Joṣ 6:15-21

Joṣ 6:15-21 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọjọ́ keje, wọ́n gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu, wọ́n yípo ìlú náà bí wọ́n ti máa ń ṣe, nígbà meje. Ọjọ́ keje yìí nìkan ṣoṣo ni wọ́n yípo rẹ̀ lẹẹmeje. Nígbà tí ó di ẹẹkeje, lẹ́yìn tí àwọn alufaa fọn fèrè wọn, Joṣua pàṣẹ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ hó yèè! Nítorí OLUWA ti fi ìlú yìí le yín lọ́wọ́. OLUWA ti yà á sọ́tọ̀ fún ìparun, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, àfi Rahabu, aṣẹ́wó, ati àwọn tí wọ́n wà ninu ilé pẹlu rẹ̀, ni yóo wà láàyè; nítorí òun ni ó gbé àwọn amí tí a rán pamọ́. Ẹ yẹra fún ohunkohun tí OLUWA ti yà sọ́tọ̀ fún ìparun, kí ẹ má baà di ẹni ègún nípa mímú ohun tí OLUWA ti yà sọ́tọ̀, kí ẹ má baà sọ àgọ́ Israẹli di ohun ìparun, kí ẹ sì kó ìyọnu bá a. Ṣugbọn gbogbo fadaka ati wúrà ati àwọn ohun èlò idẹ ati ti irin jẹ́ ohun ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA, inú ilé ìṣúra OLUWA ni a óo kó wọn sí.” Àwọn alufaa fọn fèrè ogun, bí àwọn eniyan ti gbọ́ ìró fèrè, gbogbo wọn hó yèè! Odi ìlú náà sì wó lulẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọ ogun bá rọ́ wọ ààrin ìlú, wọ́n sì gba ìlú náà. Wọ́n run gbogbo àwọn ará ìlú náà patapata: atọkunrin, atobinrin, àtọmọdé, àtàgbà, àtakọ mààlúù, ataguntan, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́; gbogbo wọn ni wọ́n fi idà parun.

Joṣ 6:15-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọjọ́ keje, wọ́n dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní àfẹ̀mọ́júmọ́, wọ́n sì wọ́de ogun yí ìlú náà ká ní ìgbà méje, gẹ́gẹ́ bí i ti ìṣáájú, ní ọjọ́ keje nìkan ṣoṣo ni wọ́n wọ́de ogun yí ìlú náà ká nígbà méje. Ní ìgbà keje, nígbà tí àwọn àlùfáà fọn fèrè, Joṣua pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ hó! Nítorí pé OLúWA ti fún un yín ní ìlú náà. Ìlú náà àti gbogbo ohun tí ó wà níbẹ̀ ni yóò jẹ́ ìyàsọ́tọ̀ fún OLúWA. Rahabu tí ó jẹ́ panṣágà nìkan àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú u rẹ̀ ni a ó dá sí; nítorí tí ó pa àwọn ayọ́lẹ̀wò tí á rán mọ́. Ẹ pa ara yín mọ́ kúrò nínú ohun ìyàsọ́tọ̀ fún ìparun, kí ẹ̀yin kí ó má ba à ṣojú kòkòrò nípa mímú nínú àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀. Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ ẹ ó sọ ibùdó Israẹli di ìparun. Kí ẹ sì mú wàhálà wá sórí i rẹ̀. Gbogbo fàdákà àti wúrà àti ohun èlò idẹ àti irin jẹ́ mímọ́ fún OLúWA, wọ́n yóò wá sínú ìṣúra OLúWA.” Nígbà tí àwọn àlùfáà fọn ìpè, àwọn ènìyàn náà sì hó. Ó sì ṣe, bí àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìró ìpè, tí àwọn ènìyàn sì hó ìhó ńlá, odi ìlú náà wó lulẹ̀ bẹẹrẹ; bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ya wọ inú ìlú náà lọ tààrà, wọ́n sì kó ìlú náà. Wọ́n ya ìlú náà sọ́tọ̀ fún OLúWA àti fún ìparun, wọ́n sì fi idà run gbogbo ohun alààyè ní ìlú náà—ọkùnrin àti obìnrin, ọ́mọdé, àti àgbà, màlúù, àgùntàn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.