Joṣ 7:24-25
Joṣ 7:24-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Joṣua, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, si mú Akani ọmọ Sera, ati fadakà na, ati ẹ̀wu na, ati dindi wurà na, ati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, ati akọ-mãlu rẹ̀, ati kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, ati agutan rẹ̀, ati agọ́ rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní; nwọn si mú wọn lọ si ibi afonifoji Akoru. Joṣua si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi yọ wa lẹnu? OLUWA yio yọ iwọ na lẹnu li oni yi. Gbogbo Israeli si sọ ọ li okuta pa; nwọn si dánasun wọn, nwọn sọ wọn li okuta.
Joṣ 7:24-25 Yoruba Bible (YCE)
Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá mú Akani, ọmọ Sera, ati fadaka, ati ẹ̀wù àwọ̀lékè, ati ọ̀pá wúrà, ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, àwọn akọ mààlúù rẹ̀ ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, àwọn aguntan rẹ̀ ati àgọ́ rẹ̀, ati ohun gbogbo tí ó ní, wọ́n kó wọn lọ sí àfonífojì Akori. Joṣua bá bi í pé, “Kí ló dé tí o fi kó wa sinu gbogbo ìyọnu yìí? OLUWA sì ti kó ìyọnu bá ìwọ náà lónìí.” Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá sọ wọ́n ní òkúta pa, wọ́n sì dáná sun wọ́n.
Joṣ 7:24-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Joṣua pẹ̀lú gbogbo Israẹli, mú Akani ọmọ Sera, fàdákà, ẹ̀wù àti wúrà tí a dà, àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin, màlúù rẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti àgùntàn àgọ́ rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ni, wọ́n sì kó wọn lọ sí ibi Àfonífojì Akori. Joṣua sì wí pé, “Èéṣe tí ìwọ mú wàhálà yìí wá sí orí wa? OLúWA yóò mú ìpọ́njú wá sí orí ìwọ náà lónìí.” Nígbà náà ni gbogbo Israẹli sọ ọ́ ní òkúta pa, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sọ àwọn tókù ní òkúta pa tán, wọ́n sì jó wọn níná.