Joṣ 23:9-10
Joṣ 23:9-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoriti OLUWA ti lé awọn orilẹ-ède nla ati alagbara kuro niwaju nyin; ṣugbọn bi o ṣe ti nyin ni, kò sí ọkunrin kan ti o ti iduro niwaju nyin titi di oni. Ọkunrin kan ninu nyin yio lé ẹgbẹrun: nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin, on li ẹniti njà fun nyin, gẹgẹ bi o ti sọ fun nyin.
Pín
Kà Joṣ 23Joṣ 23:9-10 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí pé, OLUWA ti lé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tóbi tí wọ́n sì ní agbára kúrò níwájú yín, kò sì tíì sí ẹni tí ó lè ṣẹgun yín títí di òní. Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ninu yín ni ó ń bá ẹgbẹrun eniyan jà, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ni ó ń jà fun yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín.
Pín
Kà Joṣ 23