Joṣ 9:1-5
Joṣ 9:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọba ti mbẹ li apa ihin Jordani, li ori òke, ati li afonifoji, ati ni gbogbo àgbegbe okun nla ti o kọjusi Lebanoni, awọn Hitti, ati awọn Amori, awọn Kenaani, awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi, gbọ́ ọ; Nwọn si kó ara wọn jọ, lati fi ìmọ kan bá Joṣua ati Israeli jà. Ṣugbọn nigbati awọn ara Gibeoni gbọ́ ohun ti Joṣua ṣe si Jeriko ati si Ai, Nwọn ṣe ẹ̀tan, nwọn si lọ nwọn si ṣe bi ẹnipe onṣẹ ni nwọn, nwọn si mú ogbologbo àpo kà ori kẹtẹkẹtẹ wọn, ati ìgo-awọ ọti-waini ti lailai, ti o ya, ti a si dì; Ati bàta gbigbo ati lilẹ̀ li ẹsẹ̀ wọn, ati ẹ̀wu gbigbo li ara wọn; ati gbogbo àkara èse wọn o gbẹ o si hùkasi.
Joṣ 9:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà ní agbègbè olókè, ní òdìkejì odò Jọdani ati àwọn tí wọ́n wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní etí òkun Mẹditarenia ní agbègbè Lẹbanoni, àwọn ará Hiti, àwọn ará Amori, àwọn ará Kenaani, àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi, gbọ́ nípa ìṣẹ́gun àwọn ọmọ Israẹli, gbogbo wọn parapọ̀, wọ́n fi ohùn ṣọ̀kan láti bá Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli jagun. Ṣugbọn nígbà tí àwọn ará Gibeoni gbọ́ ohun tí Joṣua ṣe sí ìlú Jẹriko ati Ai, wọ́n lo ọgbọ́n, wọ́n tọ́jú oúnjẹ, wọ́n mú àwọn àpò ìdọ̀họ tí wọ́n ti gbó, wọ́n dì wọ́n lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Wọ́n mú awọ ìpọnmi tí ó ti gbó, tí wọ́n sì ti lẹ̀, wọ́n wọ sálúbàtà tí ó ti gbó ati aṣọ àkísà, gbogbo oúnjẹ tí wọn mú lọ́wọ́ ni ó ti gbẹ, tí ó sì ti bu.
Joṣ 9:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nísinsin yìí, nígbà tí gbogbo ọba tó wà ní ìwọ̀-oòrùn Jordani gbọ́ nípa nǹkan wọ̀nyí, àwọn náà tí ó wà ní orí òkè àti àwọn tí ó wà ní ẹsẹ̀ òkè, àti gbogbo àwọn tí ó wà ní agbègbè Òkun ńlá títí ó fi dé Lebanoni (àwọn ọba Hiti, Amori, Kenaani, Peresi, Hifi àti Jebusi) wọ́n sì kó ara wọn jọ láti bá Joṣua àti Israẹli jagun. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ènìyàn Gibeoni gbọ́ ohun tí Joṣua ṣe sí Jeriko àti Ai, wọ́n dá ọgbọ́n ẹ̀tàn. Wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí aṣojú tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn kún fún ẹrù tí a fi àwọn àpò tó ti gbó dì, àti àwọn awọ ọtí wáìnì tó ti gbó tí a tún rán. Àwọn ọkùnrin náà sì wọ bàtà àti aṣọ tí ó ti gbó. Gbogbo oúnjẹ tí wọ́n pèsè fún ara wọn sì bu.