Joṣ 7:16-18
Joṣ 7:16-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹ̃ni Joṣua dide ni kùtukutu owurọ̀, o si mú Israeli wá gẹgẹ bi ẹ̀ya wọn; a si mú ẹ̀ya Juda: O si mú idile Juda wá; a si mu idile Sera: o si mú idile Sera wá li ọkunrin kọkan; a si mú Sabdi: O si mú ara ile rẹ̀ li ọkunrin kọkan; a si mú Akani ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera ninu, ẹ̀ya Judah.
Joṣ 7:16-18 Yoruba Bible (YCE)
Joṣua gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu, ó kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli wá ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, wọ́n bá mú ẹ̀yà Juda. Ó kó ẹ̀yà Juda wá ní agbo-ilé kọ̀ọ̀kan, wọn sì mú agbo-ilé Sera. Ó kó agbo-ilé Sera wá, wọ́n sì fa àwọn ọkunrin ibẹ̀ kalẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n bá mú Sabidi. Wọ́n sì fa àwọn ọkunrin ìdílé Sabidi kalẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n bá mú Akani ọmọ Karimi, ọmọ Sabidi, ọmọ Sera, ti ẹ̀yà Juda.
Joṣ 7:16-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Joṣua mú Israẹli wá síwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, a sì mú ẹ̀yà Juda. Àwọn agbo ilé e Juda wá sí iwájú, ó sì mú agbo ilé Sera. Ó sì mú agbo ilé Sera wá síwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, a sì mú ìdílé Sabdi. Joṣua sì mú ìdílé Simri wá síwájú ní ọkùnrin kọ̀ọ̀kan, a sì mú Akani ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera ti ẹ̀yà Juda.