Joṣ 24:1-4
Joṣ 24:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
JOṢUA si pè gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli jọ si Ṣekemu, o si pè awọn àgba Israeli, ati awọn olori wọn, ati awọn onidajọ wọn, ati awọn ijoye wọn; nwọn si fara wọn hàn niwaju Ọlọrun. Joṣua si wi fun gbogbo awọn enia pe, Bayi ni OLUWA, Ọlọrun Israeli wi, Awọn baba nyin ti gbé ìha keji Odò nì li atijọ rí, ani Tera, baba Abrahamu, ati baba Nahori: nwọn si sìn oriṣa. Emi si mú Abrahamu baba nyin lati ìha keji Odò na wá, mo si ṣe amọ̀na rẹ̀ là gbogbo ilẹ Kenaani já, mo si sọ irú-ọmọ rẹ̀ di pipọ̀, mo si fun u ni Isaaki. Emi si fun Isaaki ni Jakobu ati Esau: mo si fun Esau li òke Seiri lati ní i; Jakobu pẹlu awọn ọmọ rẹ̀ si sọkalẹ lọ si Egipti.
Joṣ 24:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Joṣua pe gbogbo ẹ̀yà Israẹli jọ sí Ṣekemu, ó pe gbogbo àwọn àgbààgbà, àwọn olórí, àwọn onídàájọ́, ati àwọn alákòóso ilẹ̀ Israẹli; gbogbo wọn sì kó ara wọn jọ níwájú OLUWA. Ó wí fún gbogbo wọn pé, “Báyìí ni OLUWA Ọlọrun Israẹli wí, ‘Nígbà laelae, òkè odò Yufurate ni àwọn baba yín ń gbé: Tẹra, baba Abrahamu ati Nahori. Oriṣa ni wọ́n ń bọ nígbà náà. Láti òdìkejì odò náà ni mo ti mú Abrahamu baba yín, mo sìn ín la gbogbo ilẹ̀ Kenaani já; mo sì sọ arọmọdọmọ rẹ̀ di pupọ. Mo fún un ní Isaaki; mo sì fún Isaaki ni Jakọbu ati Esau. Mo fún Esau ní òkè Seiri bí ohun ìní tirẹ̀, ṣugbọn Jakọbu ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ijipti.
Joṣ 24:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Joṣua pe gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli jọ ní Ṣekemu. Ó pe àwọn àgbàgbà, àwọn olórí, onídàájọ́ àti àwọn ìjòyè Israẹli, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Ọlọ́run. Joṣua sì sọ fun gbogbo ènìyàn pé, “Báyìí ni OLúWA Ọlọ́run Israẹli, wí: ‘Nígbà kan rí àwọn baba ńlá yín Tẹra baba Abrahamu àti Nahori ń gbé ní ìkọjá odò Eufurate, wọ́n sì sin àwọn òrìṣà. Ṣùgbọ́n mo mú Abrahamu baba yín kúrò ní ìkọjá odò Eufurate, mo sì ṣe amọ̀nà rẹ̀ ni gbogbo Kenaani, mo sì fún ní àwọn ọmọ púpọ̀. Mo fún ní Isaaki, àti fún Isaaki ni mo fún ní Jakọbu àti Esau, mo sì fún Esau ní ilẹ̀ orí òkè Seiri ní ìní, ṣùgbọ́n Jakọbu àti àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti.