Joṣ 4:1-7
Joṣ 4:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, nigbati gbogbo awọn enia rekọja Jordani tán, ni OLUWA wi fun Joṣua pe, Mú ọkunrin mejila ninu awọn enia, ọkunrin kan ninu olukuluku ẹ̀ya, Ki ẹnyin si paṣẹ fun wọn pe. Ẹ gbé okuta mejila lati ihin lọ lãrin Jordani, ni ibi ti ẹsẹ̀ awọn alufa gbé duro ṣinṣin nì, ki ẹnyin ki o si rù wọn kọja pẹlu nyin, ẹ si fi wọn si ibùsun, ni ibi ti ẹnyin o sùn li alẹ yi. Nigbana ni Joṣua pè awọn ọkunrin mejila, ti o ti pèse silẹ ninu awọn ọmọ Israeli, ọkunrin kan ninu olukuluku ẹ̀ya: Joṣua si wi fun wọn pe, Ẹ kọja lọ niwaju apoti OLUWA Ọlọrun nyin si ãrin Jordani, ki olukuluku ninu nyin ki o gbé okuta kọkan lé ejika rẹ̀, gẹgẹ bi iye ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli: Ki eyi ki o le jẹ́ àmi lãrin nyin, nigbati awọn ọmọ nyin ba bère lọwọ awọn baba wọn lẹhin ọ̀la, wipe, Èredi okuta wọnyi? Nigbana li ẹnyin o da wọn lohùn pe, Nitori a ke omi Jordani niwaju apoti majẹmu OLUWA; nigbati o rekọja Jordani, a ke omi Jordani kuro: okuta wọnyi yio si jasi iranti fun awọn ọmọ Israeli lailai.

Joṣ 4:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan náà rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani tán, OLUWA wí fún Joṣua pé, “Yan ọkunrin mejila láàrin àwọn eniyan náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Kí o pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n gbé òkúta mejila láàrin odò Jọdani yìí, lọ́gangan ibi tí àwọn alufaa dúró sí, kí wọ́n gbé wọn lọ́wọ́ bí ẹ ti ń lọ, kí ẹ sì kó wọn jọ sí ibi tí ẹ óo sùn lálẹ́ òní.” Joṣua bá pe àwọn ọkunrin mejila tí ó ti yàn tẹ́lẹ̀ ninu àwọn ọmọ Israẹli, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan; ó wí fún wọn pé, “Ẹ kọjá lọ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun yín, sí ààrin odò Jọdani, kí ẹnìkọ̀ọ̀kan sì gbé òkúta kọ̀ọ̀kan lé èjìká rẹ̀. Kí iye òkúta tí ẹ óo gbé jẹ́ iye ẹ̀yà tí ó wà ninu àwọn ọmọ Israẹli. Kí èyí lè jẹ́ ohun ìrántí fun yín, nígbà tí àwọn ọmọ yín bá bèèrè lọ́wọ́ yín ní ọjọ́ iwájú pé, ‘Báwo ni ti àwọn òkúta wọnyi ti jẹ́ rí?’ Nígbà náà, ẹ óo dá wọn lóhùn pé omi odò Jọdani pín sí meji níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA nígbà tí wọn gbé e kọjá odò náà. Nítorí náà, àwọn òkúta wọnyi yóo jẹ́ ohun ìrántí ayérayé fún àwọn ọmọ Israẹli.”
Joṣ 4:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè náà kọjá nínú odò Jordani tan, OLúWA sọ fún Joṣua pé, “Yan ọkùnrin méjìlá (12) nínú àwọn ènìyàn, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, kí o sì pàṣẹ fún wọn pé Ẹ gbé òkúta méjìlá láti àárín odò Jordani ní ibi tí àwọn àlùfáà dúró sí, kí ẹ sì rù wọn kọjá, kí ẹ sì gbé wọn sí ibi tí ẹ̀yin yóò sùn ní alẹ́ yìí.” Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua pe àwọn ọkùnrin méjìlá tí ó ti yàn nínú àwọn ọmọ Israẹli, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kọjá lọ ní iwájú àpótí ẹ̀rí OLúWA Ọlọ́run yín sí àárín odò Jordani. Kí olúkúlùkù yín gbé òkúta kọ̀ọ̀kan lé èjìká a rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli, kí ó sì jẹ́ ààmì láàrín yín. Ní ọjọ́ iwájú, nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ yín pé, ‘Kí ni òkúta wọ̀nyí dúró fún?’ Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò dá wọn lóhùn pé, nítorí a gé omi odò Jordani kúrò ní iwájú àpótí ẹ̀rí OLúWA. Nígbà tí a rékọjá a Jordani, a gé omi Jordani kúrò. Àwọn òkúta wọ̀nyí yóò sì jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli láéláé.”