Joṣ 7:10-12
Joṣ 7:10-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si wi fun Joṣua pe, Dide; ẽṣe ti iwọ fi doju rẹ bolẹ bayi? Israeli ti dẹ̀ṣẹ, nwọn si ti bà majẹmu mi jẹ́ ti mo palaṣẹ fun wọn: ani nwọn ti mú ninu ohun ìyasọtọ nì; nwọn si jale, nwọn si ṣe agabagebe pẹlu, ani nwọn si fi i sinu ẹrù wọn. Nitorina ni awọn ọmọ Israeli kò ṣe le duro niwaju awọn ọtá wọn, nwọn pẹhinda niwaju awọn ọtá wọn, nitoriti nwọn di ẹni ifibu: emi ki yio wà pẹlu nyin mọ́, bikoṣepe ẹnyin pa ohun ìyasọtọ run kuro lãrin nyin.
Joṣ 7:10-12 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni OLUWA wí fun Joṣua pé, “Dìde. Kí ló dé tí o fi dojúbolẹ̀? Israẹli ti ṣẹ̀, wọ́n ti rú òfin mi. Wọ́n ti mú ninu àwọn ohun tí a yà sọ́tọ̀, wọ́n ti jalè, wọ́n ti purọ́, wọn sì ti fi ohun tí wọ́n jí pamọ́ sábẹ́ àwọn ohun ìní wọn. Ìdí nìyí tí àwọn ọmọ Israẹli kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n sá níwájú àwọn ọ̀tá wọn nítorí pé, wọ́n ti di ẹni ìparun. N kò ní wà pẹlu yín mọ́, àfi bí ẹ bá run àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ tí ó wà láàrin yín.
Joṣ 7:10-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
OLúWA sì sọ fún Joṣua pé, “Dìde! Kín ni ìwọ ń ṣe tí ó fi dojúbolẹ̀? Israẹli ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti ba májẹ̀mú mi jẹ́, èyí tí mo pàṣẹ fún wọn pé kí wọn pamọ́. Wọ́n ti mú nínú ohun ìyàsọ́tọ̀, wọ́n ti jí, wọ́n pa irọ́, wọ́n ti fi wọ́n sí ara ohun ìní wọn. Ìdí nì èyí tí àwọn ará Israẹli kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá wọn; wọ́n yí ẹ̀yìn wọn padà, wọ́n sì sálọ níwájú ọ̀tá a wọn nítorí pé àwọn gan an ti di ẹni ìparun. Èmi kì yóò wà pẹ̀lú u yín mọ́, bí kò ṣe pé ẹ̀yin pa ohun ìyàsọ́tọ̀ run kúrò ní àárín yín.