Joṣ 3:7-13
Joṣ 3:7-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si wi fun Joṣua pe, Li oni yi li emi o bẹ̀rẹsi gbé ọ ga li oju gbogbo Israeli, ki nwọn ki o le mọ̀ pe, gẹgẹ bi mo ti wà pẹlu Mose, bẹ̃li emi o wà pẹlu rẹ. Iwọ o si paṣẹ fun awọn alufa ti o rù apoti majẹmu na pe, Nigbati ẹnyin ba dé eti odò Jordani, ki ẹnyin ki o duro jẹ ni Jordani. Joṣua si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ sunmọ ihin, ki ẹ si gbọ́ ọ̀rọ OLUWA Ọlọrun nyin. Joṣua si wipe, Nipa eyi li ẹnyin o mọ̀ pe Ọlọrun alãye mbẹ lãrin nyin, ati pe dajudaju on o lé awọn ara Kenaani, ati awọn Hitti, ati awọn Hifi, ati awọn Perissi, ati awọn Girgaṣi ati awọn Amori, ati awọn Jebusi, kuro niwaju nyin. Kiyesi i, apoti majẹmu OLUWA gbogbo aiye ngòke lọ ṣaju nyin lọ si Jordani. Njẹ nitorina, ẹ mu ọkunrin mejila ninu awọn ẹ̀ya Israeli, ọkunrin kan ninu olukuluku ẹ̀ya. Yio si ṣe, lojukanna bi atẹlẹsẹ̀ awọn alufa ti o rù apoti OLUWA, Oluwa gbogbo aiye, ba ti tẹ̀ omi Jordani, omi Jordani yio ke kuro, ani omi ti nti òke ṣànwá; yio si duro bi òkiti kan.

Joṣ 3:7-13 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Lónìí ni n óo bẹ̀rẹ̀ sí gbé ọ ga lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, kí wọ́n lè mọ̀ pé bí mo ti wà pẹlu Mose, bẹ́ẹ̀ ni n óo wà pẹlu rẹ. Pàṣẹ fún àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu náà pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé etí odò Jọdani, ẹ wọ inú odò lọ, kí ẹ sì dúró níbẹ̀.’ ” Joṣua bá pe àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun yín wí. Èyí ni ẹ óo fi mọ̀ pé Ọlọrun alààyè wà láàrin yín, kò sì ní kùnà láti lé àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, àwọn ará Hifi, àwọn ará Perisi, àwọn ará Girigaṣi, àwọn ará Amori, ati àwọn ará Jebusi, jáde fun yín. Wò ó! Wọn yóo gbé Àpótí Majẹmu OLUWA gbogbo ayé kọjá níwájú yín sinu odò Jọdani. Nítorí náà, ẹ yan àwọn ọkunrin mejila ninu ẹ̀yà Israẹli, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí ẹsẹ̀ àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA gbogbo ayé bá kan odò Jọdani, odò náà yóo dúró; kò ní ṣàn mọ́, gbogbo omi tí ń ṣàn bọ̀ láti òkè yóo sì wọ́jọ pọ̀ bí òkítì ńlá.”
Joṣ 3:7-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sì sọ fún Joṣua pé, “Òní yìí ni Èmi yóò bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ọ ga ní ojú u gbogbo àwọn ará Israẹli, kí wọn lè mọ̀ pé Èmi wà pẹ̀lú rẹ gẹ́gẹ́ bí mo ṣe wà pẹ̀lú Mose. Sọ fún àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí náà: ‘Nígbà tí ẹ bá dé etí omi Jordani, ẹ lọ kí ẹ sì dúró nínú odò náà.’ ” Joṣua sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ súnmọ́ ibí kí ẹ̀yin kí ó sì fetí sí ọ̀rọ̀ OLúWA Ọlọ́run yín. Èyí ni ẹ̀yin yóò fi mọ̀ pé Ọlọ́run alààyè wà ní àárín yín àti pé dájúdájú yóò lé àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, Hifi, Peresi, Girgaṣi, Amori àti Jebusi jáde níwájú u yín. Àpótí májẹ̀mú Olúwa gbogbo ayé ń gòkè lọ sí Jordani ṣáájú u yín. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ mú ọkùnrin méjìlá nínú àwọn ẹ̀yà Israẹli, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Bí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí OLúWA, Olúwa gbogbo ayé bá ti ẹsẹ̀ bọ odò Jordani, omi tí ń ti òkè sàn wá yóò gé kúrò yóò sì gbá jọ bí òkìtì kan.”