Joṣ 9:12-15
Joṣ 9:12-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Àkara wa yi ni gbigbona li a mú u fun èse wa, lati ile wa wá, li ọjọ́ ti a jade lati tọ̀ nyin wá; ṣugbọn nisisiyi, kiyesi i, o gbẹ, o si bu: Ìgo-awọ waini wọnyi, ti awa kún, titun ni nwọn; kiyesi i, nwọn fàya: ati ẹ̀wu wa wọnyi ati bàta wa di gbigbo nitori ọ̀na ti o jìn jù. Awọn ọkunrin si gbà ninu onjẹ wọn, nwọn kò si bère li ẹnu OLUWA. Joṣua si bá wọn ṣọrẹ, o si bá wọn dá majẹmu lati da wọn si: awọn olori ijọ enia fi OLUWA Ọlọrun Israeli bura fun wọn.
Joṣ 9:12-15 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ wò ó! Burẹdi wa nìyí, ó gbóná nígbà tí a dì í nílé fún ìrìn àjò yìí ní ọjọ́ tí a bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò náà. Ṣugbọn nisinsinyii, ó ti gbẹ, ó sì ti bu. Titun ni àwọn awọ ìpọnmi wọnyi nígbà tí a kó wọn jáde tí a sì pọn omi sinu wọn. Ẹ wò ó, wọ́n ti gbó, wọ́n sì ti ya. Àwọn aṣọ wa ati àwọn bàtà wa ti gbó nítorí ìrìn àjò náà jìn.” Àwọn ọmọ Israẹli bá wọn jẹ ninu oúnjẹ wọn, wọn kò sì bèèrè ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ OLUWA. Joṣua bá wọn dá majẹmu alaafia, pé, àwọn kò ní pa wọ́n, àwọn àgbààgbà Israẹli sì búra fún wọn.
Joṣ 9:12-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbígbóná ní a mú oúnjẹ wa wá, nígbà tí a dì í ní ilé ní ọjọ́ tí à ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín. Ṣùgbọ́n ẹ wò ó bí ó ṣe gbẹ àti bí ó sì ṣe bu nísinsin yìí. Àti ìgò wáìnì wọ̀nyí, tí àwa rọ kún tuntun ni, ṣùgbọ́n ẹ wò ó bí wọ́n ti sán. Aṣọ àti bàtà wa ni ó sì ti gbó nítorí ìrìnàjò ọ̀nà jíjìn.” Àwọn ọkùnrin Israẹli sì yẹ oúnjẹ wọn wò, wọn kò sì wádìí ní ọwọ́ OLúWA. Nígbà náà ni Joṣua ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú wọn láti dá wọn sí, àti àwọn olórí ìjọ ènìyàn fi ọwọ́ sí àdéhùn náà nípa ṣíṣe ìbúra.