Joṣ 7:19-26
Joṣ 7:19-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Joṣua si wi fun Akani pe, Ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ, fi ogo fun OLUWA, Ọlọrun Israeli, ki o si jẹwọ fun u; ki o si sọ fun mi nisisiyi, ohun ti iwọ se; má ṣe pa a mọ́ fun mi. Akani si da Joṣua lohùn, o si wipe, Nitõtọ ni mo ṣẹ̀ si OLUWA, Ọlọrun Israeli, bayi bayi ni mo ṣe: Nigbati mo ri ẹ̀wu Babeli kan daradara ninu ikogun, ati igba ṣekeli fadakà, ati dindi wurà kan oloṣuwọn ãdọta ṣekeli, mo ṣojukokoro wọn, mo si mú wọn; sawò o, a fi wọn pamọ́ ni ilẹ lãrin agọ́ mi, ati fadakà na labẹ rẹ̀. Joṣua si rán onṣẹ, nwọn si sare wọ̀ inu agọ́ na; si kiyesi i, a fi i pamọ́ ninu agọ́ rẹ̀, ati fadakà labẹ rẹ̀. Nwọn si mú wọn jade lãrin agọ́ na, nwọn si mú wọn wá sọdọ Joṣua, ati sọdọ gbogbo awọn ọmọ Israeli, nwọn si fi wọn lelẹ niwaju OLUWA. Joṣua, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, si mú Akani ọmọ Sera, ati fadakà na, ati ẹ̀wu na, ati dindi wurà na, ati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, ati akọ-mãlu rẹ̀, ati kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, ati agutan rẹ̀, ati agọ́ rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní; nwọn si mú wọn lọ si ibi afonifoji Akoru. Joṣua si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi yọ wa lẹnu? OLUWA yio yọ iwọ na lẹnu li oni yi. Gbogbo Israeli si sọ ọ li okuta pa; nwọn si dánasun wọn, nwọn sọ wọn li okuta. Nwọn si kó òkiti okuta nla kan lé e lori titi di oni-oloni; OLUWA si yipada kuro ninu imuna ibinu rẹ̀. Nitorina li a ṣe npè orukọ ibẹ̀ li Afonifoji Akoru, titi di oni-oloni.
Joṣ 7:19-26 Yoruba Bible (YCE)
Joṣua wí fún Akani pé, “Ọmọ mi, fi ògo fún OLUWA Ọlọrun Israẹli, kí o sì yìn ín. Jẹ́wọ́ ohun tí o ṣe, má fi pamọ́ fún mi.” Akani dá Joṣua lóhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun Israẹli. Ohun tí mo sì ṣe nìyí: Nígbà tí mo wo ààrin àwọn ìkógun, mo rí ẹ̀wù àwọ̀lékè dáradára kan láti Ṣinari, ati igba ìwọ̀n Ṣekeli fadaka, ati ọ̀pá wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọta Ṣekeli, wọ́n wọ̀ mí lójú, mo bá kó wọn, mo sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ ninu àgọ́ mi. Fadaka ni mo fi tẹ́lẹ̀.” Joṣua bá ranṣẹ, wọ́n sáré lọ wo inú àgọ́ rẹ̀, wọ́n bá àwọn nǹkan náà ní ibi tí ó bò wọ́n mọ́, ó fi fadaka tẹ́lẹ̀. Wọ́n hú wọn jáde ninu àgọ́ rẹ̀, wọ́n kó wọn wá siwaju Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì tẹ́ wọn kalẹ̀ níwájú OLUWA. Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá mú Akani, ọmọ Sera, ati fadaka, ati ẹ̀wù àwọ̀lékè, ati ọ̀pá wúrà, ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, àwọn akọ mààlúù rẹ̀ ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, àwọn aguntan rẹ̀ ati àgọ́ rẹ̀, ati ohun gbogbo tí ó ní, wọ́n kó wọn lọ sí àfonífojì Akori. Joṣua bá bi í pé, “Kí ló dé tí o fi kó wa sinu gbogbo ìyọnu yìí? OLUWA sì ti kó ìyọnu bá ìwọ náà lónìí.” Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá sọ wọ́n ní òkúta pa, wọ́n sì dáná sun wọ́n. Wọ́n kó òkítì òkúta jọ sórí rẹ̀. Òkítì òkúta náà sì wà níbẹ̀ títí di òní olónìí. OLUWA bá yí ibinu rẹ̀ pada. Nítorí náà ni wọ́n ṣe ń pe ibẹ̀ ní àfonífojì Akori.
Joṣ 7:19-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ní Joṣua sọ fún Akani pé, “Ọmọ mi fi ògo fún OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, kí o sì fi ìyìn fún un. Sọ fún mi ohun tí ìwọ ti ṣe, má ṣe fi pamọ́ fún mi.” Akani sì dáhùn pé, “Òtítọ́ ni! Mo ti ṣẹ̀ sí OLúWA, Ọlọ́run Israẹli. Nǹkan tí mo ṣe nìyìí: Nígbà tí mo rí ẹ̀wù Babeli kan tí ó dára nínú ìkógun, àti igba ṣékélì fàdákà àti odindi wúrà olóṣùnwọ́n àádọ́ta ṣékélì, mo ṣe ojúkòkòrò wọn mo sì mú wọn. Mo fi wọ́n pamọ́ ní abẹ́ àgọ́ mi àti fàdákà ní abẹ́ rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ran àwọn òjíṣẹ́, wọ́n sì sáré wọ inú àgọ́ náà, ó sì wà níbẹ̀, a sì fi pamọ́ nínú àgọ́ ọ rẹ̀, àti fàdákà ní abẹ́ ẹ rẹ̀. Wọ́n sì mú àwọn nǹkan náà jáde láti inú àgọ́ rẹ̀, wọ́n mú wọn wá fún Joṣua àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì fi wọ́n lélẹ̀ níwájú OLúWA. Nígbà náà ni Joṣua pẹ̀lú gbogbo Israẹli, mú Akani ọmọ Sera, fàdákà, ẹ̀wù àti wúrà tí a dà, àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin, màlúù rẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti àgùntàn àgọ́ rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ni, wọ́n sì kó wọn lọ sí ibi Àfonífojì Akori. Joṣua sì wí pé, “Èéṣe tí ìwọ mú wàhálà yìí wá sí orí wa? OLúWA yóò mú ìpọ́njú wá sí orí ìwọ náà lónìí.” Nígbà náà ni gbogbo Israẹli sọ ọ́ ní òkúta pa, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sọ àwọn tókù ní òkúta pa tán, wọ́n sì jó wọn níná. Wọ́n sì kó òkìtì òkúta ńlá lé Akani lórí títí di òní yìí. Nígbà náà ní OLúWA sì yí ìbínú gbígbóná rẹ̀ padà. Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ ibẹ̀ ní Àfonífojì Akori láti ìgbà náà.