Joṣ 4:19-24
Joṣ 4:19-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn enia si ti inu Jordani gòke ni ijọ́ kẹwa oṣù kini, nwọn si dó ni Gilgali, ni ìha ìla-õrùn Jeriko. Ati okuta mejila wọnni ti nwọn gbé ti inu Jordani lọ, ni Joṣua tòjọ ni Gilgali. O si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Nigbati awọn ọmọ nyin yio bère lọwọ awọn baba wọn lẹhin ọ̀la wipe, Ẽredi okuta wọnyi? Nigbana li ẹnyin o jẹ ki awọn ọmọ nyin ki o mọ̀ pe, Israeli là Jordani yi kọja ni ilẹ gbigbẹ. Nitoriti OLUWA Ọlọrun nyin mu omi Jordani gbẹ kuro niwaju nyin, titi ẹnyin fi là a kọja, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun nyin ti ṣe si Okun Pupa, ti o mu gbẹ kuro niwaju wa, titi awa fi là a kọja: Ki gbogbo enia aiye ki o le mọ ọwọ́ OLUWA, pe o lagbara; ki nwọn ki o le ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun nyin lailai.
Joṣ 4:19-24 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kinni ni àwọn eniyan náà gun òkè odò Jọdani. Wọ́n pàgọ́ sí Giligali ní ìhà ìlà oòrùn Jẹriko. Joṣua bá to àwọn òkúta mejila tí wọ́n kó jáde láti inú odò Jọdani kalẹ̀ ní Giligali. Ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Nígbà tí àwọn ọmọ yín bá bèèrè lọ́wọ́ àwọn baba wọn ní ọjọ́ iwájú pé báwo ni ti àwọn òkúta wọnyi ti jẹ́ rí? Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ yín mọ̀ pé àwọn ọmọ Israẹli kọjá odò Jọdani yìí lórí ilẹ̀ gbígbẹ. Nítorí OLUWA Ọlọrun yín mú kí odò Jọdani gbẹ títí ẹ fi rékọjá sí òdìkejì rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti mú kí Òkun Pupa gbẹ, títí tí ẹ fi là á kọjá. Kí gbogbo aráyé lè mọ̀ pé, OLUWA lágbára, kí ẹ sì lè máa bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín títí lae.”
Joṣ 4:19-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kìn-ín-ní àwọn ènìyàn náà lọ láti Jordani, wọ́n sì dúró ní Gilgali ní ìlà-oòrùn Jeriko. Joṣua sì to àwọn òkúta méjìlá tí wọ́n mú jáde ní Jordani jọ ní Gilgali. Ó sì sọ fún àwọn ará Israẹli, “Ní ọjọ́ iwájú nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè ní ọwọ́ baba wọn pé, ‘Kín ni òkúta wọ̀nyí dúró fún?’ Nígbà náà ni ẹ ó jẹ́ kí àwọn ọmọ yín mọ̀ pé, ‘Israẹli rékọjá odò Jordani ní orí ilẹ̀ gbígbẹ.’ Nítorí OLúWA Ọlọ́run yín mú Jordani gbẹ ní iwájú u yín títí ẹ̀yin fi kọjá. OLúWA Ọlọ́run yín ti ṣe sí Jordani gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Òkun Pupa, nígbà tí ó mú un gbẹ ní iwájú wa títí àwa fi kọjá. Ó ṣe èyí kí gbogbo ayé lè mọ̀ pé ọwọ́ OLúWA ní agbára, àti kí ẹ̀yin kí ó lè máa bẹ̀rù OLúWA Ọlọ́run yín ní ìgbà gbogbo.”