Joṣ 7:2-5
Joṣ 7:2-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Joṣua si rán enia lati Jeriko lọ si Ai, ti mbẹ lẹba Beti-afeni, ni ìla-õrùn Beti-eli, o si wi fun wọn pe, Ẹ gòke lọ ki ẹ si ṣamí ilẹ na. Awọn enia na gòke lọ nwọn si ṣamí Ai. Nwọn si pada tọ̀ Joṣua wá, nwọn si wi fun u pe, Má ṣe jẹ ki gbogbo enia ki o gòke lọ; ṣugbọn jẹ ki ìwọn ẹgba tabi ẹgbẹdogun enia ki o gòke lọ ki nwọn si kọlù Ai; má ṣe jẹ ki gbogbo enia lọ ṣiṣẹ́ nibẹ̀; nitori diẹ ni nwọn. Bẹ̃ni ìwọn ẹgbẹdogun enia gòke lọ sibẹ̀: nwọn si sá niwaju awọn enia Ai. Awọn enia Ai pa enia mẹrindilogoji ninu wọn: nwọn si lepa wọn lati ẹnubode titi dé Ṣebarimu, nwọn si pa wọn bi nwọn ti nsọkalẹ: àiya awọn enia na já, o si di omi.
Joṣ 7:2-5 Yoruba Bible (YCE)
Joṣua rán àwọn ọkunrin kan láti Jẹriko lọ sí ìlú Ai, lẹ́bàá Betafeni ní ìhà ìlà oòrùn Bẹtẹli, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣe amí ilẹ̀ náà wá.” Àwọn ọkunrin náà lọ ṣe amí ìlú Ai. Wọ́n pada tọ Joṣua wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Má wulẹ̀ jẹ́ kí gbogbo àwọn eniyan lọ gbógun ti ìlú Ai, yan àwọn eniyan bí ẹgbaa (2,000) tabi ẹgbẹẹdogun (3,000) kí wọ́n lọ gbógun ti ìlú náà. Má wulẹ̀ lọ dààmú gbogbo àwọn eniyan lásán, nítorí pé àwọn ará Ai kò pọ̀ rárá.” Nítorí náà, nǹkan bí ẹgbẹẹdogun (3,000) ninu àwọn ọmọ Israẹli lọ gbógun tì wọ́n. Ṣugbọn wọ́n sá níwájú àwọn ará Ai. Àwọn ọmọ ogun Ai pa tó mẹrindinlogoji (36) ninu wọn, wọ́n sì lé gbogbo wọn kúrò ní ẹnubodè wọn títí dé Ṣebarimu. Wọ́n ń pa àwọn ọmọ Israẹli bí wọ́n ti ń dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè náà. Ọkàn àwọn ọmọ Israẹli bá dààmú, àyà wọn sì já.
Joṣ 7:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Joṣua rán àwọn ọkùnrin láti Jeriko lọ sí Ai, tí ó súnmọ́ Beti-Afeni ní ìlà-oòrùn Beteli, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gòkè lọ kí ẹ sì ṣe ayọ́lẹ̀wò.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn arákùnrin náà lọ, wọ́n sì yọ́ Ai wò. Nígbà tí wọ́n padà sí ọ̀dọ̀ Joṣua, wọ́n wí pé, “Kì í ṣe gbogbo àwọn ènìyàn ni ó ni láti gòkè lọ bá Ai jà. Rán ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) tàbí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin láti gbà á, kí ó má ṣe dá gbogbo àwọn ènìyàn ní agara, nítorí ìba ọkùnrin díẹ̀ ní ó wà níbẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ní àwọn bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin lọ; ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Ai lé wọn sá. Àwọn ènìyàn Ai sì pa àwọn bí mẹ́rìndínlógójì nínú wọn. Wọ́n sì ń lépa àwọn ará Israẹli láti ibodè ìlú títí dé Ṣebarimu, wọ́n sì pa àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀. Àyà àwọn ènìyàn náà sì já, ọkàn wọn sì pami.