Joṣ 6:22-23
Joṣ 6:22-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn Joṣua sọ fun awọn ọkunrin meji ti o ti ṣe amí ilẹ na pe, Ẹ lọ si ile panṣaga nì, ki ẹ si mú obinrin na jade nibẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní, gẹgẹ bi ẹnyin ti bura fun u. Awọn ọmọkunrin ti o ṣamí si wọle, nwọn si mú Rahabu jade, ati baba rẹ̀, ati iya rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní, nwọn si mú gbogbo awọn ibatan rẹ̀ jade; nwọn si fi wọn si ẹhin ibudó Israeli.
Joṣ 6:22-23 Yoruba Bible (YCE)
Joṣua sọ fún àwọn ọkunrin meji tí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ náà pé, “Ẹ wọ ilé aṣẹ́wó náà lọ, kí ẹ sì mú obinrin náà wá ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti búra fún un.” Àwọn ọkunrin tí wọ́n lọ ṣe amí náà bá wọlé, wọ́n mú Rahabu jáde, ati baba rẹ̀, ati ìyá rẹ̀, ati àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn ìbátan rẹ̀, wọ́n sì kó wọn sí ẹ̀yìn àgọ́ àwọn ọmọ Israẹli.
Joṣ 6:22-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Joṣua sì sọ fún àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n ti wá ṣe ayọ́lẹ̀wò ilẹ̀ náà pé, “Ẹ lọ sí ilé panṣágà nì, kí ẹ sì mu jáde àti gbogbo ohun tí í ṣe tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ tí búra fún un.” Bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó lọ ṣe ayọ́lẹ̀wò wọlé lọ, wọ́n sì mú Rahabu jáde, baba rẹ̀, ìyá rẹ̀, àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní. Wọ́n sì mú gbogbo ìdílé rẹ̀ jáde, wọ́n sì fi wọ́n sí ibìkan ní ìta ibùdó àwọn ará Israẹli.