Joṣ 3:3-5
Joṣ 3:3-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn si paṣẹ fun awọn enia, wipe, Nigbati ẹnyin ba ri apoti majẹmu OLUWA Ọlọrun nyin, ti ẹ ba si ri awọn alufa awọn ọmọ Lefi rù u, nigbana li ẹnyin o ṣí kuro ni ipò nyin, ẹnyin o si ma tọ̀ ọ lẹhin. Ṣugbọn alafo yio wà li agbedemeji ti ẹnyin tirẹ̀, to bi ìwọn ẹgba igbọnwọ: ẹ má ṣe sunmọ ọ, ki ẹnyin ki o le mọ̀ ọ̀na ti ẹnyin o gbà; nitoriti ẹnyin kò gbà ọ̀na yi rí. Joṣua si wi fun awọn enia pe, Ẹ yà ara nyin simimọ́: nitori li ọla OLUWA yio ṣe ohuniyanu lãrin nyin.
Joṣ 3:3-5 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n pàṣẹ fún àwọn eniyan náà pé, “Nígbà tí ẹ bá rí i pé, àwọn alufaa, ọmọ Lefi gbé Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun yín, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ, kí ẹ̀yin náà gbéra, kí ẹ sì tẹ̀lé wọn. Kí ẹ lè mọ ọ̀nà tí ẹ óo gbà, nítorí pé ẹ kò rin ọ̀nà yìí rí. Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ súnmọ́ Àpótí Majẹmu náà jù, ẹ gbọdọ̀ fi àlàfo tí ó tó nǹkan bí ẹgbaa (2,000) igbọnwọ sílẹ̀ láàrin ẹ̀yin ati Àpótí Majẹmu náà.” Joṣua sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ ya ara yín sí mímọ́ nítorí pé OLUWA yóo ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrin yín ní ọ̀la.”
Joṣ 3:3-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọ́n sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé: “Nígbà tí ẹ bá rí àpótí ẹ̀rí OLúWA Ọlọ́run yín, tí àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi rù ú, nígbà náà ni ẹ̀yin yóò sí kúrò ní ipò yín, ẹ̀yin yóò sì máa tẹ̀lé e. Ẹyin yóò lè mọ ọ̀nà tí ẹ ó gbà, torí pé ẹ̀yin kò gba ọ̀nà yìí tẹ́lẹ̀ rí. Ṣùgbọ́n àlàfo gbọdọ̀ wà ní àárín yín àti àpótí náà, tó bí ìwọ̀n ẹgbàá ìgbọ̀nwọ́.” Joṣua sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ ya ara yín sí mímọ́, nítorí ní ọ̀la, OLúWA yóò ṣe ohun ìyanu ní àárín yín.”