Joṣ 5:11-12
Joṣ 5:11-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn si jẹ ọkà gbigbẹ ilẹ na ni ijọ́ keji lẹhin irekọja, àkara alaiwu, ọkà didin li ọjọ̀ na gan. Manna si dá ni ijọ́ keji lẹhin igbati nwọn ti jẹ okà gbigbẹ ilẹ na; awọn ọmọ Israeli kò si ri manna mọ́; ṣugbọn nwọn jẹ eso ilẹ Kenaani li ọdún na.
Joṣ 5:11-12 Yoruba Bible (YCE)
Òwúrọ̀ ọjọ́ keji lẹ́yìn àjọ ìrékọjá ni ìgbà kinni tí wọ́n fi ẹnu kàn ninu èso ilẹ̀ náà, wọ́n jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà ati ọkà gbígbẹ. Mana kò dà ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, àwọn ọmọ Israẹli kò rí i kó mọ́, lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ ninu èso ilẹ̀ náà. Ṣugbọn wọ́n jẹ ninu èso ilẹ̀ Kenaani ní gbogbo ọdún náà.
Joṣ 5:11-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kejì Àjọ ìrékọjá, ní ọjọ́ náà gan an ni, wọ́n jẹ nínú àwọn ìre oko ilẹ̀ náà: àkàrà aláìwú, àti ọkà yíyan. Manna náà sì tan ní ọjọ́ kejì tí wọ́n jẹ oúnjẹ tí ilẹ̀ náà mú jáde, kò sì sí manna kankan mọ́ fún àwọn ará Israẹli, ṣùgbọ́n ní ọdún náà wọ́n jẹ ìre oko ilẹ̀ Kenaani.