe wọn li aṣẹ́gi ati apọnmi fun ijọ, ati fun pẹpẹ OLUWA li ọjọ́ na, ani titi di oni-oloni, ni ibi ti o ba yàn.
Joṣ 9:16-27 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹta tí wọ́n ti bá àwọn eniyan náà ṣe àdéhùn, ni wọ́n gbọ́ pé nítòsí wọn ni wọ́n wà, ati pé aládùúgbò ni wọ́n. Àwọn ọmọ Israẹli bá gbéra ní ọjọ́ kẹta, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn ìlú wọn. Àwọn ìlú náà ni: Gibeoni, Kefira, Beeroti ati Kiriati Jearimu. Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli kò pa wọ́n, nítorí pé àwọn àgbààgbà wọn ti búra fún wọn ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli. Gbogbo ìjọ eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí i kùn sí àwọn àgbààgbà. Ṣugbọn gbogbo àwọn àgbààgbà dá ìjọ eniyan náà lóhùn pé, “A ti búra fún wọn ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli, a kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kàn wọ́n mọ́. Ohun tí a lè ṣe ni pé kí á dá wọn sí, kí ibinu OLUWA má baà wá sórí wa, nítorí ìbúra tí a ti ṣe fún wọn.” Àwọn àgbààgbà bá wí fún wọn pé, “Ẹ má pa wọ́n.” Àwọn àgbààgbà Israẹli bá pàṣẹ pé kí àwọn eniyan náà di aṣẹ́gi ati apọnmi fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli. Joṣua pè wọ́n, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi tàn wá jẹ, tí ẹ wí fún wa pé, ọ̀nà jíjìn ni ẹ ti wá, nígbà tí ó jẹ́ pé ààrin wa níbí ni ẹ̀ ń gbé? Nítorí náà, ẹ di ẹni ìfibú; ẹrú ni ẹ óo máa ṣe, ẹ̀yin ni ẹ óo máa ṣẹ́ igi tí ẹ óo sì máa pọnmi fun ilé Ọlọrun mi.” Wọ́n dá Joṣua lóhùn pé, “Wọ́n sọ fún àwa iranṣẹ yín pé, dájúdájú, OLUWA Ọlọrun yín ti pàṣẹ fún Mose láti fun yín ní gbogbo ilẹ̀ yìí, ati láti pa gbogbo àwọn eniyan ibẹ̀; nítorí náà ni ẹ̀rù yín ṣe bà wá. Kí ẹ má baà pa wá run ni a fi ṣe ohun tí a ṣe. Sibẹsibẹ, ọwọ́ yín náà ni a ṣì wà; ẹ ṣe wá bí ó bá ti tọ́ lójú yín.” Ohun tí Joṣua ṣe fún wọn ni pé ó gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, kò jẹ́ kí wọ́n pa wọ́n. Ṣugbọn láti ọjọ́ náà ni Joṣua ti sọ wọ́n di ẹni tí ó ń ṣẹ́ igi, tí ó sì ń pọn omi fún àwọn eniyan Israẹli, ati fún pẹpẹ OLUWA. Títí di òní, àwọn ni wọ́n ń ṣe iṣẹ́ náà ní ibi tí OLUWA yàn pé kí àwọn ọmọ Israẹli ti máa jọ́sìn.
Joṣ 9:16-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ẹ̀yìn ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n ti ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn ará Gibeoni, àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ pé aládùúgbò wọn ni wọ́n, tí ń gbé ní tòsí wọn. Bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọmọ Israẹli jáde, wọ́n sì dé ìlú wọn ní ọjọ́ kẹta: Gibeoni, Kefira, Beeroti àti Kiriati-Jearimu. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli kò si kọlù wọ́n, nítorí pé àwọn àgbàgbà ìjọ ènìyàn ti búra fún wọn ní orúkọ OLúWA Ọlọ́run Israẹli. Gbogbo ènìyàn sì kùn sí àwọn àgbàgbà náà, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn olórí dáhùn pé, “Àwa ti búra fún wọn ní orúkọ OLúWA Ọlọ́run Israẹli, a kò sì lè fọwọ́ kàn wọ́n nísinsin yìí. Èyí ní àwa yóò ṣe sí wọn, àwa yóò dá wọn sí, kí ìbínú kí ó má ba à wá sórí wa, nítorí ìbúra tí a búra fún wọn.” Wọ́n tẹ̀síwájú, “Ẹ dá wọn sí, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí wọn jẹ́ gégigégi àti apọnmi fún gbogbo ìlú.” Àwọn àgbàgbà náà sì mú ìlérí wọn ṣẹ fún wọn. Nígbà náà ni Joṣua pe àwọn ọmọ Gibeoni jọ pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi tàn wá wí pe, ‘Àwa gbé ní ibi tí ó jìnnà sí yín,’ nígbà tí ó jẹ́ pé tòsí wa ní ẹ̀yin ń gbé? Nísinsin yìí, ẹ̀yin di ẹni ègún: Ẹ̀yin kò sì ní kúrò ní gégigégi àti apọnmi fún ilé Ọlọ́run mi.” Wọ́n sì dá Joṣua lóhùn pé, “Nítorí tí a sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ dájúṣáká bí OLúWA Ọlọ́run rẹ ti pàṣẹ fún Mose ìránṣẹ́ rẹ̀, láti fún yín ní gbogbo ilẹ̀ náà, kí ó sì pa gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà run kúrò ní iwájú yín. Nítorí náà, àwa bẹ̀rù ẹ̀mí wa nítorí yín, èyí sì ni ìdí tí a fi ṣe bẹ́ẹ̀. Nísinsin yìí, àwa wà ní ọwọ́ yín. Ohunkóhun tí ẹ bá rò pé ó yẹ ó si tọ́ lójú yín ní kí ẹ fi wá ṣe.” Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua sì gbà wọ́n là kúrò ní ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli. Wọn kò sì pa wọ́n. Ní ọjọ́ náà ni ó sọ àwọn Gibeoni di aṣẹ́gi àti apọnmi fún àwọn ará ìlú àti fún pẹpẹ OLúWA ní ibi tí OLúWA yóò yàn. Báyìí ni wọ́n wà títí di òní yìí.