Joṣ 6:14-15
Joṣ 6:14-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Li ọjọ́ keji nwọn yi ilu na ká lẹ̃kan, nwọn si pada si ibudó: bẹ̃ni nwọn ṣe ni ijọ́ mẹfa. O si ṣe ni ijọ́ keje, nwọn dide ni kùtukutu li afẹmọjumọ́, nwọn si yi ilu na ká gẹgẹ bi ti iṣaju lẹ̃meje: li ọjọ́ na nikanṣoṣo ni nwọn yi ilu na ká lẹ̃meje.
Joṣ 6:14-15 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ keji, wọ́n yípo ìlú náà lẹ́ẹ̀kan, wọn sì pada sinu àgọ́ wọn. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fún ọjọ́ mẹfa. Ní ọjọ́ keje, wọ́n gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu, wọ́n yípo ìlú náà bí wọ́n ti máa ń ṣe, nígbà meje. Ọjọ́ keje yìí nìkan ṣoṣo ni wọ́n yípo rẹ̀ lẹẹmeje.
Joṣ 6:14-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kejì, wọ́n yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan wọ́n sì padà sí ibùdó. Wọ́n sì ṣe èyí fún ọjọ́ mẹ́fà. Ní ọjọ́ keje, wọ́n dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní àfẹ̀mọ́júmọ́, wọ́n sì wọ́de ogun yí ìlú náà ká ní ìgbà méje, gẹ́gẹ́ bí i ti ìṣáájú, ní ọjọ́ keje nìkan ṣoṣo ni wọ́n wọ́de ogun yí ìlú náà ká nígbà méje.